Nathaniel Bassey

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:EngvarB

Pastor Nathaniel Bassey
Ọjọ́ìbíLagos, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Gospel musician
Notable work#HallelujahChallenge
Websitenathanielbassey.net

Nathaniel Bassey Ig-Nathaniel Bassey.ogg (Listen) jẹ́ olórin Nàìjíríà, olùdarí ìjọ, a-fọn-fèrè àti a-kọ-orin ẹ̀mí tí ó gbajú-gbajà fún àwọn orin rẹ̀ "Imela", "Oníṣẹ́ Ìyanu" àti "Ọlọ́wọ́gbọgbọrọ."[1] Ó ń lọ The Redeemed Christian Church Of God[2], ó sì ń darí ìjọ The Oasis, Èkó, Ìjọ àwọn ọ̀dọ́ ti RCCG Kings Court ní VI,

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Bassey ní Èkó, Nàìjíríà ní 1981. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa international relations and politics ní University of Lagos kí ó tó lọ sí London láti lọ kọ́ nípa ìṣèlú lẹ́yìn náà. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin ní ilé-ẹ̀kọ́ ìgbà ẹ̀rùn Middlesex University.[3]

  1. "Nathaniel Bassey: A blessing in our time". The Nation. 3 October 2018. 
  2. "Churches Attended by Nigerian Gospel Ministers". churchlist.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2 February 2020. Archived from the original on 24 October 2020. Retrieved 27 August 2020. 
  3. "Nathaniel Bassey: A blessing in our time". The Nation. 3 October 2018. 

Iṣẹ́ orin[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nathaniel bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀ ní Ilé-ìjọsìn níbi tí ó ti dara pọ̀ mọ́ Rhodes Orchestra tí ó sì fun fèrè tírọ́ḿpẹ̀tì fún ọdún méjì. A-fọn-fèrè tírọ́ḿpẹ̀tì lásán ni tẹ́lẹ̀ títí di ìgbà tí ó ṣe àtinúdá orin níbi ìkíni sí Stella Obasanjo, ìyàwó olóògbé Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Olusegun Obasanjo.[1] Ní 2018, Bassey jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oníṣẹ́-ọnà tí ó wà lókè ní àpéjọpọ̀ àwọn Kìrìsìtẹ́ẹ́nì Nàìjíríà - The Experience.[2] Àwo rẹ̀ àkọ́kọ́ Elohim ni wọ́n ṣe àgbàsílẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì sọ ọ́ di odindi ní Cape Town, South Africa ní ọdún 2008. Wọ́n ti ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i iṣẹ́ ẹ̀mí àti àràmàndà pẹ̀lú orin tí ó gbájú gbajà jù nínú rẹ̀, "someone's knocking at the door," orin tí ó ń lọ lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀ tí àwọn ènìyàn sì ń nífẹ̀ẹ́ sí lọ́wọ́lọ́wọ́ nílé àti lókè òkun. [3]

[4] Nathaniel bẹ̀rẹ̀ #HallelujahChallenge ní June 2017,[5] níbi tí òun àti àwọn onígbàgbọ́ mìíràn ti máa ń sin Ọlọ́run fún wákàtí kan, láti 12:00 am sí 1:00 am. Ó máa ń ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní ojú ìran Instagram, ó sì máa ń pe àwọn mìíràn láti dara pọ̀ mọ. Ní ó kéré sí oṣù kan, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ní ó pọ̀ ju ìwò 600,000 lọ. #HallelujahChallenge fún 2020 ni wọ́n ṣe láti 4 sí 24 February.[6][7] Ní 2021, wọ́n ṣe challenge náà láti 1 sí 21 February.[8]

Àwọn àwo tí ó ti ṣàgbéjáde rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Someone's at the Door (2010)
  • The Son of God (& Imela) (2014)
  • This God is too Good (2016)
  • Revival Flames (2017)
  • Jesus: The Resurrection & the Life (2018)
  • The King is Coming (2019)
  • Hallelujah Again (Revelation 19:3) (2021)
  • Names of God (2022)
  1. "Nathaniel Bassey: A blessing in our time". The Nation. 3 October 2018. 
  2. "Kirk Franklin, Travis Greene, Tope Alabi, others to headline The Experience 2018". Punch Nigeria. 
  3. "Profile". nathanielbassey.net (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 27 November 2022. Retrieved 18 December 2020. 
  4. Busari, Torera Idowu and Stephanie (15 June 2017). "How Nathaniel Bassey started a praise and worship movement on Instagram". CNN (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 31 July 2021. 
  5. Busari, Stephanie; Idowu, Torera. "How Nathaniel Bassey started a praise and worship movement on Instagram". CNN. CNN. Retrieved 4 May 2021. 
  6. "Nathaniel Bassey Announces Date For 2019 #HalleluyahChallenge". P.M. News. 2 February 2019. 
  7. "Jesus – Nathaniel Bassey". Gospel Home. 
  8. "Everything about the Hallelujah Challenge by Nathaniel Bassey". Hallelujah Challenge. Archived from the original on 6 May 2021. Retrieved 4 May 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)