New Money (2018 film)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
New Money
Directed by Tope Oshin Ogun
Produced by Kene Okwuosa
Zulumoke Onuekwusi
Chinaza 'Naz' Onuzo
Isioma Osaje
Written by Chinaza 'Naz' Onuzo
Starring Jemima Osunde
Kate Henshaw
Dakore Akande
Wale Ojo
Cinematography Idowu Adedapo
Pindem Lot
Studio Inkblot Productions
FilmOne
Release date(s) 23 March 2018
Country Nigeria
Language English

New Money (Owó Tuntun) jẹ́ fíìmù eré ìtàgé apanilẹrin tí a gbé jáde ní ọdún 2018 ni orile-ede Nàìjíríà Tọpẹ Ọṣhin ni Oludari ere náà nígbàtí ilé isẹ́ Inkblot Productions àti FilmOne gbé e jade[1] Fíìmù na só ìtàn ọmọbìnrin kan ti o n ba ni ta'jà ti o ni èròngbà láti di aránṣọ ti o wá ṣàdédé rí ìpín tirẹ̀ gbà nínú ogún bàbá rẹ̀ ti o ti fi ìgbàkan kúrò ní'lé. Àwon òṣèré tí ó kó'pa nínú fíìmù naa ni Jemima Osunde, Kate Henshaw, Dakore Akande, Wale Ojo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, pẹ̀lú Falz d Bahd Guy tí ó dẹrin pani jọjọ nínú fíìmù naa.[2] Ni ọjọ́ kẹtà-lé-lógún òṣu kẹta ọdún 2018 ni a gbe fíìmù naa jade ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[3] Inkblot ati FilmOne tún pa'wọ́ pọ ṣe fíìmù lẹẹkan si lẹ́yin tí wọ́n ṣe fíìmù The Wedding Party 2.[4]

Àgbéka'lẹ̀ eré[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

New Money (Owó Tuntun) sọ ìtàn ọmọ ọdún mẹta-le-logun kan ti a npe ọrukọ rẹ ni Toun (Jemima Osunde), ti o ṣ'àdédé ba ara rẹ ni ààrin gbùngbùn ọrọ̀ nigbati baba rẹ (Kalu Ikeagwu) fi ilé iṣẹ́ rẹ ti o níye lori to ọ̀pọ̀lọpọ̀ bilionu sílẹ̀ fún un nínú ìwé ìpìngún rẹ̀. Èròngbà tirẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ ni láti di ránṣọ-ránṣọ. Ó gbọ́ ìtàn lẹ́nu ìyá rẹ̀, Fatima (Kate Henshaw) wípé ìgbéyàwó alárédè ni òun ṣe pẹ̀lú bàbá rẹ̀, Ifeanyi (Kalu Ikeagwu); ṣùgbọ́n, nítorí ìlòdì sí àwọn ẹbí Ifeanyi, wọ́n tú ìgbéyàwó naa ka. Ifeanyi wá tún ìgbéyàwó miran ṣe pẹ̀lú Ebube (Dakore Akande), eleyi ti ko sì sí ọmọ kankan laarin wọn.

Toun kọ eti'kun sí ìyá rẹ̀, o si bẹrẹ si ni gbé igbe aye afẹ́ ti arakunrin baba rẹ̀, Chuka (Wale Ojo) ati ọmọ rẹ̀, Patrick (Adeolu Adefarasin) gbiyanju lati bajẹ mọ lọ́wọ́. Ìpinnu rẹ̀ yii so ile iṣẹ na sinu ọpọlọpọ ìṣòro, eleyi ti o si mu ki àwọn eniyan ri Toun gẹ́gẹ́ bi oludari ti ko kún ojú òsùwọ̀n.

  1. . 
  2. . 
  3. . 
  4. .