Nils Olav

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Coordinates: 55°56′40″N 3°16′20″W / 55.94444°N 3.27222°W / 55.94444; -3.27222

Sir Nils Olav
Sir Nils Olav
BornEdinburgh Zoo, Scotland
Service/branch Norwegian Army
Years of service1972–1987 (àkọ́kọ́), 1987–current (ẹ̀kejì)
RankColonel-in-Chief & mascot
UnitHans Majestet Kongens Garde

Colonel-in-Chief Sir Nils Olav jẹ́ ọba Penguin tí ó ń gbé ní Edinburgh Zoo, Scotland. Ó jẹ́ ẹran ọ̀sìn fún ológun tí wọ́n máa ń lò nígbà ayẹyẹ tàbí gẹ́gẹ́ bí ààmi àpẹẹrẹ[1][2][3] , tí ó sì jẹ́ Ọ̀gágún Colonel fun Royal Guard ti orílẹ̀ èdè Norway.  Àwọn ológun lati Norwegian Royal Guard bẹ Nils wò ní Ọjọ́ karùndílógún Oṣù kẹjọ Ọdún 2008 tí wọ́n sí fi oyè Knighthood dáa lọ́lá.[4]  King Harald V ni ó pàṣé wípé kí wọ́n fi oyè yìí dáa lọ́lá. Nígbà ayẹyẹ yìí, ènìyàn ọgọrún meje ló darapọ̀ mọ́ àwọn aṣọ́gbà ẹranko 130 lati gbọ́ gbólóhun tí ọba kà jade tí ó ṣàpèjúwe Nils gẹ́gẹ́ bíi penguin "tí ó pójúùwọ̀n ní gbogbo ọnà lati gba ọlá àti iyì knighthood".[5] Orúkọ 'Nils Olav' yìí ní wọ̣́n tún fún àwọn king penguins méjì tí ó wà lẹ́yin Nils Olav lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí gẹ́gẹ́ bíi Ọba Aṣọ́gbà másíkọ́ọ̀tí.[6]

Ipá ẹ̀ nínú ológun[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Norway – tí aṣàwákiri ọmọ orílẹ̀ èdè yìí, Roald Amundsen jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ dé Òpo tó wà ní Gúúsù ní Ọdún 1911 – ta ọgbà ẹranko lọ́rẹ pẹ̀lú king penguin àkọ́kọ́ ẹ̀ nigbà tí wọ́n ṣíi ní Ọdún 1913.[5] Nígba tí àwọn onísẹ́ ọba bẹ Edinburgh Military Tattoo ní Ọdún 1961 fún ẹ̀kọ́ bí aṣelè dojú kọ ogun, ògágun lieutenant tí wọ́n ń pè ní Nils Egelien nífẹ sí ìletò penguin ní Edinburgh Zoo yìí. Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ yìí padà sí Edinburgh lẹ́ẹ̀kan síi ní Ọdún 1972, ó ṣètò bi àkójọ yìí ṣe máa gba penguin wọlé. Wọ́n sọ orúkọ penguin yìí ní Nils Olav fún ìyẹ́sí Nils Egelien, àti King Olav V of Norway.

Sir Nils ṣe àyẹ̀wò fún àwọn ọmọ ogun ti Royal Guard, tí òhun sì jẹ́ Ọ̀gágun, nígba ayẹyẹ oyè knighthood ẹ̀ ní Ọdún 2008

Wọ́n fún Sir Nils Olav ní oyè visekorporal (lance corporal) wọ́n sì maa ń foyè kún oyè rẹ̀ nígbàkúgbà tí àwọn oníṣẹ́ ọba ba padà sí ọgbà ẹranko. Ní Ọdún 1982, ó di corporal, tí ó sì di sergeant ní Ọdún 1982. Nils Olav kú lẹ́yìn ígbà díẹ̀ tí ó di sergeant, Nils Olav II sì gba ipò ọlá ẹ. Ó ní ìgbéga ní ọdún 1993 sí oyè regimental sergeant major. Ni ́ Ọjọ́ kejìlélógún Oṣù kẹjo Ọdún 2005, wọ́n yàán ní Colonel-in-Chief[7], Ni ́ Ọjọ́ kejìlélógún Oṣù kẹjo Ọdún 2008 wọ́n fí oyè knighthood dáa lọ́lá. Ó jẹ́ penguin àkọ́kọ́ tí ó gba írú ọlá bẹ́ẹ̀ ní ológun orílẹ̀ èdè Norway.[8] Bákan náà, wọ́n fún Ọgbà èranko Edinburgh ní ère idẹ Nils Olav  tí ó tó ẹsẹ bàtà mẹrin (1.2 m). Wọ́n fí ère yìí ṣèrántí oníṣẹ́ ọba àti ọnà olọgun. Ère kan náà wà níwájú àgbàlá Royal Norwegian Guard ní Huseby, Oslo. Ní Norway, wọ́n máa ń pèé ní ẹran ọ̀sìn Oníṣẹ́ Ọba, bíótilẹ̀jẹ́pé orúkọ tí wọ́n kọ síwájú ère yìí ń tọka sí oyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Colonel-in-Chief.

Ère idẹ Nils Olav

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Sir Nils Olav". EdinburgZoo.com. Archived from the original on May 28, 2013. Retrieved June 4, 2013. 
  2. Panganiban, Roma (April 4, 2013). "Sir Nils Olav, Norway's Penguin Knight". mentalfloss.com. Retrieved June 4, 2013. 
  3. "Military penguin becomes a 'sir'". BBC.co.uk. August 15, 2008. Retrieved June 4, 2013. 
  4. "King penguin receives Norwegian knighthood". 15 August 2008.
  5. 5.0 5.1 "Military penguin becomes a 'Sir'". BBC News. 15 August 2008. http://news.bbc.co.uk/1/hi/scotland/edinburgh_and_east/7562773.stm. Retrieved 14 August 2008. 
  6. "Norwegian Knight". Scandinavian Press 15 (4): p. 9. Fall 2008. 
  7. "Norwegian Consulate in Edinburgh.". Archived from the original on 2006-10-01. Retrieved 2016-06-12. 
  8. "Penguin power: Norwegian regiment honours pint-sized chief". ABC News (Sydney). 16 August 2008. http://www.abc.net.au/news/stories/2008/08/16/2337646.htm. 

Àwọn àjápọ̀ látì ìta[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]