Nwando Achebe

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Nwando Achebe
OrúkọNwando Achebe
Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́West Africanist, apìtàn àtenudẹ́nu, ajàfẹ́tọ́ obìnrin
Ìjẹlógún ganganObinrin, ìtàn àtenudẹ́nu, ọ̀rọ̀ ilẹ̀ Áfríkà àti ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Afrika

Nwando Achebe /θj/ (tí a bí ní ọjọ́ keje oṣù kẹta ọdún 1970) jẹ́ ọ̀mọ̀wé àti ajàfẹ́tọ́ obìnrin ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Òun ni adarí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nípa kíkó ara ẹni mọ́ra ní College of Social Science[2] tí ilé-ìwé Michigan State University. Òun tún ni Akọ̀ròyìn àgbà fún Journal of West African History.[3]

Ìpìlẹ̀ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Nwando Achebe sí Enugu, ní ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà[4] sínú ìdílé, Chinua Achebe, àti Christie Chinwe Achebe, Chinua Achebe jẹ́ òǹkọ̀wé àti akéwì, ìyàwó rẹ̀, Christie sì jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ Ẹ̀kọ́.[5] Nwando ni ìyàwó Folu Ogundimu, òjògbón nínú ìmò kíkọ ìròyìn ní Michigan State University, àti ìyá ọmọbìnrin kan, Chino.[6] Ẹ̀gbọ́n Nwando, Chidi Chike Achebe jẹ́ oníṣègùn òyìnbó.

Ètò ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Achebe gba àmì-ẹ̀yẹ Ph.D. nínú ìmò Ìtàn ilẹ̀ AfrikaUniversity of California, Los Angeles ni ọdún 2000. Ó jẹ́ amòye nínú ìtàn àtenudẹ́nu, pápá jùlọ nínú ìmò Ìtàn Ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Áfríkà. Ipò àkọ́kọ́ tó dìmú nínú ètò ẹ̀kọ́ ni igbákejì òjògbón nínú ìmò ìtàn ní College of William and Mary, kí ó tó lọ sí Michigan State University ní ọdún 2005 láti tún di ìgbàkejì ọ̀jọ̀gbọ́n fún ìgbà díè, Achebe di ọ̀jọ̀gbọ́n ní ọdún 2010.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Woodrow Wilson National Fellowship Foundation. "Seeing The Whole Dance: Nwando Achebe WS '00 Brings New Perspective to African Women's Power". Retrieved 11 May 2017. 
  2. "Associate Dean of Diversity, Equity, and Inclusion". Retrieved 15 August 2020. 
  3. OkayAfrica International Edition. "Why It is Crucial to Locate the "African" in African Studies". okayafrica.com. Retrieved 11 May 2017. 
  4. Daily Trust Newspaper. "Nigeria: Nwando Achebe--The Woman and Her Works". All Africa. Retrieved 13 May 2017. 
  5. Offiong, Vanessa. "Nigeria: Nwando Achebe--The Woman and Her Works". AllAfrica. Retrieved 11 May 2017. 
  6. "Meet the Winner of the 2013 Aidoo-Snyder Prize--Dr. Nwando Achebe". African Studies Association. Archived from the original on 31 March 2017. Retrieved 13 May 2017.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)