Egbògi Alábùkún

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Oògùn Alábùkún)

Egbògi Alábùkún jẹ́ oògùn tí olóògbé Jacob Ṣógbóyèga Odùlatẹ̀ ṣàwárí rẹ̀ ní ọdún 1981, lásìkò tí ìmúnisìn àwọn Gẹ̀ẹ́sì ilẹ̀ Britain lágbara gidi. Oògùn yí .[1][2] Púpọ̀ nínú àwọn èlò oògùn yí ni wọ́n kó jọ láti ìlú Liverpool.

Àwọn èròjà inú egbògi náà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awọn ohun èlò tí wọ́n fi se egbògi Alábùkún oníyẹ̀fun ni

  • acetylsalicylic acid àti caffeine. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ojú-lówó jùlọ tí iye èròja acetylsalicylic acid sì jẹ́ 760 mg nígbàbtí èlò caffeine jẹ́ 60 mg tí àpapọ̀ èlò méjèjì yí jẹ́ 820 mg.

Ìwúlò egbògi yí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lára àwọn ohun tí wọ́n ma ń lo egbògi yí fún ni:

  1. gbọ̀fun gbọ̀fun (sore throat]],
  2. akokoro (thoothache),
  3. ẹ̀jẹ̀ dídì(blood cloth) ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[3]

Ìmọ̀ ìwádí ìjìnlẹ̀ ní oògùn ati egbògi sọ wípé Alábùkún ma ń dèna ìfúnpọ̀ tàbí dídìpọ̀ ẹ̀jẹ̀ ní agọ́ ara. Ó tun ń ṣiṣẹ́ fún ara ríro, ó sì ma ń jẹ́ kí ẹni tí ó bá lòó ó mí sókè sódò dára dára.

Ìpalára egbògi yí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n fi kun wípé bí a bá si egbògi yí lò, ó lè fa àwọn àìsàn wọ̀nyín nínú ara.:

Egbògi yí gbajúmọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó ṣì fi wà lórí àtẹ láti nkan bí ọgọ́rún ùn ọdún sẹ́yìn tí tí di òní. Àwọn orílẹ̀-èdè bí Nàìjíríà, Benin Cameroon, Ghana àti àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ Europe náà ni wọ́n ti ń lo egbògi yí.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Admin. "The life and times of Jacob odulate". News Headlines. Retrieved 7 February 2017. 
  2. Admin. "Yoruba who have made us proud". Yoruba Parapo. Retrieved 7 February 2017. 
  3. EDWARD-EKPU, UWAGBALE. "The Nigerian pharmacist who invented alabukun powder 100 years ago". Science Tech Africa. Archived from the original on 7 February 2017. Retrieved 7 February 2017.