Jump to content

Ogedengbe Agbogungboro

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ògèdèngbé Agbógungbórò jẹ́ ìnagijẹ fún jagun jagun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọ̀rìṣàráyíbí Ògúnmọ́lá. Ògèdèngbé jẹ́ akínkanjú, alágbára àti jagun jagun ọmọ bíbí ìlú IléṣàÌpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[1] Ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn olórí ogun nínú ìtàn ilẹ̀ Yorùbá. Òun ni adarí ogun àwọn ọmọ ogun Èkìtì-Parapọ̀.

Ìgbé ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ológun

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bi ní ìlú Ijọ̀kà kí wọ́n tó gbe lọ sí Àtorin ní ìtòsí ìlú Iléṣà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní ọdún 1822. Orúkọ rẹ̀ Ògèdèngbé ní ó gbà níbí ìṣe akínkanjú rẹ̀ ní eré Ìjàkadì tí ó jẹ́ ọ̀kan lára eré ìdárayá tí àwọn ọ̀dọ́ ma ń ṣe láti fi kọ́ nípa ìwà ìgboyà àti akínkanjú láyé àti àtijọ́. Agbógungbórò ni àwọn ènìyàn fi kun nígbà tí ipò ogun jíjà rẹ̀ gòkè àgbà si. Ògèdèngbé dàgbà nígbà tí ìjà òun ogun abẹ́lé ń ṣẹlẹ̀ látàrí ìjà àgbà láàrín àwọn ọmọ Oòduà. Ọ̀Pọ̀ ìgbà ni òun náà ti báwọn fẹ̀hónú hàn sí ìwà ìrẹ́jẹ àti ìjẹ gàba ilẹ̀ Ìbàdàn tí ó Ma ń kógun ja ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà. Nínú ikan nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni oguu Ìgbájọ tí ó ṣẹlẹ̀ ní 1867, nínú ogun yí ni wọ́n ti mú Ògèdèngbé lẹ́rú, ní àsìkò ìṣẹrú sìn rẹ̀ yí ni a ti gbọ́ wípé ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Ìbàdàn ti bẹ́ Ògèdèngbé lórí, àmọ́ tí ó ta gọ̀ọ́ gọ̀ọ́ lọ gbé orí rẹ̀ tí wọ́n ti be kúrò tí ó sì gbe sí ọr ún rẹ̀ padà. Èyí ya gbogbo àwọn jagun jagun ilẹ̀ Ìbàdàn lẹ́nu púpọ̀, èyí ló mú Náàọ̀run Ògúnmọ́lá mu lọ sí ilẹ̀ Ìbàdàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun tí ó sì ja fita fita fún ilẹ̀ Ìbàdàn tó fi dépò adarí ogun ilẹ̀ Ìbàd. Wọ́n kọ ilà Ìbàdàn fun kí àwọn ọ̀tá Ìbàdàn lè pa sógun lérò pé ọmọ bíbí ilẹ̀ Ìbàdàn ni. [2]

Lẹ́yìn tí Yorùbá ìṣubú ìjọba Ọ̀yọ́ Ilé, ilẹ̀ Ìbàdàn dìde ní nkan bí ọdún 1820s tí wọ́n sì ń jẹ gàba lórí àwọn ọmọ Yorùbá tókù. Ìjẹ gàba yí ni ó dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun sílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, lára àwọn ogun náà ni Ogun Kírìjí. Ogun yí wọ́n sọ lórúkọ Kírìjí látàrí iró Bọ́mbù oníkẹ̀kẹ́ tí àwọn ọmọ ogun Èkìtì àti Ijẹ́ṣà ń yín tí ó sì ń ro Kiri.[3]

Lábẹ́ ìdarí Ògèdèngbé. Ogun Kírìjì ni ó wáyé láàrín ilẹ̀ Ìbàdàn, Modákẹ́kẹ́, Ọ̀yọ́, àti Ọ̀fà gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ kan, nígbà tí ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà, Èkìtì, Àkókó, Ifẹ̀, Ìgbómìnà, Kàbbà, Ẹ̀gbẹ̀ àti Lọ́kọ́ja náà jẹ́ ikọ̀ mìíràn. [4] [5]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Historical Figure: Ogedengbe of Ijeshaland -". The NEWS. Aug 1, 2015. Archived from the original on January 13, 2020. Retrieved Jan 13, 2020. 
  2. HiztoryBox (Aug 21, 2018). "Ogedengbe The Itinerant Warrior". HiztoryBox. Archived from the original on January 13, 2020. Retrieved Jan 13, 2020. 
  3. "Ogedengbe Agbogungboro - Wars & Generals - ASIRI". ASIRI Magazine 2. 2014-05-05. Archived from the original on 2020-02-16. Retrieved 2020-03-03. 
  4. "Inside Ogedengbe’s house of war". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). Feb 16, 2013. Retrieved Jan 13, 2020. 
  5. "Ogedengbe Agbogungboro - Wars & Generals - ASIRI". ASIRI Magazine. 2014-05-05. Archived from the original on 2020-02-16. Retrieved 2020-03-03.