Jump to content

Olúfúnkẹ́ Bàrúwá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Olufunke Baruwa
Olúfúnkẹ́ Bàrúwá
Ọjọ́ìbí9 Oṣù Kọkànlá 1976 (1976-11-09) (ọmọ ọdún 48)
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́University of Abuja (BSc)
University of Nigeria, Nsukka (MBA)
University of East Anglia
University of York
Iṣẹ́Activist
OrganizationFord Foundation
Gbajúmọ̀ fúnGender, public policy and governance
Àwọn ọmọ2

Olúfúnkẹ́ Bàrúwá jẹ́ aṣègbèfábo àti sọ̀rọ̀sọ̀sọ̀ àwùjọ, pàápàá jù lọ lórí ìjọba àti ètò-ìṣèjọba ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Fún nǹkan bí ogún ọdún, ó ti jẹ́ gbajúmọ̀ àti ọkàn gbòógì nínú àwọn aṣáájú lámèyító lórí ètò-àyíká àti àtúnṣe lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba, àwọn àjọ abẹ́lé àti àjọ òkè-òkun alábàáṣepọ̀ mìíràn.

Bàrúwá kàwé gboyè Ifáfitì àkọ́kọ́ ní University of Abuja, bẹ́ẹ̀ ló kàwé gboyè kejì, (MBA) ní University of Nigeria, Nsukka (MBA), bẹ́ẹ̀ náà ló kàwé gboyè ní University of East Anglia àti University of York.

Bàrúwá di gbajúmọ̀ nípa iṣẹ́ ìṣàgbèfábo rẹ̀ nínú ètò òṣèlú, àwùjọ àti ọrọ̀-ajé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Lọ́dún 2000 sí 2015, Ó jẹ́ olùdarí ètò aléṣẹ̀ẹ́wọ̀gbẹ́ ìjọba àpapọ̀ àná, (National Poverty Eradication Programme), bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ agbani-nímọ̀ràn ní yàrá-iṣẹ́ ilé-ìṣe olùgbaninímọ̀ràn pàtàkì fún Ààrẹ Nigeria, bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ olùrannilọ́wọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ fún iṣẹ́ àkànṣe ìwádìí, ètò àti ìṣètò, Research, Policy & Planning ní ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ fún ìmọ̀-ẹrọ lórí ètò ìbánisọ̀rọ̀. Lọ́dún 2015, wọ́n yàn-án lẹ́yìn Ayisha Osori gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá-àgbà fún Nigerian Women Trust Fund, èyí àjọ ìkówójọ-àtinúwá fún irànlọ́wọ́ àwọn òṣèlú-bìnrin, níbi tí ó ti ṣe kòkárí àwọn ètò àti ète àtinúdá láti kówójọ àti ìfojúsùn ọjọ́ ọ̀la tó yanntírí.[2] Kí ó tó di ọ̀gá-àgbà ní Nigerian Women's Trust Fund, ó ṣiṣẹ́ ní àjọ àwọn adarí àgbà ìsúná-owó láti ọdún 2011 sí 2015.[3] bẹ́ẹ̀ lọ́dún 2018, wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bí akẹgbẹ́ ọ̀gá-àgbà tí ó gbapò lọ́wọ́ Amina Salihu. Lọ́dún yẹn bákan náà, ó dára pọ̀ mọ́ àjọ, the US Agency for International Development (USAID) / Nigeria as the Civil Society and Media Specialist in their Peace & Democratic Governance Office.

Lọ́dún 2020, Olufunke Bàrúwá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Ford Foundation, tí ẹ̀ka ike-iṣẹ́ ilẹ̀-adúláwò Áfíríkà, gẹ́gẹ́ bí aṣètò fún ètò ìṣàgbèfábo, ìdájọ́-ẹ̀tọ́ fún ẹlẹ́yàmẹ̀yà, níbi tí ó ti ṣe agbátẹrù ìfòpin sí ìfabojìyà.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]