Old Town of Prague

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Old Town Square in Prague

Old Town of Prague (Tsẹ́kì: [Staré Město pražské] error: {{lang}}: text has italic markup (help)) nibó jẹ́ ìletò kan tí ó ti wà tipẹ́ ní ìlú Prague, ní orílẹ̀-èdè Czech Republic. Wọ́n yà á sọ́tọ̀ láti ìta pẹ̀lú odi kérébété kan tí wọ́n pè ní Vltava tí ó sì ní odò ní apá ọ̀tún ati apá òsì. Kòtò yí ni wọ́n fi òpópó oríṣiríṣi bò mọ́lẹ̀ láti apá (north sí south-west) Revoluční, Na Příkopě, àti ìyẹn Národní tí ó sì jẹ́ ààlà fún abúlé cadastral Old Town. Àmọ́ ó ti di ìkan lára Prague 1 nísìnyí.

Lára àwọn ibi tí wọ́n gbajúmọ̀ ní Old Town ni: Old Town Square àti Astronomical Clock. Old Town ni àwọn ìlú bíi New Town of Prague yí po. Nísọdá afárá odò Vltava tí ó so afárá Charles Bridge ni Lesser Town of Prague (Tsẹ́kì: [Malá Strana] error: {{lang}}: text has italic markup (help)). Ìlú àwọn Júù tẹ́lẹ̀ (Josefov) nió wà ní apá àríwá Old Town tí ó dojú kọ ìlú Vltava.

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Old Town with Charles Bridge in 1840
Charles Bridge connects Old Town with Lesser Town

Láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ní nkan bí ọ̀rùndún kẹsàán, Staré Město ni ó wà ní apá ibi tí ọjà wà nítòsí odò Vltava. Àkọsílẹ̀ tí wọ́n ti kọ sílẹ̀ ní nkan bí ọdún 1100 AD ni ó fi hàn wípé ní gbogbo ọjọ́ Àbámẹ́ta ni wọ́n ma ń nájà, tí ìpàdé awọn ológun tí wọn kò lónkà náà ma ń wáyé níbẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn olùnájà oríṣiríṣi ni wọ́n ti tara ọjà yí lówó lọ́wọ́, ati wípé Ọb Wenceslaus I of Bohemia tún fún wọn ní ànfaní láti dá ìlú Prague (Město pražské) sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ akọsílẹ̀ ayé atijọ́ ti fi lélẹ̀, ìlú yí ní géètì tí ó tó mẹ́talá níye , tí ó sì tún ní kòtò ńlá kan yíká ìlú náà láti lè fi ṣe àabò fún ìlú náà lọ́wọ́ ìkọlù.

Ní ọdún 1338, Ọba ìlú Bohemia ìyẹ Jhon of Luxembourg fún alámòójútó abẹ́lé ní àṣẹ láti láti ra ilé ẹbí kan lọwọ́ ẹbí Volfin od Kamene (), ilé tí wọ́n rà yí ni wọ́ n sọ di Ilé ìlú títí di òní.[1][2] Ní nkan bí àárí ln ọ̀rùndún kẹrìnlá, ìlú Old Town bẹ̀rẹ̀ sí ń gbòòrò si látàrí akitiyan àwọn ọlọ́jà àti àwọn ohun atinúdá ọgbọ́n inú tí wọ́n pèsè tí wọ́n sì ń tà lọ́jà wọn, èyí mu kí ó di ojúkò okòwò fún ààrin gbùngbùn Yúróòpù ati agbègb3 rẹ̀. Òkìkí ìlú Old Town ń gbilẹ̀ si pàá pàá jùlọ nígbà tí ọba Bohemia Charles IV jẹ tí ó sì tún di Roman Empror ní ọdún 1355, òkìkí yí túbọ̀ pọ̀ si. Látàrí jíjẹ ọba yí, àwọn ènìyàn bá ṣíjú sí ìlú Prague tí ó jẹ́ ìlú tí ọba náà ti wá. Wọ́n tún ilé ìlú náà kọ́ sí pẹ̀tẹ́sì alájà gogoro tí ó ń fi agbára àti ipò patàkì tí ọba náà wà hàn lára ìlú rẹ̀. Nígbà tí awọn yóò fi parí kíkọ́ ilé ìlú náà tán ní ọdún 1364, ilé náà ni ó ga tí ó sì rẹwà jùlọ nínú ìlú náà.[2]

Lẹ́yìn tí wọ́n fẹ ìlú náà lójú síwájú si, ní ọ̀rùndún kẹrìnlá, tí wọ́n sì ti kọ́ ilé ìlú tuntun fún wọn, wọ́n pa gbogbo kòtò tí wọ́n gbẹ́ yíká odi ìlú náà rẹ́ pátá.

Gallus Market (Havelské tržiště)

Ní ọdún 1348, ni wọ́n dá University of Prague sílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Charles IV. Ọba yí tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ new bridge ní ọdún 1357 sórí odò tí Vltava tí yóò so Old Town pọ̀ mọ́ Lesser Town of Prague. Ọdún 1391, ni wọ́n kọ́ ilé ìjọsìn Bethlehem Chapel sí Czech. Ilé-ìjọsìn yí kó ipa ribiribi nínú Ìṣàtúnṣe sí Bohemian àti Hussite movement. Ajíyìnrere Jan Hus ni ó lo iléjọ̀sìn láàrín ọdún 1402–1413 láti fi ṣe ìwàásù .[1]

Iná kan tí wọ́n ń pè ní (French fire) ni ó jà ní ọdún 1689 tí ó sì run ọ̀pọ̀ ohun ìní ní Old Town tí ó fi mọ́ ìlú kan tí ó sún mọ́ wọn tí wọ́n ń pè ní Jewish Town. Ní ọdún 1784, àwọn ìlú mẹ́rin tí wọ́n múlé ti ara wọn ni wọ́n kóra pọ̀ tí wọ́n ń pè ní Royal Capital City of Prague lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo.

Àwọn àwòrán[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Wikivoyage


  1. 1.0 1.1 Prague: City Guidebook. Praha: Kartografie Praha. 2000. p. 6. 
  2. 2.0 2.1 Míka, Alois (1968). Staroměstská radince a náměstí: Old Town Hall and Square: Altstädter Rathaus und Ring. Praha: Olympia. pp. 20–21. 

Wo èyí náà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn àyọka tí a sopọ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Districts and cadastral areas of Prague

Coordinates: 50°05′17″N 14°25′20″E / 50.08806°N 14.42222°E / 50.08806; 14.42222 Àdàkọ:Authority control