Jump to content

Olowu ti ilu Owu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Olowu ti ilu Owu jẹ́ ọba aládé ìlú Owu.

Àwọn ọmọọba tí wọ́n yàn láti ìdílé ọba mẹ́fa tí ń ṣe; Amororo, Otileta, Ayoloye, Akinjobi, Akinoso àti Lagbedu ló ń darí ìlú Òwu.[1] Àwọn Ògbóni àti àwọn ológun ló máa ń ran ọba lọ́wọ́. Balógun ló jẹ́ olórí àwọn ìjòyè, lábẹ́ rẹ̀ ni a sì rí Otun, Osi, Seriki, Aare Ago àti Jagunna. Lára àwọn olóyè Ogboni ni Akogun, Obamaja, Orunto, Oyega, Osupori àti Omolasin. Olosi ni adífálà ìlú Òwu àti Olowu. Láti ìpìlẹ̀, ìlú Òwu ní ìletò mẹ́ta, tí ń ṣe eyun Owu, Erunmu àti Apomu. Nínú ìṣẹ̀ṣe, àwọn afọbajẹ mẹ́fà ló máa ń yan Olówu, àmọ́ wọ́n ti fi olóyè méjì kún un ní ọdún 1964, tí ń ṣe Balogun àti Olosi.

Àṣà Ogboni ò sí lára àwọn àṣà ará ìlú Òwu tẹ́lẹ̀. Ọwọ́ à̀wọn Egba ni wọ́n ti ya, lẹ́yìn tí àwọn Òwu tẹ̀dó sí ìlú Abeokuta. Èyí sì ni ìdí tí àwọn Owu ò ní Ilédì (ilé Ògbóni) títí dòní.

Ní ọdún 2006, lábẹ́ àsìkò ìjọba Olówu, Ọba Olusanya Adegboyega Dosunmu (Amororo II), wọ́n ṣàtúntò ètò ìṣèlú. Wọ́n tún ètò ìṣejọba Ògbóni àti Ológun tò, wọ́n sì yan ìgbìmọ̀ tuntun tí á máa ṣe ìjọba. Lára ìgbìmọ̀ yìí ni a tí ní olóyè méje kan, tí ń ṣe:[2]

 • Balogun
 • Olórí Ìgbìmọ̀
 • Olórí Ọmọọba
 • Olórí Parakoyi
 • Balogun Apomu
 • Oluroko, Oba of Erunmu
 • Iyalode

Àtòjọ àwọn Olówu ti ìlú Òwu tó ti jẹ sẹ́yìn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
 • Oba Pawu 1855-1867 (OTILETA Family)
 • Oba Adefowote 1867-1872 (OTILETA Family)
 • Oba Aderinmoye 1873-1890 (OTILETA Family)
 • Oba Adepegba 1893-1905 (AYOLOYE Family)
 • Oba Owokokade 1906-1918 (OTILETA Family)
 • Oba Dosunmu 1918-1924 (AMORORO Family)
 • Oba Adesina 1924-1936 (OTILETA Family)
 • Oba Adelani Gbogboade 1938-1946 (OTILETA Family)
 • Oba Salami Gbadela Ajibola 1949-1972 (AYOLOYE Family)
 • Oba Adebowale Oyegbade 1975-1980 (AKINJOBI Family)
 • OBA Michael Oyelekan April 29th, 1987 -May 8th, 1987 (AKINOSO Family)
 • Oba Olawale Adisa Odeleye 1993-2003 (LAGBEDU Family)
 • Oba Adegboyega Dosunmu Amororo II láti ọdún 2005 (AMORORO Family) (ó ti wàjà)
 • Oba Ojogbon. Saka Adelola Matemilola Oluyalo Otileta VII láti ọdún 2022 - títí dòní (OTILETA Family)[3]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
 1. Online, Tribune (2022-08-05). "History, origin of Owu kingdom and past Olowu of Owu". Tribune Online. Retrieved 2023-03-22. 
 2. "New Olowu begins traditional rites, meets Obasanjo". Punch Newspapers. 2022-08-01. Retrieved 2023-03-22. 
 3. Nigeria, Guardian (2022-09-08). "Matemilola to succeed Dosunmu as Olowu of Owu Kingdom". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Archived from the original on 2023-03-22. Retrieved 2023-03-22.