Ìyálóde

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìyálóde jẹ́ obìnrin onípò gíga nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìlú ìbílẹ̀ Yorùbá. Lóde òní, àwọn ọba ló ń fi obìnrin joyè Ìyálóde, àmọ́ lọ́dún 2002 Njoku ṣàlàyé pé láyé àtijọ́ nílẹ̀ Yorùbá, ìlànà ìyannisípò gẹ́gẹ́ bí Ìyálóde kò jẹ mọ́ ìpinnu ọba. Kàkà bẹ́ẹ̀, yálà a ó fi obìnrin joyè ìyálóde tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, dá lórí àṣeyọrí àti ìkópa nínú ìgbòkègbodò — ìyẹn ló mú wa bọlá fún un pàápàá tó bá dọ̀ràn ọrọ̀ ajé àti ìṣèlú. [1]

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nítorí náà, nínú ìtàn, kì í wulẹ̀ ṣe pé Ìyálóde ń ṣojú fáwọn obìnrin ní àjọ ìgbìmọ̀, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ọ̀kan lára olùdarí ìṣèlú àti ọrọ̀ ajé ní ìjọba ìbílẹ̀ Yorùbá.

Nínú ìtàn àròsọ Yorùbá, a tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí "ọba obìnrin", àbá Ìyálóde ni ìjòyè máa ń jíròrò nípa ní ìgbìmọ̀. Lọ́dún 2017, Ọlátúnjí ti Yunifásítì Táí Ṣólàárín fi ojúṣe Ìyálóde wé ojú ìwòye ìṣègbèfábo lóde òní. Ó wá ṣàlàyé pé Ìyálóde ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún, Ìyálóde Tinúbú, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n lọ́rọ̀ jù nílẹ̀ Yorùbá, ó sì kópa pàtàkì nínú ìpinnu ẹni tí yóò jọba nílùú méjèèjì Èkó - ibi tí ó fẹ́ ọba - àti nílẹ̀ Ẹ̀gbá - ibi tí ó ṣètìlẹ́yìn fún àwọn Ẹ̀gbá ẹlẹ́yà rẹ̀ nígbà ogun. [2]

Mosádomi sọ pé ipa tí Ìyálóde kó, kò mọ sọ́dọ̀ àwọn obìnrin nìkan, ṣùgbọ́n ó tún ní í ṣe pẹ̀lú gbogbo ìṣèlú, àṣà àti ẹ̀sìn Yorùbá. Ó mẹ́nu kan Tinúbú àti Ẹfúnṣetán Aníwúrà bí àpẹẹrẹ tó hàn gbangba. [3] [4] Sofola (1991) jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí, ní sísọ pé “Bó ti wù kí ọba lágbára tó, kò lè gbapò Ìyálóde láéláé”. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọláṣùpọ̀ ṣe sọ, àṣẹ tí Ìyálóde pa lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lóde òní ò pọ̀ bí i ti tẹ́lẹ̀. Aláàfin Ọ̀yọ́, Làmídì Adéyẹmí, tọ́ka sí ìparun àṣà tìtorí àṣà “ìgbàlódé” gẹ́gẹ́ bí èrèdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó rántí pé láàárín àwọn ìgbìmọ̀ olùdarí, àwọn obìnrin ní ipò pàtàkì tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. [5] Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ní Tinúbú lẹ́nu láwùjọ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó dá Ọba ìlú Èkó dúró kó má ṣe fi Èkó lé àwọn Gẹ̀ẹ́sì lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀.

Ìyálóde ìsinsìnyí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olóyè Àlàbá Lawson ni Ìyálóde ilẹ̀ Yorùbá nísinsìnyí, Aláàfin Ọ̀yọ́ ló fi í joyè yìí lọ́dún 2008. [6] Ṣáájú ìyẹn, Ìyálóde ilẹ̀ Ẹ̀gbá ni.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 

  1. "WOMEN IN NIGERIAN HISTORY: AN EVALUATION OF THE PLACE OF, AND VALUES ACCORDED TO WOMEN IN NIGERIA" (PDF). Journal of Research in Arts and Social Science. June 1, 2014. Retrieved 2018-08-03.
  2. "FEMINISM AND THE CHANGE MANTRA IN AKINWUNMI ISOLA'S DRAMATIC TEXT OF MADAM EFUNROYE TINUBU: THE IYALODE EGBA" (PDF). A Journal of the Society of Nigeria Theatre Artists (SONTA). Retrieved 2018-08-03.
  3. "CHIEFTAINCY TITLES IN YORUBALAND AND THEIR IMPLICATION FOR GROWTH AND TOLERANCE AMONG CHRISTIANS AND MUSLIMS". LUMINA.
  4. "The Yoruba Iyalode". A Journal of Culture and African Women Studies. Retrieved 2018-08-03.
  5. Okwuofu, Osheye (October 25, 2017). "Alaba Lawson: The making of Iyalode of Yoruba land". Retrieved 2018-08-03.
  6. Seye, Kehinde (May 16, 2017). "LIFE AS IYALODE OF EGBALAND & YORUBALAND, •CITY PEOPLE SPENDS 2 HOURS WITH IYALODE ALABA LAWSON". City People. Retrieved 2018-08-03.