Oníṣe:Agbalagba/Razaq Okoya (1)
Razak Akanni Okoya | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 12 Oṣù Kínní 1940 Lagos, Nigeria[1] |
Ibùgbé | "Oluwa ni Shola" Estate, Ajah, Lagos, Nigeria |
Iṣẹ́ | Billionaire industrialist, chairman of the Eleganza Group and the RAO Property Investment Company[1] |
Olólùfẹ́ |
|
Àwọn ọmọ | |
Parent(s) | |
Àwọn olùbátan | Wosilat Okoya (sister)[2] |
Website | eleganzagroups.com |
Oloye Razak Akanni Okoya ni won bi ni ipinle Eko ni ojo Kejila Osu Kini,odun 1940 (12 January 1940). O je onilese okowo ti o to bilionu naira ati Aare fun ipinle Eko.[5] O keko akobere re nile eko alakoobere ti Ansar-un-deen, Oke popo, ni ipinle Eko. Oun ni alase ati oludasile ile ise akojopo Eleganza, ti o n ta oja jake jado ile Adulawo (Western Africa).
Ibere igbesi aye re
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oloye Razak Okoya je omo Yoruba lati ariwa iwo Oorun(south-western) Naijiria. Won bi ni ididle ogbeni Tiamiyu Ayinde Okoya ni ilu Eko . O sise pelu baba re gege bi aranso ti baba re je, ti won si tun n ta awon ohun elo iranso pelu .[6] Imo ti o ni lo fun ni igboya lati da duro funra re gege bi oga. O tu owo jo ti o fi pe ogun Poun (20 Pounds), ti iya re naa si raan lowo pelu aadota Poun (50 Pounds),[7] lati fi bere owo tita ati rira lati ile Japan.
Ise okowo re
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ile ise Razak Okoya gbooro kia, o si n serin ajo kaakiri lati mo nipa bi won se n pese nkan ti o nigbagbo wipe won yoo se se ni orile ede Naijiria bi tawon toku .
Iyawo re akoko ti oruko re n je Kuburat Okoya, ni o feran ki o ma ra awon ohun oso ara jewellery pamo ti Razak si ma n semo nipa bi won se won to. O mo wipe iye owo awon oso ara wonyi ko kere, atipe oun le ma se won nile Naijiria igba ti owo ohun ipese re ko won ni ile Naijiria. Okoya tun rin iri ajo lo si ile okere lati ra ero ti o le pese awon ohun oso ara naa. Nigba ti o bere si ni pese re ni ona ara ti o si n taa ni owo pooku, awon eniyan boo apa re ko si fe ka bi awon eniyan se n beere fun oja re mo. Eyi ni o bere ile ipese ile ise ohun oso ara jewellery re.
O bere kiko awon bata gidi lopo yanturu, lai moye igba ni awon oja re kii tete de pelu bi o se n tete san owo asan sile. O serin ajo lo ile Italy lati ri awon ti won n se bata naa, iyalenu lo je fun wipe won ti fi owo oja re san gbese tiwon. Bayi ni o se pinu lati da ile ise bata tire naa sile. O ra awon ero to lagbara lati sise naa ti o si gba awon akose-mose lati ko awon osise re ni ile Naijiria bi won se n pese bata.
Loni, labe akoso re,ile ise Eleganza ti n pese orisirisi ohun elo ile. Awon ile ise re wa ni: 'Oregun-Ikeja, Isolo, Alaba and Iganmu' ti o ti gba o le ni egberun marun osise ti o je omo orile ede Naijiria ati awon ajoji. Ile ise akojopo Eleganza je okan lara awon ile ise to laami laka jake jado ile Naijiria , ti o si tun ni o kere tan mefa kaakiri awon orile ede to sunmo ile Naijiria.
O ti gba ami eye idani-lola fun idi aseyori okowo re gege bi Oludasile ise ara-eni asiko tiwa (Business Entrepreneur of Our Time) lati owo iwe iroyin Thisday Newspapers.[8]
Awon oro ojogbon re
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]"Nile iwe, mo ni anfani lati sesa ise okowo nigba ti mo ri awon oluko mi ninu awon aso to ti gbo; ti mo si ri onise okowo to n wo aso pataki laarin oja Dosumu ti o je oju oja lEko nigba naa."[6]
" Mo ma n sora mi. Mi o si ki n wo aago alaago sise. Mo si ma n je ki ohun ti mo bani o temi lorun. Mi o si ki n wa owo ofe. Bakan naa ni mi o ki n je ki oselu o wo mi loju. "[6]
"A o ki n fi igberaga se owo. Ohun ti a ma n wo ni pipese ohun ti awon eniyan le ra lowo pooku.Eyi je okan lara asiri mi." [6]
"Ohun ti o je iwuri fun mi ni wipe mo fe je olola, mo si mo wipe mo ti sise gidigidi lati de ipo naa."[6]
"Mi o ni ero kero si kikekoo. Sugbon nigba miran, iwe kika ma n se awon eniyan ni akin ti kii se ooto. O ma n je ki won fokan bale lori iwe eri won laisakitiyan lati ni ola."
Awon omo re
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oloye Razak Okoya bi omo maruun. Awon omo naa ni: Sade Okoya, Olamide Okoya, Subomi Okoya, Oyinlola Okoya, ati Wahab Okoya.
Awon iyawo re
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oloye Razak Okoya ni awon iyawo to po seyin. Sugbon, eyi ti o wa loju opon lowo ni iya Afin Folasade Okoya ti Oloye Razak Okoya so wipe o ma sise kara kara. Oun naa lo bi awon (Olamide, Oyinlola, Subomi and Wahab) fun. Sade paa paa ti gba opo ami eye idani-lola gege bi eni to mo araamu julo ti awon eiyan si n kose re.
Awon itoka si
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 Lanre-Aremu, Kemi (19 January 2014). "I like to be stylish". Punch. Archived from the original on 28 March 2014. https://web.archive.org/web/20140328210349/http://www.punchng.com/spice/personalities/i-like-to-be-stylish-razaq-okoya/. Retrieved 28 March 2014.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 "From Ghetto To Wealth: The Story Of Sade Okoya – How She took over Okoya’s household". Global News. http://www.globalnewsnig.com/from-ghetto-to-wealth-the-story-of-sade-okoya-how-she-took-over-okoyas-household/. Retrieved 28 March 2014.
- ↑ "We were brought up to see realities of life — Okoya, Director, Fico Solutions". Nigerian Best Forum. Retrieved 28 March 2014.
- ↑ "Razaq Okoya – Eleganza Group". Financial Freedom Inspiration. Archived from the original on 28 March 2014.
- ↑ Lanre-Aremu, Kemi (16 March 2014). "Between Dupe Oguntade and Shade Okoya". Punch. Archived from the original on 24 March 2014. https://web.archive.org/web/20140324143216/http://www.punchng.com/spice/society/between-dupe-oguntade-and-shade-okoya/.
- ↑ 6.0 6.1 6.2 6.3 6.4 Sotunde, Oluwabusayo. "Portrait of a Mercurial Industrialist: Rasaq Akanni Okoya". Ventures Africa. Retrieved 28 March 2014.
- ↑ Olaode, Funke (12 January 2008). "Nigeria: My Mother Started Me Off in Business – Rasaq Akanni Okoya". This Day. http://allafrica.com/stories/200801140577.html. Retrieved 28 March 2014.
- ↑ "When Teachers Got Their Rewards on Earth". This Day. 3 March 2013. Archived from the original on 24 March 2014. https://web.archive.org/web/20140324143609/http://www.thisdaylive.com/articles/thisday-awards-when-teachers-got-their-rewards-on-earth/141078/. Retrieved 28 March 2014.
[[Ẹ̀ka:Àwọn ojọ́ìbí ní 1940]] [[Ẹ̀ka:Àwọn ènìyàn alààyè]] [[Ẹ̀ka:Àwọn oníṣòwò ará Nàìjíríà]]