Jump to content

Orin Wéré

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Orin Wéré jẹ́ orin ìtara àti ìtaníjí nínú ẹ̀sìn Mùsùlùmí ni a gbọ́ pé ìpilẹ̀ṣẹ̀ eré ajíwéré [1], nígbà tí àwọn olúfọkànsìn kan máa ń lọ káàkiri àdúgbò ní ìdájí láti jí àwọn Mùsúlùmí lati kírun àárọ̀. Èyí ni aáyan láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn sùn gbàgbera, kí wọn sì jí wéré láti ṣàdúrà òórọ̀....

Àwọn ohun èlò eré Jùjú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nígbà ti eré Jùjú bẹ̀rẹ̀, àwọn ohun èlò tí àwọn òṣèré n lò ni: báńjò, ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, samba àti ‘jùjú’ (àsìkò). Nígbà tí wọn kò lo gìtá alápòótí mọ ní wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí lo báńjò. Àwọn ohun-èlò ìbílẹ́ tí wọ́n tún mú wọ inú eré Jùjú ni gágan, sákárà tàbí orùn ìṣà, gudugudu, agogo, àgídigbo tàbí móló. Àwọn ohun-èlò ìgbàlódé tí a mú wọ́nú eré Jùjú ní gìtá, ọ̀pọ̀ ìlú alásopọ̀ tí ẹnìkanṣoṣo máa ń lù, bóńgò, kóńgà, ẹ̀rọ gbohùngbohùn, míkísà, búsítà, àkọ́díọ̀nù àti dùùrù àfẹnufọn, nígbà kan rí. ...

Igbagbo Yoruba nipa ajodun ibile

Orin ninu odun ibile

Odun ibile

Ero Yoruba nipa ajodun ibile

Orin nínú ọdún ìbílẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èrò àti ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa àjọ̀dún ìbílẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àjọ̀dún ìbílẹ̀ jẹ́ mọ́ bíbọ òrìṣà kan tí àwọn olùsìn rẹ̀ fi ń wájú mọ́ra tàbí láti fi bẹ̀bẹ̀ tàbí san ẹ̀jẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo ìwọ̀nyí wà fún ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àjọ̀dún ìbílẹ̀ tún lè wà fún ìrántí aṣááju tàbí akọni kan, bóyá tí ó tẹ ìlú kan dó, tàbí tí ó jagun kan láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tá tàbí lọ́wọ́ ibi tàbí ìjàǹbá kan, tàbí tí ó ṣe ohun mánigbàgbé kan tí wọn fi ń ránti rẹ̀ tàbí tí wọ́n fi ń ṣọpẹ́ fún un, tí wọ́n sì tí ipa bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ di òrìṣà tí wọn yóò máa bọ, tí wọn yóò sì máa ṣe ẹ̀yẹ fún lọ́dọọdún tàbí lóòrèkóòrè. ...

Agbalogbabo lori orin Yoruba

Iwulo orin Yoruba

Orin Yoruba

Àgbálọgbábọ̀ lori orin

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìwúlò orin Yorùbá

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orin jẹ ọ̀nà kan pàtàkì tí ẹní tí ó kọrín fí ń gbé èrè-ọkàn rẹ̀ jáde lórí ohun tí ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, yálà nípa ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn tàbí nípa ọ̀rọ̀ kan láwùjọ.

Ọ̀kọrin lè fi orin mú iwúrí àti ìdùnu bá ara rẹ̀ tàbí ẹlòmìíràn. Gẹ́gẹ́ bí alóre láwùjọ, ọ̀kọrin tàbí òṣèré lè fi orin gbé ẹ̀dùn ọkàn èrò àwùjọ síta, èyí tí ìba máa fún ni ni ìnira tàbí ìtẹ̀mọ́lẹ̀ tàbí ìbánujẹ́ abẹ́nu, yálà láti ọwọ́ ìjọba tàbí àwọn aláṣẹ kan. Orin lè wá fún lílò ara-ẹni tàbí tí àwùjọ lápapọ̀. Orin lè mú ní sapá ṣe ohun tí ó dàbí ẹní ṣòroó ṣe fún ní nígbà mìíràn. ...

Orin apala

Apala

Ìfáàrà

Orin àpàlà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin Yorùbá ti wọ́n jẹ́ gbájúmọ̀ ni agbègbè ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú, Ọ̀yọ̀, Ọ̀sun àti Ìgbóminà. Orin ayẹyẹ ni orin àpàlà, orin ìgbàlóde ni pẹ̀lú. Orin àpàlà kò ní nǹkan án se pẹ̀lú ẹ̀sìn, òrìsà tàbí ìbọ kan tí a mọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá. Orin ìgbàfẹ́ ni orin àpàlà....

Ìfáàrà

Orin ìgbàlódé ni orin Fújì. Orin tó gbalágboko ni pẹ̀lú. Àwọn ohun díẹ̀ péréte ni a ó ṣọ̀rọ̀ lé lorí nínú orin yìí. A ó fi ẹnu ba ohun èlò orin Fújì, àwọn ọ̀kọrin Fújì ìṣàkóso àti kókó tí Fújì ń dálé lórí. ...

Ìfáàrà

Ẹ̀dá ìtàn méjì ní a gbọ́ tí ó rọ̀ mọ́ bí eré Sákárà ṣe bẹ̀rẹ̀. Ọkan ní pé ni ìlú Ìlọrin ní Sákárà tí bẹ̀rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn Mùsúlùmí kan, kí a to mú un wá sí Ìbàdàn lásìkò Baálẹ̀ Sítú tí ó jẹ́ Olúbàdàn láàrin ọdún 1914 sí 1925. Ẹ̀dà ìtàn kejì ní pé eré kerekérè ni ó pilẹ̀ eré Sakárà láti ọwọ́ Abúdù, tí ó jẹ́ ọmọ Yorùbá kan tí ó ń ṣe àtìpó ní ìlú Bídàá ní ìpínlẹ̀ Náíjà. ...

Àwọn orin kán wà ni ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n ń kù lọ. Wọ́n ti fi ìgbà kan kári ilẹ̀ Yorùbá rí. Ní àsìkò yìí ìlú kọ̀ọ̀kan ní a ti ń rí wọn. Wọn ò tilẹ̀ kárí ẹkù kan mọ́. Irúfẹ́ àwọn orin náà fara pẹ́ òrìṣà kan pàtó. Ìlú tí ẹ̀sìn òkèrè bá ti gba ẹ̀ṣìn ìbílẹ̀ lọ́wọ́ wọn, dandan ni kí irú orin bẹ́ẹ̀ kú pẹ̀lú ẹ̀sìn tí wọ́n gbé jù sílẹ̀....


Omoniyì Ajíbóyè (2003) Ewì Alohùn Yorùbá Orin Majab Books, Ilorin. ISBN 978-32402-3-4, oju-iwe 95-124.

Omoniyi Ajiboye

link title Archived 2007-08-07 at the Wayback Machine.


  1. https://openlibrary.org/books/OL22675867M/A%CC%80sa%CC%80ya%CC%80n_orin_i%CC%80bi%CC%81le%CC%80%CC%A3_Yoru%CC%80ba%CC%81#:~:text=ISBN%2010-,9783596292,-LCCN