Jump to content

Osita Iheme

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Osita Iheme
MFR
Khawl award
Ọjọ́ìbí20 Oṣù Kejì 1982 (1982-02-20) (ọmọ ọdún 42)
Mbaitoli, Imo, Nigeria
Ọmọ orílẹ̀-èdèNaijiria
Ẹ̀kọ́ìjìnlẹ̀ kọ̀m̀pútà,Lagos State University
Iléẹ̀kọ́ gígaLagos State University
Iṣẹ́Actor

Osita Iheme, MFR tí wọ́n bí ní ogúnjọ́ oṣù kejì ọdún 1982 (February 20, 1982) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó di gbajúmọ̀ òṣèré ìlúmọ̀ọ́kà tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí "Pawpaw" látàrí ipa tó kó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn Pawpaw nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń Aki na Ukwa pẹ̀lú Chinedu Ikedieze. Òun ni olùdásílẹ̀ Inspired Movement Africa, èyí tí ó dá sílẹ̀ láti ṣe móríyá fún àwọn màjèsín àti ọ̀dọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Áfíríkà lápapọ̀.

Lọ́dún 1988, Iheme gba àmì ẹ̀yẹ Lifetime Achievement Award, èyí tí African Movie Academy Awards fún un.[1] Wọ́n kà á sí ọ̀kan nínú àwọn òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó gbajúmọ̀ jùlọ.[2]

Lọ́dún 2011, ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà ìṣèjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan fún un ní àmì ìdálọ́lá ọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́lá Order of the Federal Republic (MFR). [3]

[4][5] Ó jẹ́ ọmọ bíbí Mbaitoli ní ìpínlẹ̀ Ímò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n ìpínlẹ̀ Abia ló gbé dàgbà, ó sìn kàwé gbàwé ẹ̀rí dìgírì nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kọ̀m̀pútà ní ifáfitì Lagos State University.[6]

Àtòjọ àwọn sinimá-àgbéléwò rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Coker, Onikepo (4 May 2007). "Africa Celebrates Film Industry at AMAA 2007". Mshale Newspaper (Minneapolis, USA: Mshale Communications). Archived from the original on 3 March 2012. https://web.archive.org/web/20120303204433/http://www.mshale.com/article.cfm?articleID=1407. 
  2. Muchimba, Helen (23 September 2004). "Nigerian film lights Zambia's screens". BBC News (London, UK: BBC). http://news.bbc.co.uk/2/hi/africa/3674322.stm. 
  3. "BN Bytes: Genevieve Nnaji, Stephanie Okereke, Amaka Igwe, Aliko Dangote & Jim Ovia receive National Honours – Photos from the Ceremony". bellanaija.com. Retrieved 24 September 2014. 
  4. M'bwana, Lloyd. "Who is older between Aki and Paw Paw?? As Aki celebrates his 41st birthday". www.maravipost.com. Retrieved 11 September 2019. 
  5. Adikwu, Marris (14 August 2019). "The Nigerian Film Stars Behind Some of Twitter’s Greatest Memes". Vulture. https://www.vulture.com/2019/08/osita-iheme-chinedu-ikedieze-twitter-memes.html. Retrieved 13 September 2019. "Don’t be fooled by Iheme and Ikedieze’s size — they’re both grown men (Iheme is 37 and Ikedieze is 41)." 
  6. Cornel-Best, Onyekaba (6 May 2005). ".DYNAMITES. That's what we are". Daily Sun (Lagos, Nigeria). Archived from the original on 10 May 2005. https://web.archive.org/web/20050510225149/http://sunnewsonline.com/webpages/features/showtime/2005/may/06/showtime-06-05-2005-001.htm. Retrieved 5 September 2010.