Jump to content

Philip Begho

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Philip Begho (tí a bí ní ọjọ́ 11 Oṣù Kiní ọdún 1956) jẹ́ oǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀ èdè Naìjíríà (òṣèré, oǹkọ̀wé fún àwọn ọmọ, oǹkọ̀wé ìtàn kúkurú, àti akéwì), ó ti kọ ju ìwé ogójì lọ. A bí I ní Warri, Ipinle Delta, Itsekiri ni baba rẹ̀ ìyá a rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ẹlẹ́yàmẹyà, ó gba ẹ̀kọ́ ilé-ìwé gíga rẹ̀ ní King's College, Èkó, ó sì gba LLB. láti Yunifásitì ìlú Èkó àti LL. M. láti Yunifásitì ìlú Lọ́ńdọ̀nụ̀ ( Ile-ẹkọ Iṣowo ti Ilu Lọ́ńdọ̀nù ). [1] Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ bí oǹkọ̀wé, ó ti ṣiṣẹ́ bí oníròyìn, òṣìṣẹ́ báǹkì, oníṣòwò, amòfin àti olùkọ́ni ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Ó tún ti ṣiṣẹ́ ní fíìmù àti eré orí ìtàgé. [2] Àwọn ìwé ere oníṣe rẹ̀ fara hàn nínú fíìmù, tẹlifísìọ̀nù, rédíò àti gbàgede, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré orí-ìtàgé rẹ̀ ti gba àwọn àmì-ẹ̀rí. Ó tún máa ń kọ àwọn orin àti àwọn ìtàn nípa ìrírí, ìwé òfin rẹ̀ Company Formation: Precedents on Objects of Incorporation ti lọ sínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpín.

Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Díẹ̀ lára ètò ẹ̀kọ́ Philip Begho ni ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni ó gbà ní Grange School, IkejaÈkó, ṣùgbón nígbà tí bàbá rẹ̀, tí ó ti fìgbà kan jé olórí adájọ́ ní Ikeja, gba tiransifa lọ sí Benin City ti a sì yàn gẹ́gẹ́ bí adájọ́ ní Mid-Western Region, [3] ó tẹ̀síwájú nínu ètò-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ilé-ìwé aládàáni Emotan. Ní ọdún 1967 ó lọ sí King's College, Èkó ó sì bẹ̀rẹ̀ ìwé kíkọ ní ọmọ ọdún mọ́kànlá fún àwọn àtẹ̀jáde méjì ilé-ìwé rẹ̀ - The Searchlight àti The Mermaid.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Daily Times, Lagos, Saturday, 3 December 1994, p. 17, col. 4.
  2. Daily Sun, Lagos, Tuesday, 30 May 2006, p.21, col.1
  3. Begho, M.A. (1988), The Dog-Bite Magistrate, p. 80, The Daily Times of Nigeria Ltd, Lagos. ISBN 978-144-009-0