Pius Adesanmi
Pius Adésanmí | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Pius Adebola Adesanmi 27 February 1972 Isanlu, Kogi State, Nigeria |
Aláìsí | 10 March 2019 (aged 47) near Bishoftu, Ethiopia |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Titcombe College Egbe, University of Ilorin, University of Ibadan, University of British Columbia |
Iṣẹ́ | Professor, writer, columnist, literary critic, satirist |
Alábàálòpọ̀ | Muyiwa |
Àwọn ọmọ | Oluwatise, Oluwadamilare |
Pius Adesanmi(Ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ́n, Oṣù kejì, ọdun 1972[1] sí Ọjọ́ Kẹwàá, Oṣù kẹ̀ta, ọdun 2019) jẹ́ ọmọ Orílẹ̀èdè Nàìjíríà tí ó fi ìlú Canada ṣe ibùgbé. Ọ̀jọ̀gbọ́n, òǹkọ̀wé, Onísẹ́ lámèyítọ́ alátinúdá ni, òǹkọ̀wé afẹ̀dáṣẹ̀fẹ̀ àti òǹkọ̀wé sínú ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà. Òun ni òǹkọ̀wé ìwé Naija no dey carry last, Àkójọpọ̀ àwọn àròkọ ìfẹ̀dásẹ̀fẹ̀ ọdún 2015. Adesanmi pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní ọjọ́ kẹwàá, Oṣù Kẹta, Ọdún 2019 nínú ọkọ̀ bàlúù Ethiopian Airlines Flights tí ó jábọ̀ ní kété tí ó gbéra.
Ìtàn ìgbésí ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọmọ bíbí Ìlú Isanlu ní Ìjọba ìbílẹ̀ Apá Ìlá Oòrùn Yagba ní Ìpínlẹ̀ Kogi, Nàìjíríà ni Adesanmi[2]. Ó gba oyè àkọ́kọ́ nínú imọ̀ ìpìlẹ̀ ẹ̀dá (BA.)nínú Èdè Faransé ní Yunifásítì ti Ìlọrin ní ọdún 1992, oyè ìjìnlẹ̀ (MA)nínú Èdè Faransé ní Yunifásítì ti Ìbàdàn ní ọdún 1998, àti oyè ìjìnlẹ̀ gíga nínú Èkọ́ Faransé ní Yunifásítì ti Bìrìtìkó, Columbia, Canada ní ọdún 2002[3]
Ìṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Adesanmi di ọmọ ẹgbẹ́ Ibùdó Ìmọ̀ èdè Faransé fún ìṣèwádìí ní Áfíríkà (French Institute for Research in Africa - IFRA) ní Ọdún 1993 sí ọdún 1997, and Ibùdó Ìmọ̀ Èdè Faransé ni Ìlú Apá Gúúsù Áfíríkà (South Africa) ní ọdún 1998 sí 2000[4]. Ó jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú imọ̀ Lítíréṣọ̀ Ìfarawéra ni Yunifasiti ìjọba Ìpínlẹ̀ Pennsylvania, USA láàrin ọdún 2002 sí 2005. Ní ọdún 2006, ó darapọ̀ mọ́ Yunifásítì Carleton gẹ́gẹ́ bí i Ọ̀jọ̀gbọ́n Lítíréṣọ̀ àti Èkọ́ ajẹmọ́ Áfríkà[5]. Òun ni olùdarí ibùdó ìmọ̀ Yunifásítì ti Èkọ́ Ajẹmọ́ Áfíríkà kí ó tó di olóògbé[6].
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni Adesanmi jẹ́ òǹkọ̀wé tó ń kọ àwọn èrò rẹ̀ sínú ìwé ìròyìn premium Times àti Sahara reporters lóòrèkóòrè. Ìfẹ̀dásẹ̀fẹ̀ ló pọ̀jù nínú àwọn àròkọ rẹ̀, ó ṣe átẹnumọ́ alákiyèsí lórí àwọn ohun kòbọ́gbónmu tí ó ṣẹlẹ̀ ni agbo òṣèlú àti ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ Orílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Àwọn ẹ̀dá tó ṣàyàn láti máa kọ èrò rẹ̀ lè lórí ni àwọn olóṣèlú, àwọn pásítọ́ àti àwọn gbajúmọ̀ àwùjọ tí ó ṣe pàtàkì. Ní Oṣù Ọ̀wàrà, ọdún 2015, ó ṣọ̀rọ̀ lòdì sí ìgbésẹ̀ Emir tí Kano tẹ́lẹ̀ rí Lamido Sanusi láti gbé ọmọdé ní ìyàwó di kókó ọ̀rọ̀[7], kódà Emir fún lésì lórí ọ̀rọ̀ náà[8]. Ní ọdún 2015, ó ṣọ̀rọ̀ lórí TED Talk tí àkòrí ń jẹ́ "Ìlú Áfíríkà ní I Ìtẹ̀síwájú tí àgbáyé ni láti gbajúmọ̀[3].
Ikú ati ìyẹ́sí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Adesanmi kú ní ọjọ́ kẹwàá, Oṣù Ẹ̀rẹnà, Ọdún 2019 nígbà tí bàlúù Ethiopian Airlines Flights 302 jábọ̀ ní kété tí ó gbéra láti Addis Ababa sí Nairobi[9][10]. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn Òǹkọ̀wé káàkiri àgbáyé kọ àkójọpọ̀ ewì ọ̀tàlélúgbaléméje tí wọ́n pè ní (Wreaths for a Wayfarer) ní ìtọ́kasí sí ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó tẹ̀ jáde ní ọdún 2001. Daraja Press ló gbé jáde láti fi ṣe ìyẹ́sí rẹ̀. Nduka Otiono àti Uche Peter Umezurike ni wọ́n ṣiṣẹ́ olótùú Àkópọjọ̀ ewì náà
Àkójọpọ̀ àwọn ìwé tí ó kọ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]The Wayfarer and Other Poems (Oracle Books, Lagos; 2001)
You're Not a Country, Africa (Penguin Books; 2011)
Naija No Dey Carry Last (Parrésia Publishers; 2015)[11][12]
Who Owns the Problem? Africa and the Struggle for Agency (Michigan State University Press; 2020).
Àwọn àmì-ẹyẹ tí ó gbà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní 2001, Ìwé Adesanmi's àkọ́kọ́ The Wayfarer and Other Poems, gba àmì ẹ̀yẹ ewì Ẹgbẹ́ àwọn Òǹkọ̀wé Orílẹ̀èdè Nàìjíríà (Association of Nigerian Authors' Poetry Prize)[13].
Ní 2010, Ìwé rẹ̀ You're not a Country, Africa (Penguin Books, 2011), Àkójọpọ̀ àròkọ, gbégvá orókè níbi ìfilọ́lẹ̀ Penguin Prize fún African Writing in the nonfiction category.[14][15][16]
Ní 2017 Adesanmi ni ó gbà Canada Bureau of International Education Leadership Award.[17][18][19].
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Pius Adesanmi: Nigerian image is a burden" (interview), EverythinLiterature, 1 July 2007.
- ↑ "Professor Pius Adesanmi; Award-Winning Writer, Activist and Academician" (in en-US). Konnect Africa. 7 March 2013. http://www.konnectafrica.net/professor-pius-adesanmi-award-winning-writer-activist-and-academician/.
- ↑ 3.0 3.1 TEDx Talks (2 February 2015), Africa is the forward that the world needs to face | Pius Adesanmi | TEDxEuston, retrieved 20 February 2018
- ↑ Ibrahim, Abubakar Adam (7 October 2012). "Pius Adesanmi for ANA 2012 convention". Daily Trust. https://www.dailytrust.com.ng/news/others/pius-adesanmi-for-ana-2012-convention/94298.html.
- ↑ "Naija No Dey Carry Last by Pius Adesanmi". the Magunga Bookstore. Archived from the original on 28 July 2018. https://web.archive.org/web/20180728141724/http://books.magunga.com/store/naija-no-dey-carry-last-pius-adesanmi/.
- ↑ "Ethiopian Airlines: Who are the victims?". BBC News. 11 March 2019. https://www.bbc.com/news/world-africa-47522028. Retrieved 11 March 2019.
- ↑ Adesanmi, Pius (27 September 2015). "SLS: What Will Not Stick, What Will Stick". Sahara Reporters. http://saharareporters.com/2015/09/27/sls-what-will-not-stick-what-will-stick-pius-adesanmi.
- ↑ "At last Sanusi speaks on marriage to teenager "The lady gave her free consent" | The Light News". thelightnews.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 12 April 2018. Retrieved 19 March 2018. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "BREAKING: Pius Adesanmi, Nigerian scholar, feared dead in plane crash". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 10 March 2019. Retrieved 10 March 2019.
- ↑ "Ottawa professor dies in Ethiopian Airlines crash". CBC News. 10 March 2019. Retrieved 10 March 2019.
- ↑ ""Naija No Dey Carry Last": Nuggets from Pius Adesanmi's Satirical Masterclass, By Premium Times Books and Parrésia – Premium Times Nigeria" (in en-GB). Premium Times Nigeria. 31 August 2015. https://www.premiumtimesng.com/entertainment/artsbooks/189319-naija-no-dey-carry-last-nuggets-from-pius-adesanmis-satirical-masterclass-by-premium-times-books-and-parresia.html.
- ↑ "Book Review | Pius Adesanmi's Nigeria No Dey Carry Last | by Echezonachukwu Nduka" (in en-US). Brittle Paper. 19 October 2015. https://brittlepaper.com/2015/10/review-pius-adesanmis-nigeria-dey-carry-echezonachukwu-nduka/.
- ↑ "African Writing; Profiles of 50 African Writers". www.african-writing.com. Retrieved 26 December 2017.
- ↑ "The Winners of the Penguin Prizes for African Writing". 6 September 2010. Archived from the original on 9 May 2021. https://web.archive.org/web/20210509140714/http://penguin.bookslive.co.za/blog/2010/09/06/the-winners-of-the-penguin-prizes-for-african-writing/.
- ↑ siteadmin (5 September 2010). "Pius Adesanmi, SaharaReporters Weekly Columnist, Wins Penguin Prize for African Writing | Sahara Reporters" (in en). Sahara Reporters. http://saharareporters.com/2010/09/05/pius-adesanmi-saharareporters-weekly-columnist-wins-penguin-prize-african-writing.
- ↑ "Nigerian, Zambian win 2010 Penguin African Writing Prize" (in en-US). Africa Book Club. 5 September 2010. Archived from the original on 20 March 2018. https://web.archive.org/web/20180320173556/https://www.africabookclub.com/nigerian-zambian-take-top-2010-penguin-africa-writer-prize/.
- ↑ "Premium Times columnist Pius Adesanmi wins prestigious Canadian award – Premium Times Nigeria" (in en-GB). Premium Times Nigeria. 14 September 2017. https://www.premiumtimesng.com/news/more-news/243299-premium-times-columnist-pius-adesanmi-win-prestigious-canadian-award.html.
- ↑ "Premium Times columnist, Pius Adesanmi, honoured in Canada (PHOTOS) – Premium Times Nigeria" (in en-GB). Premium Times Nigeria. 24 November 2017. https://www.premiumtimesng.com/news/top-news/250520-premium-times-columnist-pius-adesanmi-honoured-canada-photos.html.
- ↑ siteadmin (23 November 2017). "Professor Pius Adesanmi Honored By Canadian Bureau For International Education in Halifax, Canada | Sahara Reporters". Sahara Reporters. http://saharareporters.com/2017/11/23/professor-pius-adesanmi-honored-canadian-bureau-international-education-halifax-canada.