Jump to content

Potato fufu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Potato Fufu

Potato fufu jẹ́ oúnjẹ òkèlè tí àwọn ará agbègbè àríwá Nàìjíríà máa ń jẹ. Ó gbájúmọ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí wọ́n ń gbé ní ìpínlẹ̀ Kwara. Oúnjẹ òkèlè náà rọrùn láti ṣe ní fífi wé iyán àti ìdáyàtọ̀ adùn rẹ̀ nígbà tí oúnjẹ náà bá jẹ́ ṣíṣè níbi ìgbéyàwó, ayẹyẹ àti àwọn àseyẹ mìíràn.

Oúnjẹ òkèlè náà di ṣíṣè láti ara ànàmọ́ tàbí ọ̀dùnkún ṣíṣè ní èyí tí a lè fi kún iyán, ẹ̀gẹ́ tàbí ìyẹ̀fun láti lè mú un le. Ẹ̀rọ ìlọ nǹkan tàbí ìyá odó àti ọmọ odó ni a máa ń lò láti gùn ànàmọ́ náà sí ìwọ̀n àti ìrísí tí a bá fẹ́ .[1][2]

Ànàmọ́ jẹ́ túbà tí wọ́n máa ń wà láàárín oṣù mẹ́ta sí mẹ́rin lẹ́yìn gbíngbín. Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí ó ń gbin ànàmọ́ ó sì le di ṣíṣe sí orísìírísìí ohun èlò tí ó ṣe é jẹ fún àwọn ènìyàn tí ọkàn nínú wọn jẹ́ potato fufu.[3][4]

Potato fufu máa ń di gbígbádùn ní jíjẹ jù pẹ̀lú ọbẹ̀ ilá ọbẹ̀ ilá níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ó rọrùn láti sè àti pé kò gba àkókò púpọ̀ láti sè.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Potato". ResearchGate. https://www.researchgate.net/publication/324715113. 
  2. AL, Ayo (2019-04-12). "Potato Fufu Recipe | Video Tutorial | FabWoman". FabWoman | News, Style, Living Content For The Nigerian Woman (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-01. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. "Competitiveness of sweet potato puree in bread amid food inflation". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-07-19. Retrieved 2022-07-01. 
  4. "'How Nigeria can reduce wheat importation'". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-11-02. Retrieved 2022-07-01.