Prof. Ibiyemi
Ibiyemi Olatunji-Bello | |
---|---|
9th Vice-Chancellor of Lagos State University | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 16 September 2021 | |
Appointed by | Babajide Sanwoolu |
Asíwájú | Olanrewaju Fagbohun |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 23 Oṣù Kẹrin 1964 Lagos, Nigeria |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Olatunji Bello |
Ibiyemi Olatunji-Bello (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kẹrin, ọdún 1964) ọ̀mọ́wé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni. Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa bí àwọn ẹ̀yà ara ṣe ń ṣiṣẹ́ ni.[1] òun sì ni Gíwá kẹsàn-án ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ Èkó.[2]
Ìgbésí ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Olatunji-Bello ní àdúgbò Olówógbowó ní Idumota, Erékùṣù Èkó ní òpin ìlà-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kẹrin, ọdún 1964. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Anglican Girl Grammar School ní Surulere láàárín ọdún 1970 sí ọdún 1974, ó sì ka ẹ̀kọ́ ti Girama ní Methodist Girls' High School, Yaba fún ti ìpele àkọ́kọ́ àti ẹ̀ẹ̀kejì láàárín ọdún 1974 sí 1979. Fún ti ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó lọ sí kọ́lẹ́ẹ̀jì ti Ìpínlẹ̀ Èkó fún ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀-ẹ̀rọ, ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìbàdàn, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè àkọ́kọ́ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tó ń rí sí bí ẹ̀yà ara ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ọdún 1985. Ó gba oyè ìpele kejì bẹ́ẹ̀ náà ní ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ tó ń rí sí bí ẹ̀yà ara ṣe ń ṣiṣẹ́ ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1987.[3] Ó tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti University of Texas at San Antonio, ti àlàáfíà ti Sáyẹ́ǹsì,ní San Antonio láàárín ọdún 1994 sí 1998.[4]
Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ Olùkọ́ ní College of Medicine, University of Lagos tí ó sì ti a ti ibẹ̀ gòkè, tí ó sì padà di Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè, ìyẹn ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ tó ń rí sí bí ẹ̀yà ara ṣe ń ṣiṣẹ́ ní Lagos State University College of Medicine ní ọdún 2007. Ó tún jẹ́ igbákejì fún Gíwá ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 2008.[4] Ó tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adelé Gíwá ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ Èkó tí a tún mọ̀ sí LASU kí wọ́n tó wa yan Ọ̀jọ̀gbọ́n Ìbíyẹmí Ọlátúnji-Bello gẹ́gẹ́ bi Gíwá gangan tí ó sì jẹ́ pé òun ni Gíwá kẹsàn-án nínú ọgbà ilé-ẹ̀kọ́ náà.[3] Nínú ifọ́rọ̀wáni-lẹ́nu-wò kan pẹ̀lú The Nation, Ó sọ níbẹ̀ pé, bí òun ṣe di Gíwá ilé-ẹ̀kọ́ yìí o, agbára àti àsìkò tí Ọlọ́run yan òun síbẹ̀ ni.[2]
Ìyá-Ààfin Ọlátúnjí-Bello fẹ́ Kọmíṣọ́nà, Bello Olutunji tí ó ń ṣe àkóso fún àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì agbègbè àti omi ní Ìpínlẹ̀ Èkó, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìyá-Ààfin Bello-Ọlátúnjí bí ọmọ mẹ́ta.[4][5][6]
Àmì-ẹ̀yẹ àti àwọn ìdánimọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọlátúnjí-Bello ni ó gba àmì-ẹ̀yẹ ní abala ẹni tó dá yàtọ̀ jùlọ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga níbi, The Feminine Nigerian Achievement Award.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Anyanwu, Christy (2019-12-22). "We must keep talking about social issues until govt does the needful –Prof. Ibiyemi Tunji Bello". The Sun Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-09-16.
- ↑ 2.0 2.1 "LASU VC: 'it's my appointed time'". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-10-04. Retrieved 2021-10-07.
- ↑ 3.0 3.1 Oamen, Samuel (2021-09-16). "UPDATED: Professor Olatunji-Bello is new LASU VC". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-09-16.
- ↑ 4.0 4.1 4.2 Ugbodaga, Kazeem (2021-09-16). "Tunji Bello's wife Prof. Ibiyemi named new LASU VC". PM News. Retrieved 2021-09-16.
- ↑ "Ibiyemi Bello: 16 facts to know about new LASU VC". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-09-16. Retrieved 2021-09-25.
- ↑ "I wanted to be a policewoman, became lecturer by providence –LASU VC, Prof Olatunji-Bello". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-02-19. Retrieved 2022-02-20.
- ↑ "LASU VC emerges Nigeria's most outstanding woman in tertiary education - AF24News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-02-23. Archived from the original on 2022-02-23. Retrieved 2022-03-08. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)