Rufus Giwa Polytechnic
Rufus Giwa Polytechnic jẹ́ Ile-ẹ̀kọ́ giga gbogbonìṣe tí ó wà ní ìlú Ọ̀wọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Òndó, Nàìjíríà. Ó gbàṣẹ gbòntẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń ri sí ètò ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe nílẹ̀ Naijiria láti jẹ́ kí ó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ aládàáni ti ìjọba ìpínlẹ̀. Àjọ tí ó ń ri sí ìdásílẹ̀ Ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ( National Boars of Technical Education) àti Institute of Chatered Accountant. .
Wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀ ní ọdún 1979 pẹ̀lú àṣẹ látẹnu gómìnà lásìkò ìjọba ológun Sunday Tuoyo wípé kí ó ma jẹ́ The Polytechnic Owo. Lẹ́yìn èyí ni gómìnà Adekunle Ajasin bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣagbátẹrù iké-ẹ̀kọ́ náà ní kété tí ó gorí oyè àṣẹ ní ọdún 1980. Wọ́n yí orúkọ iké-ẹ̀kọ́ yí padà Ondo State Polytechnic ní ọdún 1990. Nígbà tí yóò fi tó ọdún 2010, ilé-ẹ̀kọ́ náà ti ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000). [1]
ilé-ẹ̀kọ́ yìí ní àwọn agbọ́nrin ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ lábẹ́ ẹ̀ka Faculty ti Engeneering, Science àti Technology, LEMS, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bákan náà ni wọ́n ń sapá ní ìkẹ́kọ̀ọ̀ nípa, ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìmọ̀ ìwádí àyíká, ìmọ̀ ìṣirò, ìmọ̀ ètò ọrọ̀ ajé àti ìṣúná.
Ilé-ẹ̀kọ́ yí ti wọ́n tún ń dà pè ní Rufus Giwa Polytechnic ní àwón olùdarí wọ̀nyí ti darí: Mr Olúṣẹ́gun Aródúdú, Mr James Kọ́láwọlé, Dr Adéyẹrí, Prof Adedimila, Mr Àlàó Mr Ogundowole, Prof Peter Fapetu, prof agibefun. [1]
Ẹ tun le wo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ile-ẹkọ Achievers
- Federal Medical Center
- Atokọ awọn imọ-ẹrọ imọ-jinlẹ ni Nigeria
Gallery
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ìjásóde
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- "Welcome to Our Site" . Polytechnic Rufus Giwa. Ṣe ifipamọ lati ipilẹṣẹ ni 2012-01-28 . Fifẹyinti 2013-11-19 .