Sam Loco Efe

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Sam Loco Efe (tí a bí ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá, ọdún 1945, tó sì di olóògbé ní ọjọ́ keje oṣù keje, ọdún 2011), tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Sam Loco Efeeimwonkiyeke tí wọ́n bí ní Ìpínlẹ̀ Ẹnúgu [1] jẹ́ òṣèrékùnrin àti olùdarí eré.[2][3][4][5][6][7][8]

Sam Loco Efe
Ọjọ́ìbí25 December 1945
Enugu, Nigeria
Aláìsí7 August 2011
Amakohia
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Actor
Ìgbà iṣẹ́1977-2011

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Efe sí Ìpínlẹ̀ Ẹnúgu,[9] ó jẹ́ ọmọ Arase Efeimwonkiyeke. Bàbá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Benin, tó ń ṣiṣẹ́ ní apá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ oníṣòwò, tó ń ta àkàrà.[10] Ìlú Abakaliki ni ó ti lo ìgbà èwe rẹ̀.[11] Ó pàdánù bàbá rẹ̀ nígbà tó wà ní ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, èyí sì mú kí ó lọ ọ̀pọ̀ ọdún ju bí ó ti yẹ lọ láti kàwé rẹ̀ tán nítorí ó ní láti ran ìyá rẹ̀ lọ́wọ́ níbi òwò rẹ̀.[10] Ìrírí àkọ́kọ́ rẹ̀ sí eré orí-ìtàgé bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ onítíátà kan wá sí ilé-ìwé wọn láti wá ṣe eré orí-ìtàgé kan tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní The Doctor In Spite of Himself. Lẹ́yìn eré náà, Efe pinnu láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà. Látara èyí, ó bá wọn ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré orí-ìtàgé, ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ.[10]

Àtòjọ àwọn fíìmù àgbéléwò rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Sam Loco Efeeimwonkiyeke - 1945-2011 - Exit of an Exceptional Thespian". Leadership. 17 August 2011. http://allafrica.com/stories/201108190576.html. Retrieved 17 August 2014. 
  2. "Sam Loco Efe: How he died, his unfulfilled dream". vanguardngr.com. 8 August 2011. Retrieved 17 August 2014. 
  3. "AFTER FATHER'S BURIAL SAM LOCO'S ELDEST SON,NOW LIVES LARGE IN BENIN CITY.". modernghana.com. Retrieved 17 August 2014. 
  4. "Popular actor, Sam Loco Efe, dies at 73". arisenigeria.org. Archived from the original on 19 August 2014. Retrieved 17 August 2014. 
  5. "Swapping Sam Loco with Zebrudaya for comedy sake". punchng.com. Archived from the original on 25 April 2014. Retrieved 17 August 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "Sam Loco, Veteran Nollywood Actor And Comedian Dies". saharareporters.com. 7 August 2011. Retrieved 17 August 2014. 
  7. "Actors Guild Confirms Sam Loco's Death". saharareporters.com. 7 August 2011. Retrieved 17 August 2014. 
  8. "Remembering Nollywood legend, Sam Loco, nine years on" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-08-08. Retrieved 2020-10-05. 
  9. "Sam Loco Efe biography, net worth, age, family, contact & picture". www.manpower.com.ng. Retrieved 2022-07-23. 
  10. 10.0 10.1 10.2 Iwuagwu, Nonye (October 27, 2007). "Why I Can't Remarry". Modernghana.com. Nigeriafilms. 
  11. "Popular actor, Sam Loco Efe, dies at 73". Arisenigeria.org. The Guardian (lagos). Archived from the original on 2018-02-11.