Jump to content

Sam Oritsetimeyin Omatseye

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Sam Omatseye jẹ́ akéwì, òǹkọ̀wé ìtàn àròsọ, akọ̀tàn fún eré oeí-ìtàgé àti Akọ̀ròyìn ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria.[1][2][3] Wọ́n bí Sam ní ọjọ́ 15 oṣù June, ọdún 1961, Ipinle Delta, Nigeria ni ó sì ti wá.[4] Ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti ọdún 2019 fún National Productivity Order of Merit (NPOM).[5][6]

Sam Omatseye lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti Government College, Ughelli, (ìpínlẹ̀ Bendel tẹ́lẹ̀), ipinle Delta láti ọdún 1973 sí 1979 fún ètò ẹ̀kọ́ girama rẹ̀, ó sì gba ìwé-ẹ̀rí ilé-ìwé West African School. Ó lọ sí Federal School Of Arts And Science, Victoria Island, Lagos fún ètò ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀. Ó kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ history ní University of Ife[7] (tó ti di Obafemi Awolowo University) láti ọdún 1980 sí 1985, ó sì gba Bachelor of Arts Degree.[8]

Ó kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti lítíréṣọ̀ ní Aminu Kano Commercial College, Kano nígbà tó ń ṣe NYSC láti ọdún 1985 sí 1986. Láti ọdún 1987 sí 1988 ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ajábọ̀-olùṣèwádìí ní Newswatch Magazine,[9] ó sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ nínú ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ajèjì àti àṣà. Ní ọdún 1988, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé fún African Concord Magazine, ó sì ṣagbátẹrù oríṣiríṣi ìtàn, tó ṣe àkọsílẹ̀ ìtàn Ibrahim Babangida. Ó di igbákejì olóòtú òṣèlú ti àwọn ìwé-ìròyìn Concord ní ọdún 1989.[10]

Àwọn ìwé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìwé kehkeré

  • In Touch, Journalism as National Narrative
  • A Chronicle Foretold.[11]

Awọn aramada

Àwọn ewì

  • Mandela's Bones and Other Poems
  • Dear Baby Ramatu
  • Lion Wind And Other Poems
  • Scented Offal[14]

Àwọn eré tó kópa nínú

  • The Siege to mark Professor Wole Soyinka's 80th birthday[15]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]