Jump to content

Segun Adewale (Aeroland)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Otunba Segun Adewale
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí15 Oṣù Kàrún 1966 (1966-05-15) (ọmọ ọdún 58)
Lagos, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlúPeoples Democratic Party (PDP)
(Àwọn) olólùfẹ́Victoria Taiwo (Nee Owoeye)
Alma materUniversity of Ibadan Lagos State University
OccupationEntrepreneur, politician
WebsiteOfficial website
Nickname(s)Aeroland

Ọ̀túnba Ṣẹ́gun Adéwálé,ti gbogbo eniyan mo si Segun Aẹṛ́oland, ti a bi ni ojo keedogun sukarun odun 1966, je ogbontarigi onisowo, eleyinjuanu ati oloselu ibere pepe ni ilu Eko, o si je omo bibi EbiKlei ti nijpionleba ibile Ijero ni ipinle Ekit, i o wa ni apa Guusu Iwo-oorun Naijiria, oun si ni asoju fun ekun iwo oorun ipinle EkOoni ile asofin aga orile-ede ONijAria latA ibnu Egbe ose PDP nolonmiunira atio idiibo si ile asofin agba ni odun 2l 015.[1][2]

Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Ṣẹ́gun Adéwálé sínu ẹbí Ọ̀̀gbẹ́́ni àti Ìyáàfin Mikaeli Adéwálé tí agbo ilé Àrẹmọ àti agbo ilé Ọ̀gẹ́gẹ́nìjó ní ọjọ́ kẹ̀ẹ̀́dógún oṣu karùn ọdún 1966.[3]

Ṣégun Adéwálé lọ sí ilé-ìwé alákọ̀bẹ̀rẹ̀ ti Seventh Day Adventist, tí ó wà ní Abúlé Ọjà, ní ìlú Èkó láàrín ọdún 1972 àti 1978. Ní ọdún 1979, àwọn òbí rẹ̀ pinnu láti mú àkọ́bí ọmọ wọn padà sí ìlú Èk̀itì kí ó lè kọ́ àṣà, ìṣẹ̀dálẹ̀ àti iṣẹ́ ìlú Èkìtì dáadáa; fún ìdí èyí, ó wọ ilé ẹ̀kọ́ girama ti Ìpótì ní ọdún kan náà. Ní ilé-ìwé yìí, òun ni ó kéré jùlọ lọ́jó orí nínú àwọn tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá. Látìgbà yí ni ìwà ẹlẹ́yinjú-àánú ti bẹrẹ sí fi ara hàn nínú rẹ̀ ní àkókò tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò tíì tó ǹkan nítorí tí ó ń ran àwọn aláiní lọ́wọ́ ní ìlú Ìpoti nípa bíbá wọn ṣe iṣé ọmọ-ilé láì gba owo ọ̀yà! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní ìlú Èkìtì, síbẹ̀-síbẹ̀ ó ti ní òye tí ó pọ̀ jọjọ nínú ìwà ọmọlúwàbí àti ìṣẹ̀dálè ìlú Èkìtì, èyí t́i a mọ̀ mọ àwọn ọmọ Èkìtì. Lópin rẹ̀, ó parí ẹ̀kọ̣́ girama rẹ̀ ní ilé Ẹ̀kọ́ Girama Oríwù, ní ìlú Ìkòròdú ní ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1983, ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ ní ilé-ìwé náà.[4]

Ṣeǵun Adéwálé lọ sí ilé-ẹ̀kó àgbà Fásitì Ibadan láàrín ọdún 1986 àti ọdún 1990 ní bi tí ó ti kẹkọ̀ọ́ gboyè ìm̀ọ ìjìnlẹ̀ nípa àyíká. Ó tún kẹ́kọ̀ọ̀ si tí ó sì fi gba oyè ọ̀gá nínú ètò ìṣèjọba láti ilé-ẹ̀kọ́ àgbà Fásitì ti ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1995. Bákan náà ni ó tún gba ìwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ nípa ìṣètò ìrìnà òjú òfurufú ní ọdún 2012 tí ó sì gba ìwé ẹ̀rí pé ó mọ̀ nípa àmójútó ètò ìrìnà ojú òfururú láti ̀ilú Texas ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ní odun 2013.

  1. "Archived copy". Archived from the original on 2015-02-24. Retrieved 2015-02-24. 
  2. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2015-02-24. Retrieved 2018-04-28. 
  3. "2018: How I'll fix Ekiti state economy - Segun Adewale". Vanguard News. 2018-04-13. Retrieved 2018-05-23. 
  4. "Ekiti 2018: ADP adopts Segun Adewale as gubernatorial candidate". The Nation Nigeria. 2018-03-07. Retrieved 2018-05-23.