Jump to content

Shuga Naija

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Shuga, tí wọ́n pè ní Shuga Naija, je eré-oníṣe-ẹlẹsẹsẹ tẹlẹfísọ̀nu [1] kọ́kọ́ gba ìkéde lórí MTV Base láti oṣù Kejìlá ọdún 2013 títí di oṣù àkọ́kọ́ ọdún 2014. Sáà náà jẹ́ kíkọ láti ọwọ́ Kẹ́mi Adésoyè àti jẹ́ ìdarí láti ọwọ́ Bíyìí Bándélé. Tí àwọn olórí òṣèré jẹ́ Tíwá Savage, Chris Attoh, Maria Okanrende, Emmanuel Ikubese, Sharon Ezeamaka, Efa Iwara, Dorcas Shola Fapson, Okezie Morro, Timini Egbuson, Kachi Nnochiri, Sanni Mu'azu and Leonora Okine.[2] Shuga Naija jẹ́ iṣẹ́ takuntakun tó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan sínú tó kọ́ àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nípa àjàkálẹ̀ àrùn HIV, Ìbálòpọ̀ tí ò léwu àti lílóyún ọ̀dọ́.[3] Ó tún mẹ́nubà ẹ̀kọ́ àwọn abiamọ, ẹ̀kọ́ àlàáfíà ọmọ, ẹ̀kọ́ ìṣètò ẹbí, ìmọ̀ jẹ́ńdà tó ní ṣe láti yọ ipá àti fífún obìnrin níṣẹ́ ọwọ́ .[4][5] Eré ẹlẹ́sẹsẹ tẹlẹfísọ̀n náà ní apá mẹ́jọ,[6] tí wọ́n yà àti ṣe àgbékalè rẹ̀ ní Ìpílẹ̀ Èkó, tí atọ́kùn rẹ̀ níṣẹ́ pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú National Agency for the Control of AIDS (NACA).[7]

  1. Milah, Ojay (28 June 2013). "MTV TV Show Shifts to Nigeria from Kenya". Daily Times. Daily Times Nigeria. Retrieved 6 October 2014. 
  2. "It’s Finally Here! Watch Episode 1 of MTV Base’s Shuga Season 3 – "Home Coming"". Bella Naija. bellanaija.com. 6 December 2013. Retrieved 6 October 2014. 
  3. Ochugbua, Mary (5 July 2013). "MTV Shuga launches in Nigeria". BusinessDay. Business Day Online. Archived from the original on 11 February 2014. Retrieved 6 October 2014. 
  4. "‘SHUGA’ SEASON 3 LAUNCHED: Shifts to Nigeria, with only one Kenyan actor". Hinamundi Reviews. 5 August 2013. Archived from the original on 21 December 2014. Retrieved 6 October 2014. 
  5. "Shuga Ends With A Pow Wow! Catch Episode 8 of MTV Shuga – ‘Kasala’". Bella Naija. bellanaija.com. 20 January 2014. Retrieved 7 October 2014. 
  6. "The Thing Sweet Like Shuga! Watch All The Episodes Of The Hit Series, MTV Shuga". Jaguda.com. 20 January 2014. Archived from the original on 2 September 2014. Retrieved 7 October 2014. 
  7. "TV series & multimedia campaign to educate Nigerian youth on HIV, safe sex & teen pregnancy". MTV. MTV Base. 24 June 2013. Retrieved 6 October 2014.