Jump to content

Tiwa Savage

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Aworan Tiwa Savage ni ile isise kan

Tiwatope Savage-Balogun [1] (tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kejì ọdún 1980), tí àwọn ènìyàn mọ́ sí Tiwa Savage, jẹ́ akọrin, olùṣàkóso orin, oníṣẹ́ àti òṣèré ìlú Nàìjíríà. Ó fọwọ́ síwèé pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ òǹtẹ̀wé kan Sony/ATV Music Publishing. Savage fi ọwọ́ síwẹ̀ẹ́ iṣẹ́ pẹ̀lú Mavin Records ni ọdun 2012,[2] ó tún fi ọwọ́ síwẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Roc Nation ní oṣù kẹfà, ọdún 2016 tí ó sì jẹ́rìísi ní orí Instagram.[3] Ó pẹ̀lú àwọn mìíràn láti kọ orin Collard Greens & Cornbread láti inú album tí wọ́n yàn fún àmì ẹyẹ Grammy, Back to Me.[4] Tiwa Savage ṣe àfihàn lórí Solar Plexus, àkójọ album tí Mavin Records ṣe àfihàn rẹ̀. [5] Album àkọ́kọ́ rẹ̀, Once Upon a Time, jáde ní ọjọ́ kẹta, oṣù keje, ọdún 2013. Àwọn orin àìlẹ́gbẹ́ tí wọ́n ṣe àtìlẹ́yìn rẹ̀ ni: "Kele Kele Love", "Love Me (3×)", "Without My Heart", "Ife Wa Gbona", "Folarin", "Olorun Mi" ati "Eminado". Album kejì rẹ̀, R.E.D, jáde ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kejìlá, ọdún 2015 ó sì mú àwọn orin wọ̀nyìí jáde: "My Darling", "African Waist" àti "If I Start To Talk". Savage jẹ́ ẹni tí ó máa ń kọ orin ní èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá. [6] Gẹ́gẹ́ bíi akọrin, àwọn àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú: MTV Africa Music Award kan, àmì ẹ̀yẹ The Headies méjì, Channel O Music Video Award kan, Nigeria Music Video Award kan àti City People Entertainment Awards méjì.

Iṣẹ́ Orin[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Iṣẹ́ orin, Ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àti Orin kíkọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Savage ní ìlú Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko. Àwọn ẹbí rẹ̀ kó lọ sí ìlú Lọndọọnu nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá. Nígbà tí ó wà ní ilé-ìwé gíga, ó jẹ́ ẹni tí ó máa ń fun trombone fún orchestra band ilé-ìwé rẹ̀. Ó dàgbà sínú ètò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣà látàrí ìṣílọ rẹ̀ láti Nàìjíríà lọ sí United Kingdom àti láti United Kingdom lọ sí United States. Lẹ́yìn tí ó jáde pẹ̀lú iyì nínú Business administration láti University of Kent, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní máa ṣiṣẹ́ ní The Royal Bank of Scotland.[7] Ó ṣe elégbè fún George Michael nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún àti fún Mary J. Blige, Chaka Khan, Blu Cantrell, Emma Bunton, Kelly Clarkson, Andrea Bocelli àti Ms. Dynamite láàrin àwọn yòókù.[8][9] Ó ti ṣeré lórí ìtàgé pẹ̀lú Sting, 50 Cent, The Black Eyed Peas, Eminem, Robbie Williams àti Destiny's Child láti mẹ́nu bá díẹ̀.[10]

Savage fi orúkọ sílẹ̀ ní Berklee College of Music ó sì gboyè nínú Music. Nígbà tí ó ń ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìrírí rẹ̀, ó sọ ó di mímọ̀ pé ìwúrí òun wá látàrí ìfẹ́ tí àwọn ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ fi máa ń hàn sí ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. Savage sọ̀rọ̀ ráńpẹ́ lórí àwọn ìpèníjà tí àwọn akọrin máa ń dojú kọ tí wọ́n bá fẹ́ yí sí adarí orin láti elégbè àti wípé wọ́n máa ń dojú kọ ìyẹ̀wò nígbà tí eré wọ́n ò bá jẹ́ nǹkankan. Ó tún sọ̀rọ̀ nipa owo re ati pe ipele ọjọgbọn rẹ ko jẹ ki o ni ifarahan si ẹtan.[11]

Ni ọdun 2016, Savage kopa ninu UK edition ti The X Factor ti o si lọsiwaju lati wa lara awọn mẹrinlelogun ti o gbẹyin nigba ti o n lọ ile-iwe ti a mẹnu ba lẹẹkan.[12] Nigba ti o n kopa ninu idije na, o koju awọn iṣoro kan.[13]

Ni ọdun 2009, Sony/ATV Music Publishing buwọlu Savage fun iṣẹ orin kan ti o fun ni agbara lati kọ orin fun Babyface, Kat Deluna, Fantasia Barrino, Monica ati Mýa. O ti gba kirẹditi orin kikọ fun ilọwọsi rẹ si orin balaadi Monica: "Catch Me". Bakannaa, ibaṣepo rẹ pẹlu Fantasia lori Orin "Collard Greens & Cornbread" jẹ ki ara Amẹrika na gba yiyan fun ẹyẹ Grammy ni ọdun 2010. Savage kọ orin Jaico "Oh Yeah" ti o ṣafihan Snoop Dog pelu orin Kat Deluna "Push Push" ti o ṣafihan Akon ati David Guetta. Bi o ṣe nifẹ si ki o ma kọ orin fun awọn akọrin yoku to, o nifẹ si ki o ma kọ orin fun ara rẹ julọ. Savage ṣe elegbe lori orin Whitney Houston: I Look to You (2009).[14]

Ni oṣu kejila, ọdun 2011, o pẹlu IllRymz lati ṣeto Nigerian Idol apa keji. Bakanna, o ṣe fiimu akọkọ rẹ pẹlu Joke Silva ati Ireti Doyle ninu ere ori-itage For Coloured Girls. Savage jẹ ara-ilu Afirika akọkọ lobirin ti o niṣe pẹlu ẹya Pepsi lẹyin ti o bu ọwọ lu iwe pẹlu wọn.[15]

Ọdun 2010 titi di 2013; "Once Upon A Time", iṣowo Mavin Records, iṣẹ ọmọniyan ati ifọwọsiwe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tiwa Savage nibi ajọdun orin Mavin Industry Nite ni ọdun 2012

Savage ṣedasilẹ lebẹli rẹ, 323 Entertainment, pẹlu oluṣakoso ati ọkọ rẹ igbana Tunji "Tee Bills" Balogun ti o ṣadehun igbeyawo fun ni ọjọ karun, oṣu keji, ọdun 2013. O darapọ mọ Mavin Records ti Don Jazzy ni ọdun 2012. O wa lara awọn akọrin to dari lori Solar Plexus, alibọọmu ti labẹli naa ṣe akojọpọ re ni 2012.[16][17] Savage bẹrẹ si ni ma gba alibọọmu akọkọ rẹ silẹ ni ọdun 2010. O nẹtiwọki pẹlu awọn alumini Berklee bii Keith Harris, Derek Pate, Scott Coleman, Radar Ellis ati Darien Dorsey nigba ti o fi n lọ ile-iwe na. Nigba ti o ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Brenda Pike, o ni oun ṣiṣẹ pẹlu awọn aṣagbejade orin bii Chuck Harmony, Warren "Oak" Felder ati So Sick (Da Grin) laarin awọn yooku. Bakanna, o sọ wipe alibọọmu akọkọ rẹ yoo ni orin ni ede abinibii rẹ.[18] Savage ṣe afihan lori "Oyi Remix" ti Flavour N'abania ni ọdun 2012. Ṣiwaju ki o to ṣiṣẹ papọ pẹlu Flavour, o ṣe ẹya orin na.[19]

Lati kopa ninu ajọyọ ọdun mejilelaadọta ti Naijiria gba ominira, Savage ṣe ijabọ "Arise, O Compatriots" fun Ndani Sessions.[20] Ni oṣu kọkọnla, ọdun 2012, Savage ṣiṣẹ papọ pẹlu Waje, Praiz, Timi Dakolo ati Pamela Egoh lori akori-orin Ovation Red Carol "Higher".[21] Ni oṣu karun, ọdun 2013, Savage pe pati lori titẹti si alibọọmu ni The Wheat Baker Hotel ni Ikoyi. O ṣafihan gbogbo orin to wa lori alibọọmu na o si kede Iceberg Slim, Sarkodie ati General Pype gẹgẹbi awọn ti wọn kopa.[22] Ni ọjọ kẹta, oṣu keje, o ṣe afihan alibọọmu rẹ akọkọ, Once Upon a Time, fun gbogbo awọn ọmọ Naijiria. Alibọọmu na jade lori iTunes ni oku ọla ki o jare ni Naijiria. Savage sọ alibọọmu na ni Once Upon A Time lati ṣafihan awọn ohun rere ti o ṣẹlẹ ninu igbesi aye rẹ. O sọ wipe oun fẹ jẹ iwuri fun awọn olorin to mbọ lọna wipe, igba kan ri o, oun jẹ ọmọbirin kekere lati Isalẹ Eko ti o ni lọkan lati di irawọ. Alibọọmu na pẹlu awọn orin oṣelu bii "Middle Passage", ti o sọ nipa itiraka awọn ọmọ Afirika ni ilu ajeji.[23]

Savage ti kopa ninu ọpọlọpọ iro ọdọ lagbara ati eto ayẹwo ọmu awọn obirin fun alakán kakiri Naijiria.[24][25] Savage ti ṣe iranlọwọ lati gbe owo jade fun awọn ile-iṣẹ ti o n kọ ile-iwe ni ilu rẹ. Ni oṣu keje, ọdun 2013, o fọwọ si adehun pẹlu MTN Naijiria ti o n lọ si ọgbọn miliọnu nẹra.[26] O tun fọwọsiwe iṣẹ pẹlu Pepsi,[27] Forte Oil[28] ati Maggi.[29]

Awọn ipenija ti o dojukọ ni ile-iṣẹ orin Naijiria[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nigba ti Savage tẹ papa orin Naijiria, ko mọ o un ti oyẹ ki o reti. Bakanna, o gba ọpọlọpọ ipaya ati ikanra lọwọ awọn ti wọn lero wipe kole yege. O sọ wipe ọpọlọpọ eniyan ni o gbiyanju ati yi ọkan rẹ pada nipa titẹdo si Naijiria rẹ. Bakanna, awọn eniyan sò fun wipe wọn o le gba wọle gẹgẹbi akọrin obinrin. Ni itẹsiwaju, wọn sọ fun wipe ko le lo ori itage kanna pẹlu awọn bii Tuface ati Wizkid. Savage o jẹ ki awòn ọrọ odi na yilọkan pada nipa ṣiṣe iṣẹ orin. O ṣe agbekalẹ akọkọ orin-ẹlẹyọkan rẹ Kele Kele Love ti o roke lori ọpọlọpọ ṣaati orin Naijiria.[30]

Ọdun 2014 titi di 2016: Gbigbe orin jade, iṣẹ MTV Africa Music Awards ati iṣẹ Roc Nation[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tiwa n ṣere ni Biggest Baddest ti GTBank ni oṣu kejila, ọdun 2014

Ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kini, ọdun 2014, Savage ṣe agbejade "Love in Yellow", ti o jẹ ipolongo lati ṣajọyọ ayajọ ololufe ti ọdun 2014. Orin na, ti o ni ohun retiro R&B ati Funk jẹ agbejade lati ọwọ Spellz.[31] Savage kopa lori orin-ẹlẹyọkan ti Reekado Banks "Turn It Up" ti o jẹ agbejade lati ọwọ Don Jazzy.[32] Ni ọjọ kini, oṣu karun, ọdun 2014, Mavin ṣe agbekalẹ "Dorobucci" ti Savage, Don Jazzy, Dr SID, D'Prince, Reekado Banks, Korede Bello ati Di'Ja kopa ninuẹ. Orin yi, ti o jẹ agbekalẹ lati ọwọ Don Jazzy, jẹ akọkọ ajọṣe ti lebẹli na gbe jade lati igba ti wọn ti ṣe agbejade alibọọmu Solar Plexus ni ọdun 2012.[33][34]

Ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun, ọdun 2014, Foston Musik fi "Girlie 'O' Remix" ti Patoranking ti Savage ṣafihan lori e ṣaaju, orin na jẹ agbekale lati ọwọ WizzyPro.[35] Wọn ya fidio orin na ni Lọndọnu ti Moe Musa si ṣe itọsọna rẹ. Wọn gbe si ori Vevo akanti Patoranking ni ogunjọ, oṣu karun, ọdun 2014 ti gbogbo gigun rẹ si jẹ iṣẹju mẹrin ati aaya meje.[36] Ni ọjọ keje, oṣu kẹfa, ọdun 2014, Savage kopa ninu MTV Africa Music Awards ti ọdun 2014 pẹlu Miguel, Flavour N'abania, Davido, Mafikizolo, Uhuru, Oskido ati Professor.[37] Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu karun, ọdun 2014, 323 Entertainment ati Mavin Records ṣe agbekalẹ fidio "Wanted" ti o jẹ orin lati inu alibọọmu Once Upon a Time. Moe Musa ni o ṣe itọsọna fidio na ni Lọndọnu.

Ni oṣu kẹfa, ọdun 2014, Savage ṣiṣẹ papọ pẹlu Mi Casa, Lola Rae, Sarkodie, Diamond Platinumz ati Davido lori orin kan fun ipolongo Africa Rising ti DSTV ti wọn ṣe lati le jẹ iwuri fun awọn ọmọ Afirika lati kopa ninu awọn iṣẹ akanṣe lori idanilokowo ti o wa lawujọ. Fidio orin na, ti o jade ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ọdun 2014, jẹ didari ati gbigbekalẹ latọwọ ile-iṣe South Africa kan, Callback Dream.[38] Awọn akọrin na kọ orin na nibi ayẹyẹ ifilọlẹ Africa Rising ni Mauritius.[39] Ni oṣu kẹfa, ọdun 2016, awuyewuye wa laarin awọn to n gbe iroyin jade wipe Savage ti fi ọwọ si iwe iṣe iṣakoso pẹlu Roc Nation.[40] Ni ọjọ kọkandinlọgbon, oṣu keje, ọdun 2016, o fidi ọrọ na mulẹ nipa kikede rẹ latara akanti rẹ lori Instagram eleyi si ṣe ni ọmọ Naijiria akọkọ ti o ma wa lori lebẹli na.[41][42]

Igbesi Aye[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Savage fẹ Tunji "Tee Billz" Balogun ri. Ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2013, tọkọtaya na ṣe igbeyawo ibilẹ wọn ni the Ark ni Lekki.[43][44] Igbeyawo alaṣọ funfun na waye ni ọjọ kẹrindinlọgbon, oṣu kẹrin, ọdun 2014 ni Armani Hotels ni Dubai.[45][46] Ni ọjọ kini, oṣu kini, ọdun 2015, Savage ati ọkọ rẹ kede wipe awọn n reti akọbi won.[47] Ni ọjọ kejilelogun, oṣu keje, ọdun 2015, Savage bi ọmọkunrin ti wọn sọ ni Jamil Balogun.[48][49] Ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2016, "Tee Billz" Balogun, ninu ọpọlọpọ ifiranṣẹ lori social media, fi ẹsun agbere kan iyawo rẹ o si fi ẹsun ajẹ kan iyarẹ.[50] Ninu ifọrọwanilẹnuwo oniṣẹju marundinlaadọta ti iweroyin Thisday ati Pulse Nigeria ṣe, Tiwa Savage koju gbogbo oun ti ọkọ rẹ sọ lori social media ni kikun. O dabajẹ ẹsun agbere ti ọkọ rẹ fi kan o si fi ẹsun ina apa, inifẹsodi ogun oloro ati ipaniti.[51] Bakanna, o sọ wipe igbeyawo oun pẹlu rẹ ti dopin.[52]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "It’s Official: Tiwa Savage Now Mrs Balogun". PM NEWS Nigeria. November 23, 2013. Retrieved August 26, 2018. 
 2. "Tiwa Savage". Mavin Records. September 28, 2012. Archived from the original on September 28, 2012. Retrieved August 26, 2018. 
 3. "Tiwa Savage 'seals' management deal with Jay Z's Roc Nation". TheCable. July 28, 2016. Retrieved August 26, 2018. 
 4. "Tiwa Savage Grammy Nomination". Latest Naija Nigerian Music, Songs & Video. February 12, 2011. Archived from the original on October 26, 2018. Retrieved August 26, 2018. 
 5. "Don Jazzy forms Mavin Records, signs on Wande Coal, Tiwa Savage, D’Prince". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. October 21, 2014. Archived from the original on October 21, 2014. Retrieved August 26, 2018. 
 6. "Profile". Tiwa Savage Official Website. July 2, 2013. Archived from the original on March 4, 2016. Retrieved August 26, 2018. 
 7. "Tiwa Savage Biography, a Nigerian singer". Nigeria Music Network. September 30, 2011. Archived from the original on December 15, 2017. Retrieved August 27, 2018. 
 8. "Tiwa Savage". Mavin Records. September 28, 2012. Archived from the original on September 28, 2012. Retrieved August 27, 2018. 
 9. "Profile". Tiwa Savage Official Website. July 2, 2013. Archived from the original on March 4, 2016. Retrieved August 27, 2018. 
 10. "Tiwa Savage". Mavin Records. September 28, 2012. Archived from the original on September 28, 2012. Retrieved August 27, 2018. 
 11. "Tiwa Savage Biography, a Nigerian singer". Nigeria Music Network. September 30, 2011. Archived from the original on December 15, 2017. Retrieved August 27, 2018. 
 12. "Profile". Tiwa Savage Official Website. July 2, 2013. Archived from the original on March 4, 2016. Retrieved August 27, 2018. 
 13. "Tiwa Savage Biography, a Nigerian singer". Nigeria Music Network. September 30, 2011. Archived from the original on December 15, 2017. Retrieved August 27, 2018. 
 14. "Tiwa Savage Biography, a Nigerian singer". Nigeria Music Network. September 30, 2011. Archived from the original on December 15, 2017. Retrieved August 27, 2018. 
 15. "Tiwa Savage Biography, a Nigerian singer". Nigeria Music Network. September 30, 2011. Archived from the original on December 15, 2017. Retrieved August 27, 2018. 
 16. "Tiwa Savage". Mavin Records. September 28, 2012. Archived from the original on September 28, 2012. Retrieved August 28, 2018. 
 17. "Profile". Tiwa Savage Official Website. July 2, 2013. Archived from the original on March 4, 2016. Retrieved August 28, 2018. 
 18. "Tiwa Savage Biography, a Nigerian singer". Nigeria Music Network. September 30, 2011. Archived from the original on December 15, 2017. Retrieved August 28, 2018. 
 19. "Tiwa Savage - OYI (Tiwa Remix)". Latest Naija Nigerian Music, Songs & Video (in Lùṣẹ́mbọ́ọ̀gì). July 19, 2012. Retrieved August 28, 2018. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
 20. "Tiwa Savage Sings The National Anthem on Naija Independence Day". GhanaFilla. 1 October 2012. Archived from the original on 11 August 2014. Retrieved 28 August 2018. 
 21. Osarumwense; Osarumwense; Osarumwense; LamBA; Osarumwense (August 18, 2013). "OVATION RED CAROL". Hip Hop World Magazine. Archived from the original on August 18, 2013. Retrieved August 28, 2018. 
 22. "Tiwa Savage Holds Album Listening Party; Reveals Tracklist". HipHopWorldMagazine. 27 May 2013. Archived from the original on 29 October 2013. Retrieved 28 August 2018. 
 23. Ogunjimi, Opeoluwani (June 8, 2013). "My fiance wiped away my shame - Tiwa Savage". Vanguard News. Retrieved August 28, 2018. 
 24. "Profile". Tiwa Savage Official Website. July 2, 2013. Archived from the original on March 4, 2016. Retrieved August 28, 2018. 
 25. Ogunjimi, Opeoluwani (June 8, 2013). "My fiance wiped away my shame - Tiwa Savage". Vanguard News. Retrieved August 28, 2018. 
 26. "Nigeria's Top Website for News, Gossip, Comedy, Videos, Blogs, Events, Weddings, Nollywood, Celebs, Scoop and Games". Nigerian Entertainment Today. September 30, 2015. Retrieved August 28, 2018. 
 27. "Nigeria: Tiwa Savage and Wizkid Unveiled As Pepsi Ambassadors". AllAfrica.com. 14 July 2012. Retrieved 28 August 2018. 
 28. "Nigeria's Top Website for News, Gossip, Comedy, Videos, Blogs, Events, Weddings, Nollywood, Celebs, Scoop and Games". Nigerian Entertainment Today. September 30, 2015. Retrieved August 28, 2018. 
 29. Zandonda, Isaac (7 April 2014). "Tiwa Savage, Toke Makinwa, and Sisi Yemmie Sign Mega Endorsement Deal with Maggi". Newspoint Africa. Retrieved 28 August 2018. 
 30. Ogunjimi, Opeoluwani (June 8, 2013). "My fiance wiped away my shame - Tiwa Savage". Vanguard News. Retrieved August 29, 2018. 
 31. "NEW MUSIC: Tiwa Savage Drops Love In Yellow For Valentine". Daily Times Nigeria. November 29, 2014. Archived from the original on November 29, 2014. Retrieved August 29, 2018. 
 32. "Another Mavin Activated! Don Jazzy presents Reekardo Banks Feat. Tiwa Savage - Turn It Up". BellaNaija. February 21, 2014. Retrieved August 29, 2018. 
 33. Akan, Joey (May 12, 2014). "All Hail Don Jazzy! "Dorobucci" Makes Us Dance Our Brains Out!". Pulse.ng. Retrieved August 29, 2018. 
 34. "MUSIC REVIEW: 'Dorobucci' Could Have Been Better With D'Banj". Daily Times Nigeria. November 29, 2014. Archived from the original on November 29, 2014. Retrieved August 29, 2018. 
 35. "BN Music Premiere: Patoranking Feat. Tiwa Savage - Girlie 'O' (Remix)". BellaNaija. May 19, 2014. Retrieved August 29, 2018. 
 36. "Patoranking Features Tiwa Savage In Girlie O Remix (Video) • Channels Television". Channels Television. May 20, 2014. Retrieved August 29, 2018. 
 37. "Miguel, Tiwa Savage, Davido & Flavour to Perform at the 2014 MAMAs". BellaNaija. May 21, 2014. Retrieved August 29, 2018. 
 38. Kaggwa, Andrew (June 29, 2014). "DStv launches new campaign to inspire Africa". The Observer - Uganda. Archived from the original on June 27, 2018. Retrieved August 29, 2018. 
 39. "Lindiwe rocks Africa Rising extravaganza". archive.is. July 26, 2014. Retrieved August 29, 2018. 
 40. "TimesLIVE". TimesLIVE. June 9, 2016. Retrieved August 29, 2018. 
 41. "CONFIRMED: Tiwa Savage signs deal with Roc Nation". Channel 24 (Johannesburg). 29 July 2016. http://www.channel24.co.za/The-Juice/News/confirmed-tiwa-savage-signs-deal-with-roc-nation-20160729. Retrieved 2 August 2016. 
 42. "TimesLIVE". TimesLIVE. June 9, 2016. Retrieved August 29, 2018. 
 43. "Nigeria's Top Website for News, Gossip, Comedy, Videos, Blogs, Events, Weddings, Nollywood, Celebs, Scoop and Games". Nigerian Entertainment Today. September 30, 2015. Retrieved August 29, 2018. 
 44. "Breaking News & Latest Nigeria News Today 29.08.2018". Naija News. May 6, 2017. Retrieved August 29, 2018. 
 45. "EN: Tiwa Savage Ties Knot In Star Studded Dubai Wedding, Jeta Amata Debuts 3 Films • Channels Television". Channels Television. April 29, 2014. Retrieved August 29, 2018. 
 46. Orenuga, Adenike (April 26, 2014). "Tiwa Savage and Tee Billz tie the knots in star-studded Dubai wedding [PHOTOS]". Daily Post Nigeria. Retrieved August 29, 2018. 
 47. Nwachukwu, Emmanuel (January 3, 2015). "Tiwa Savage, Tee Billz Expecting 1st Child - Nigerian News from Leadership Newspapers". Nigerian News from Leadership Newspapers. Archived from the original on January 4, 2015. Retrieved August 29, 2018. 
 48. Egbo, Vwovwe (July 30, 2015). "Tiwa Savage: Singer shares excitement on new born son". Pulse.ng. Retrieved August 29, 2018. 
 49. Owoseje, Toyin (April 28, 2016). "Is Tiwa Savage's marriage over? Tee Billz accuses Nigerian singer's mother of witchcraft". International Business Times UK. Retrieved August 29, 2018. 
 50. "Tiwa Savage opens up: Our marriage has been over for a while". The Nation Nigeria. April 30, 2016. Retrieved August 29, 2018. 
 51. "Tiwa Savage opens up: Our marriage has been over for a while". The Nation Nigeria. April 30, 2016. Retrieved August 29, 2018. 

[Ẹ̀ka:Àwọn ọmọ Yorùbá]]