Smart Adeyemi
Smart Adéyẹmí (tí a bí ní Ọjọ́ kejìdínlógún Oṣù Kẹjọ ọdún 1960) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria láti ìpínlẹ̀ Kogí.
Ìlà kàkà rẹ̀ gẹ́gẹ́ òṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Sínétọ̀ Smart Adéyẹmí ti fìgbà kan jẹ́ ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ aṣòfin-àgbà níbi tí ó ti ṣojú ẹkùn ìwọ̀-oòrùn ìpínlẹ̀ Kogí títí di ọdún 2015 lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party. Sínétọ̀ Dino Mélayé tí ẹgbẹ́ All Progressives Congress ló borí rẹ̀ nínú ìdìbò náà. Nígbà tí ó di ọdún 2019, Smart Adéyẹmí tún díje ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, ṣùgbọ́n lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Dino Mélayé tí ó jẹ́ aṣojú ẹgbẹ́ PDP ló tún borí rẹ̀ nínú ìdìbò náà. [1] [2]
Láìpẹ́ yìí, ilé-ẹjọ́ da ìbò tó gbé Dino Mélayé wọlé nù, ó sìn pàṣẹ kí wọ́n ṣe àtúndìbò mìíràn. Ìdìbò náà ń lọ lọ́wọ́ ni ìpínlẹ̀ Kogí.[3] [4] Lẹ́yìn àtúndì ìbò náà, Smart Adéyẹmí ló wọlé gẹ́gẹ́ bí Aṣòfin-àgbà láti ṣojú apá ìwọ̀-oòrùn ìpínlẹ̀ Kogí. [5][4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Smart Adeyemi’s Decision To Challenge My Victory Is An Action Of A “Defeated And Frustrated Man” – Melaye". Information Nigeria. 2015-04-25. Retrieved 2019-11-17.
- ↑ "Dino Melaye Vs Smart Adeyemi: INEC Fixes November 16 For Rerun Of Kogi West Senatorial Election". Sahara Reporters. 2019-10-22. Retrieved 2019-11-17.
- ↑ "2019: APC adopts Smart Adeyemi for Senate". The Sun Nigeria. 2018-07-08. Retrieved 2019-11-17.
- ↑ 4.0 4.1 "Dino Melaye leads Smart Adeyemi in race for Kogi West Senate seat". Premium Times Nigeria. 2019-02-24. Retrieved 2019-11-17. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; name "Premium Times Nigeria 2019" defined multiple times with different content - ↑ Published (2015-12-15). "Congratulating Smart Adeyemi same as celebrating an armed robber —Dino Melaye". Punch Newspapers. Retrieved 2019-12-28.