Dino Mélayé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Dino Melaye
Senato ní ilé ìgbìmọ̀ Asòfin
In office
June 2015 – 11 October 2019
AsíwájúSmart Adeyemi
Arọ́pòSmart Adeyemi
ConstituencyKogi West
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Dino Daniel Melaye

1 Oṣù Kínní 1974 (1974-01-01) (ọmọ ọdún 50)
Kano, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlúPeople’s Democratic Party (PDP)
Alma materAhmadu Bello University
Websitehttp://Senatordinomelaye.com

Dino Melaye (tí a bí ní Ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún 1974) jẹ́ Sínétọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò apá ìwọ̀-oòrùn ìpínlẹ̀ Kogí lọ́wọ́́lọ́wọ́ lábẹ́ àsíyá Peoples Democratic Party kí ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn to da ìbò tí ó gbé e wọlé nù, tí ó sìn pàṣẹ kí àtúndì ìbò wáyé láàárín òun àti Sínètọ̀ Smart Adéyẹmí tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress lọ́dún 2019, ìdì ìdìbò náà ni wọ́n ṣì ń kó lọ́ wọ́lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Kogí.[1] [2]

Ẹ̀kọ́ àti Ìgbé-ayé rẹ̀ nígbà èwe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Daniel Dino Mélayé ní ìpínlẹ̀ Kánò, lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó lọ sí ilé-ìwé girama Command and Air-force Secondary School, ní ìlú Kàdúná. Ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé Ifáfitì ti Ahmadu Bello University, Zaria níbi tí ó ti kẹ̀kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ àyíká (Geography) lọ́dún 2000.[3][3] Nígbà ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Ifáfitì, ó jẹ́ olùdarí àwọn ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn èyí, wọ́n yàn án ní akọ̀wé ẹgbẹ́ African Youth Council, bákan náà, ó tú jẹ akọ̀wé ẹgbẹ́ Commonwealth Youth Council. Ààrẹ ìgbà kan, Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ yàn án sínú ìgbìmọ̀ agbani nímọ̀ràn tí Presidential Advisory Council on Youths nígbà tí ó ń ṣe ìjọba.

Ìgbé-ayé òṣèlú rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Dino Melaye tí jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ aṣojú-ṣòfin (House of Representatives), níbi tí ó ti ṣojú ẹkùn ìdìbò Kabba/Ijumu ti ìpínlẹ̀ Kogí. Lọ́dún 2015, wọ́n dibò yàn án gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ aṣòfin-àgbà (Senate) tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò ìwọ-oòrùn Kogí lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress. Dino Mélayé jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn tí wọ́n ṣe atìlẹ́yìn fún Bùkọ́là Sàràkí tí ó jẹ Ààrẹ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ wọn, All Progressives Congress kò fọwọ́ sí í. Ní ọdún 2019, Dino Mélayé àti Bùkọ́là Sàràkí pẹ̀lú àwọn sọ̀ǹgbè wọn fi ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress sílẹ̀, wọ́n sì dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party. Òun àti Sàràkí jọ díje lẹ̀gbẹ́ PDP, Sàràkí kò wọlé ṣùgbọ́n Mélayé wọlé kí ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó da ìbò rẹ̀ nù, tí ó sìn pàṣẹ kí fún àtúndì ìbò náà pẹ̀lú Smart Adeyemi tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress.[4] [5] [6] [5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Dino Melaye Biography, Career, Controversies & Net worth (2019)". Nigerian Infopedia. 2019-10-08. Archived from the original on 2019-10-16. Retrieved 2019-11-17. 
  2. Biography, Goodread (2019-03-01). "Daniel Dino Melaye Biography". Goodread Biography | The Famous People Biography Database. Archived from the original on 2019-11-17. Retrieved 2019-11-17. 
  3. 3.0 3.1 "Sen. Melaye graduated from ABU Zaria - VC confirms". News Agency of Nigeria (NAN). 2017-03-27. Archived from the original on 2019-11-17. Retrieved 2019-11-17. 
  4. "Dino Melaye Archives". Information Nigeria. Retrieved 2019-11-17. 
  5. 5.0 5.1 Toromade, Samson (2019-02-25). "PDP's Dino Melaye wins re-election to represent Kogi West Senatorial district". Pulse Nigeria. Retrieved 2019-11-17. 
  6. "N'Assembly: Saraki is Senate President, Dogara Speaker, Articles - THISDAY LIVE". thisdaylive.com. 2015-06-11. Archived from the original on 2015-06-11. Retrieved 2019-11-17.