Jump to content

Tim Robbins

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Tim Robbins
Robbins at the Berlin Film Festival 2013
Ọjọ́ìbíTimothy Francis Robbins
16 Oṣù Kẹ̀wá 1958 (1958-10-16) (ọmọ ọdún 66)
West Covina, California, U.S.
Ẹ̀kọ́University of California, Los Angeles (BA)
Iṣẹ́
  • Actor
  • director
  • producer
  • screenwriter
Ìgbà iṣẹ́1982–present
Olólùfẹ́
Gratiela Brancusi
(m. 2017; div. 2022)
Alábàálòpọ̀Susan Sarandon (1988–2009)
Àwọn ọmọ2, including Miles Robbins
AwardsFull list
Websitetimrobbins.net
Tim Robbins

Tim Robbins tí orúkọ rẹ̀ kíkún ń jẹ́ Timothy Francis Robbins (ọjọ́-ìbí Oṣù Kẹwàá Ọjọ́ Kẹ́rindínlógún, ọdún 1958)[2] jẹ́ òṣèré ará Améríkà. Ó gbajúmọ̀ jùlọ fún bí ó ṣe ṣe Andy Dufresne nínú fíìmù The Shawshank Redemption (1994), àti Jacob Singer nínú Jacob's Ladder (1990), àti bí ó ṣe gba àmì ẹ̀yẹ Academy àti àmì ẹ̀yẹ Golden Globe fún ipa rẹ̀ nínú Mystic River (2003) àti Golden Globe mìíràn fún The Player (1992). Àwọn ipa míìràn ti Robbins pẹ̀lú ìṣèré bí Lt. Samuel "Merlin" Wells nínú Top Gun (1986), Nuke LaLoosh nínú Bull Durham (1988), Erik nínú Erik the Viking (1989), Ed Walters nínú I.Q. (1994), Nick Beam nínú Nothing to Lose (1997) àti Senator Robert Hammond nínú Green Lantern (2011). Ó tún darí àwọn fíìmù Bob Roberts (1992) àti Dead Man Walking (1995), àwọn méjèèjì ni wọ́n gbà dáadáa. Wọ́n fi orúkọ rẹ̀ sára àwọn tí wọ́n yàn láti gba àmì ẹ̀yẹ Academy fún Olùdarí tó dára jùlọ fún n Dead Man Walking.

Ní orí tẹlifíṣàn, Robbins ṣe bí Akọ̀wé Ìjọba Àpapọ̀ Walter Larson nínú eré àwàdà HBO The Brink (2015), àti nínú Here and Now (2018) ó ṣe bí Greg Boatwright. Ní ọdún 2023, ó ṣe bí Bernard Holland nínú Apple TV+ jara Silo.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Robbins ní West Covina, California, ó sì dàgbà ní New York City. Àwọn òbí rẹ̀ ni Mary Cecelia (née Bledsoe), akọrin, àti Gilbert Lee Robbins, akọrin, òṣèré, àti olùṣàkóso ti The Gaslight Cafe. Robbins ní àwọn arábìnrin méjì, Adele àti Gabrielle, àti arákùnrin kan, akọrin David Robbins. Ìsìn Kátólíìkì ni wọ́n fi tọ́ ọ dàgbà.