Jump to content

Ugali ní Nàìjíríà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ugali ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àkàmù, ògì tàbí Kókó fi ara jọ́ ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.[1] Ògì/Àkàmù ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń jẹ pẹ̀lú "moin moin", ohun tí a ṣe láti ara ẹ̀wà, tàbí "akara", èyí tí à ṣe láti ara ẹ̀wà pẹ̀lú. Ẹ̀yà kan náà wà tí ó máa ń le, wọn a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ẹ̀kọ láàrin àwọn Yoruba, Agidi ní àárín àwọn Igbo. Oúnjẹ yìí jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń sè ní orí iná títí tí á fi jinnà. Wọ́n sáábà máa ń pọ́n ọn sínú ewé tí a mọ̀ sí Thaumatococcus daniellii.[2] Àwọn ẹ̀yà Yorùbá a máa pè é ní Ewé ééran nígbà tí àwọn ẹ̀yà Igbo máa ń pè é ní Akwukwo Elele.[3] Kò fẹ́ ẹ̀ sí ọbẹ̀ tàbí ẹ̀fọ́ tí a kò le fi jẹ oúnjẹ yìí, bẹ́ẹ̀ ni a máa ń lo ẹwà tàbí àwọn oúnjẹ tí le fi ẹ̀wà se láti jẹ ẹ́ pẹ̀lú.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Kulp, Karel (2000-03-28) (in en). Handbook of Cereal Science and Technology, Second Edition, Revised and Expanded. CRC Press. ISBN 978-0-8247-8294-8. https://books.google.com/books?id=gtqEWcA73BEC&pg=PA166. 
  2. "Moi-moi leaf plant prevents kidney, liver damage". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 8 November 2018. 
  3. "Moi-moi leaf plant prevents kidney, liver damage". 8 November 2018.