Jump to content

Moin moin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Moin-Moin or Moi-Moi
Alternative namesMoyi-Moyi, Mai-Mai, Olele
TypePudding
Place of origin(Nigeria, Benin and Togo)
Region or stateWestern Africa
Created byYorùbá
Main ingredientsBlack-eyed beans or honey beans, onions, fresh ground peppers,oil
Àdàkọ:Wikibooks-inline 
Nigerian fried rice served with grilled fish, mixed salad and moi moi

Mọ́ín-mọ́ín, ọ̀lẹ̀lẹ̀ tàbí ọ̀ọ̀lẹ̀ jẹ́ ẹ̀wà tí a bo èpo rẹ̀, tí a lọ̀, tí a sì fi àwọn èròjà bíi ata, epo, iyọ̀ edé, iyọ̀ àti àwọn èròjà míràn sí ṣáájú kí wọ́n tó sè é lórí iná. Lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n ma ń fi àlùbọ́sà, atalẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kun kí ó lè dùn un jẹ. [1]Móí-mọ́í jẹ́ óunjẹ ìbílẹ̀ Yorùbá tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Òúnjẹ yí jẹ́ ìkan pàtàkì lára àwọn óúnjẹ aṣaralóore .[2][3]

Yàtọ̀ sí mọ́í-mọ́í tí wọ́n ń pèé ní ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n tún ń pèé ní alele, tàbí ọ̀lẹ̀lẹ̀ ní apá orílẹ̀-èdè Sierra Leone ati Ghana . Wọ́n tún ma ń jẹ mọ́ímọ́í pẹ̀lú ẹ̀kọ, kòkó lọ́dọ̀ àwọn Hausa tàbí ògì. [4] Tubaani (also spelled tubani) is a similar dish found in Northern Ghana.[5] Wọ́n lè fi mọ́ímọ́í mu gàrí pẹ̀lú, wọ́n sì tún ma ń fi gbádùn ounje bíi ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù, ìrẹsì ọ̀fadà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn èròjà mọ́ímọ́í

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n lè lo ẹ̀wà pupa, ẹ̀wà sèsé, tàbí ẹ̀wà funfun tí wọ́n ń pe ní erèé, wọ́n ma ń fi ata, epo, òróró, edé, àlùbọ́sà, ẹyin, ẹja yíyan, iyọ̀, magí tàbí ẹran tí wọ́n ti bọ̀ si kí ó lè ládùn tó dára.

Bí a ṣe ń pèsè mọ́ímọ́í

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ma ń pèsè mọ́ímọ́í pẹ̀lú kí wọ́n kọ́kọ́ rẹ ẹ̀wà èyíkéyí tí wọ́n fẹ́ lò sínú omi tútù títí yóò fi rọ̀, lẹ́yìn náà wọn yóò bo èpo ara ẹ̀wà náà kúrò.[6]Lẹ́yìn èyí ni wọn yóò lọ̀ọ́ kúná, wọn yóò wá fi àwọn èròjà tí a ti mẹ́nu bá ṣáájú. Àwọn míràn ma ń fi ẹyin, ẹran bíbọ, edé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kun kí ó lè dùn yùngbà yùngbà. [7] Irúfẹ́ mọ́ímọ́í tí wọ́n bá pèsè pẹ̀lú àwọn èròjà tí a ti ka sílẹ̀ yí ni a lè pe ní mọ́ímọ́í ẹlẹ́mí méje. [8]

Wọ́n ma ń ṣu mọ́ímọ́í rogodo, tàbí kí wọ́n ṣù ú pẹrẹsẹ, ó da lórí ohun tí wọ́n bá fi ṣù ú. [9] Bí wọ́n bá ti fi sínú ohun tí wọ́n fẹ́ fi ṣù ú tán, wọn yóò sì gbe sí orí iná. Tí wọ́n bá fi ewé éran tàbí ewé ẹ̀bà [10] tàbí ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣu mọ́ímọ́í ni yóò jẹ́ kí ó rí rogodo. [11] omi tó pọ̀ ni wọ́n fi ma ń se mọ́ímọ́í.


Àwọn itọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "The thriving 'Moi-moi' business in Nigeria". 22 March 2022. 
  2. "Nigerian Moi Moi". All Nigerian Recipes (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-23. 
  3. "Nigeria", The World Factbook (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), Central Intelligence Agency, 2022-08-23, retrieved 2022-08-28 
  4. "NEWS". miczd.gov.gh. Archived from the original on 2020-06-06. Retrieved 2020-06-07. 
  5. Osseo-Asare, Fran; Baeta, Barbara (2015). The Ghana Cookbook. New York: Hippocrene Books. ISBN 978-0-7818-1343-3. OCLC 896840053. 
  6. "Best Moi-moi recipe". 11 November 2020. Archived from the original on 18 October 2022. Retrieved 26 January 2023. 
  7. "Moin-Moin". 13 April 2010. 
  8. "Moin-Moin". 13 April 2010. 
  9. "The Nigerian Moi-Moi". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-07-21. Archived from the original on 2022-07-23. Retrieved 2022-07-23. 
  10. Iwalaiye, Temi (2021-12-17). "What should you use to wrap moi-moi?". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-23. 
  11. "Moi Moi Wrapped In Banana leaves Recipe by UmmiAbdull". Cookpad (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-23. 

Àdàkọ:Puddings Àdàkọ:African cuisine