Uyaiedu Ikpe-Etim

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Uyaiedu Ikpe-Etim tí wọ́n bí ní ọdún 1989 jẹ́ olùgbéré-jáde àti ònkọtàn ọmọ orílẹ̀-èdè *Nàìjíríà tí ó kéde fún ẹ̀tọ́ àwọn LGBT gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń fi ẹ̀tọ́ wọ jẹ wọ́n níyà. Ní inú ọdún 2020, ilé-iṣẹ́ BBC fi orúkọ rẹ̀ sí ara àwọn ènìyàn ọgbàọ́rùn un obìnrin fún ọdún 2020 (100 Women of the Year).

Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Etim ní wọ́n bí ní ọdún 1989. [1] Òun àti ẹnìkan ni wọ́n jọ dá ilé-iṣẹ́ Hashtag Media House, ó sì ti ń ṣe àtìlẹyìn fún àwọn àwùjọ kéréje-kéréje pàá pàá jùlọ àwùjọ LGBTQ láti ọdún 2011.[2] Ó ri wípé àwọn ènìyàn ń fojú pa làbà ẹ̀tọ́ àwọn LGBT ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, pàá pàá jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó fi mọ́ àwọn ilé iṣẹ́ agbéré-jáde gbogbo ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ilé-iṣẹ́ Nollywood, Gbogbo eré tí ó bá ti jẹ mọ́ ti LGBT ni wọ́n ma m fi ṣe yẹ̀yẹ́, tabí kí wọ́n sọ pe ẹ̀dá ìtàn náà wà ní inú ẹgbẹ́ òkùnkùn tàbí kí wọ́n sọ wípé onítọ̀hún wà nínú ìgbèkùn tí wọn yóò sọ wípé àfi kí wọ́n gbé wọn lọ sí ilé ìjọsìn fún ìtúsílẹ̀.[3][4][5] Eré èyí tí wọ́n bá gbé jáde tí ó jẹ́ ti LGBT ni ó sábà ma ń jẹ́ ti Àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ homosexual.[6] Ní ọdún 2020, Etim ati akẹgbẹ́ rẹ̀ kan Pamela Adie di lààmì-laaka ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú bí eọ́n ṣe gbé eré kan tí ó ni ṣe pẹ̀lú LGBT jáde tí wọ́n pe ní Ìfé.[7] Eré yí ni ó gbé Etim jáde gẹ́gẹ́ bí adarí eré, tí wọ́n sì fi eré náà sọ nípa ọrọ̀ ìfẹ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrí àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ olólùfẹ́.[1] Eré onítan Ìfé kìí ṣe eré tí yóò ma sọ nípa LGBT ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àmọ́ oun ni ónṣe àfihàn Ìbáṣepọ̀ abo méjì tí kò sì mú gbọ́nmi si omi ò to láti ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú.[4][7] Lóòtọ́ ni wípé gbogbo àwọn tí Won kópa nínú eré náà láti olùdarí eré, olùgbéré-jáde ati àwọn olú ẹ̀dá ìtàn ni wọ́n jọ jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ LGBT.[4] Ikpe-Etim ni wọ́n ṣàfihàn bíi queer.[2] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé, àjọ tí wọ́n ṣe ìgbéléwọn àwọn eré sinimá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kọ̀ jálẹ̀ wípé wọn kò gbọdọ̀ gbé eré náà jáde tí wọ́n sì tún dún kokò mọ́ àwọn òṣèré náà wípé wọn yóò lọ sẹ́wọ̀n bí eré náà bá fi jáde, látàrí wípé wọ́n ní wọ́n gbé kí ọkùnrin ati ọkùnrin ó ma fẹ́ra wọn ní ohun tí òfin orílẹ̀-èdè wọn kò sì fàyè gba irúfẹ́ nkan bẹ́ẹ̀ láti ọdún 2014.[7] Láti yagò fún ìjìyà ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, wọ́n lọ gbé eré náà jáde ní ìlú London ní inú oṣù Kẹwàá ọdún 2020 ní Toronto LGBT Film Festival.[5][8][9] Wọ́n sì ń ṣàfihàn rẹ̀ ní orí Ìtàkùn ehtvnetwork.com.[10] Wọ́n tún ṣe àfihàn rẹ̀ ní Leeds International Film Festival in November 2020.[11]

Àwọn ìtoọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-iṣẹ́ BBC yan Ikpe-Etim mọ́ àwọn ọgọ́rún obìrin tí wọ́n fẹ́ fún ní amì-ẹ̀yẹ 100 Women fún ti ọdún 2020 láti fi gbóríyìn fún lórí bí ó ṣe ń ṣe àtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ àwọn LGBT ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[12][13]

Àwọn Itọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 "ÌFÉ, UNA CINTA LGTBQ DE 'NOLLYWOOD'". Cinemelodic (in Èdè Sípáníìṣì). 2020-08-22. Retrieved 2021-01-05. 
  2. 2.0 2.1 "Ìfé Writer and Director Uyaiedu Ikpe-Etim on Decolonizing Nigerian Storytelling and Queer Love Stories". Autostraddle (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-09-09. Retrieved 2021-01-07. 
  3. "Here is all you need about 'Ìfé', a lesbian love story directed by Uyai Ikpe-Etim". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-07-04. Retrieved 2021-01-07. 
  4. 4.0 4.1 4.2 Aisha Salaudeen. "A Nollywood film about two women in love faces an uphill battle in a country where homophobia is rampant". CNN (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-07. 
  5. 5.0 5.1 "A rare cinematic portrait of queer women’s intimacy in Nigeria". africasacountry.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-07. 
  6. "Producer of Nigeria’s new history-making lesbian film has a cunning plan to beat homophobic censors". PinkNews - Gay news, reviews and comment from the world's most read lesbian, gay, bisexual, and trans news service (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-08-05. Retrieved 2021-01-07. 
  7. 7.0 7.1 7.2 "The Nigerian filmmakers risking jail with lesbian movie Ife" (in en-GB). BBC News. 2020-09-14. https://www.bbc.com/news/world-africa-54070446. 
  8. Akwagyiram, Angela Ukomadu, Alexis (2020-08-22). "Película de amor lésbico de Nigeria se lanzará online para evitar la censura" (in es). Reuters. https://es.reuters.com/article/nigeria-lgbt-pelicula-idESKBN25H25C. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]Àdàkọ:Cbignore
  9. Desmond, Vincent (2020-08-06). "Nigerian's First Lesbian Love Story Goes Online to Beat Film Censors". allAfrica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-07. 
  10. Lebret, Melusine (2020-12-13). ""Ife" Set To Become A Turning Point In Nollywood’s History". The Organization for World Peace (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-07. 
  11. "These Are The Best Nigerian Films of 2020". OkayAfrica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-12-18. Retrieved 2021-01-07. 
  12. "BBC 100 Women 2020: Who is on the list this year?" (in en-GB). BBC News. 2020-11-23. https://www.bbc.com/news/world-55042935. 
  13. "Aisha Yesufu, Uyaiedu Ikpe-Etim and others make 2020 BBC's 100 women list". Pride Magazine Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-11-24. Retrieved 2021-01-07. 

External links[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Authority control