Vaal Dam

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Vaal Dam ni orílẹ̀-èdè South Africa ni a ṣe ní ọdún 1938 ó sì wà ní ìwọ̀n 77km gúúsù ti OR Tambo International Airport, Johannesburg . Adágún tí ó wà lẹ́hìn odi-ìdídò náa ní àgbègbè ojú tí ó fẹ̀ tó bíi 320 square kilometres (120 sq mi) [1] ó sì jìn ní ìwọ̀n mítà 47. Ìdídò Vaal wà lórí Odò Vaal, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òdò tí ńṣàn tí ó lágbára jùlọ ní orílẹ̀-èdè South Africa. Àwọn òdò mìíràn tí ńṣàn sínu ìdídò náà ni Odò Wilge,Odò Klip Molspruit ati Grootspruit.[2] Ó ní ju 800 kilometres (500 mi) ti etí òkun àti pé ó jẹ́ ìdídò ńlá kejì ti orílẹ̀-èdè South Africa nípasẹ̀ àgbègbè àti ẹ̀kẹrin tí ó tóbi jùlọ nípasẹ̀ ìwọ̀n.

Dámù Vaal nígbà ìkún omi ọdún 2010

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìkọ́lé Vaal Dam bẹ̀rẹ̀ lákòkóò ibànújẹ́ ti ibẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọdun 30s àti pé iṣẹ́ ìkọ́lé ìdídò náà parí ní ọdún 1938 pẹ̀lú gíga odi ti 54.2 metres (178 ft) lékè ìpìlẹ̀ tí ó súnmọ́ ilẹ̀ jùlọ àti agbára ìpèsè kíkún ti 994,000,000 cubic metres (3.51×1010 cu ft). Ìdídò náà jẹ́ èyí tó dábu lé etí odò ti a fi erùpẹ̀ ilẹ kún-un ní apá ọ̀tún. Àpapọ̀ Rand Water ati Ẹka ti Awọn ọ̀rọ̀ Omi) ni wọń kọ́ ọ.

Ìdídò náà tún di gbígbé sókè ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọdún 50s sí gíga ìwọ̀n 60.3 metres (198 ft) èyí tí o fi kún agbara rẹ̀ láti di 2,188,000,000 cubic metres (7.73×1010 cu ft). Ìgbéga kejì wáyé ní ọdún 1985 nígbà tí odi di gbígbé sókè nípasẹ̀ 3.05 metres (10.0 ft) sí 63.4 metres (208 ft) lékè ìpìlẹ̀ tí ó súnmọ́ ilẹ̀ jùlọ. Agbára ìdídò lọ́wọ́lọ́wọ́ jẹ́ 2,609,799,000 cubic metres (9.21642×1010 cu ft) àti síwájú síi 663,000,000 cubic metres (2.34×1010 cu ft) tàbí ìdá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26%) le wà ní ìpamọ́ fún ìgbà díẹ̀ fún ìdínkù iṣàn omi.

Àwọn ohun-ìní ìdínkù iṣàn omi ti ìdídò náà ní oríṣi ìdánwò ní Oṣù-kejì ọdún 1996 nígbà tí iṣàn omi tí ó tóbi jùlọ ṣẹlẹ̀ ní Ìdídò Vaal. Ṣíṣànwọlé tí ó ju 4,700 cubic metres per second (170,000 cu ft/s) ní ìwọ̀n ló ṣàn sínu Ìdídò Vaal tí ó tilẹ̀ wà ní agbára kíkún nítorí òjò ń ṣe déédé àti pé nípasẹ̀ ìṣàkóso amòye ti òṣìṣẹ́ Hydrology ni DWAF nìkan ni ìkún omi tí ó pọ̀jù tí ó jáde láti inú ìdídò náà mọ níwọ̀n si 2,300 cubic metres per second (81,000 cu ft/s) . Àwọn ìṣàn tí ó ju 2,300 cubic metres per second (81,000 cu ft/s) yóò ti fa ìbàjẹ́ ńlá ní ìsàlẹ̀ ti ìdídò Vaal àti pé ipò lákòókò ìṣàn omi 1996 di wàhálà púpọ̀ bí ibi ìpamọ́ tí ó wa nínu ìfiomipamọ́ fò sí 118.5% ti Agbára Ìpèsè ní kíkún ní ọjọ́ 19 oṣù kejì 1996, èyí já sí pé 194,000,000 cubic metres (6.9×109 cu ft) ti agbára gbígba ìṣàn omi wà ṣáájú kí ṣíṣàn kíkún yóò ti tú sílẹ̀ tí ńfa ìbàjẹ́ ńlá.

Lesotho Highland Water Project ń pèsè omi sínú ẹ̀rọ̀ nípasẹ̀ gíráfítì tí ó ṣe ìdásí sí ìpèsè omi tó fọkànbalẹ̀ sí àwọn ènìyàn àti ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ti Gauteng . Omi yìí jẹ́ fífà láti Lesotho sí inú Liebenbergsvlei àti Wilge Rivers. .

Dam Sterkfontein jẹ́ apákan ti ètò gbígbé omi Tugela V aal fún gbígbé omi intabésìn láti òdò Thukela ní KwaZulu-Natal láti ṣe àlékún àwọn ìpele ní Ètò Odò Vaal . Omi láti Sterkfontein Dam ti wà ní ìdásílẹ̀ ní kété tí omi inú Vaal Dam lọlẹ̀ sí 16%.

Ìdídò náà ní erékùsù tirẹ̀ tí ó gùn tó 5 kilometres (3 mi). A lo erékùsù náà gẹ́gẹ́ bí ibi ìpàdé ìkọ̀kọ̀ ìjọba ẹlẹ́yàmẹyà ṣùgbọ́n nísìn yìí ó gbàlejò eré-ìje Round the Island Yacht lọ́dọọdún, àkọlé Guinness Book of World Records ti eré-ìje ọkọ̀ ojú omi inú-ìlú tí oọ tóbi jùlọ. [3]

Ní ọjọ́ 4 Oṣù Karùn-ún ọdún 1948 BOAC ṣàfihàn àwọn ọkọ̀ ojú-omi Short Solent lori òpópónà orí omi UK (Southampton) sí South Africa (Vaaldam).[4].Abúlé kékeré ti Deneysville ni a lò bí aàyè ìdúró-lórí nípasẹ̀ àwọn ọkọ̀ ojú omi BOAC àtijọ́ tí ń fò.

Àwọn eré ìdárayá orí-omi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìdídò Fáàlì jẹ́ ibi ìpẹja olókìkí àgbáyé fún oríṣi ẹja káàbù àti ẹja àrọ̀. Àwọn etí òkun rẹ̀ kún fún àwọn apẹja ní gbogbo ọdún.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ eré ìdárayá omi tó wuyì káàkiri àgbáyé ni ó wáyé níbí pẹ̀lú eré-ìje ọkọ̀ ojú omi “Round The Island” lọ́dọọdún tí a ṣètò nípasẹ̀ Lake Denis Yacht Club—[5] eré-ìje kan tí ó wà nínú Guinness Book of Records fún jíjẹ́ “Àwọn ọkọ̀ ojú omi Púpọ̀ jùlọ tó kópa nínú eré-ìje kan ṣoṣo ti Ọkọ̀ ojú omi ní Àgbáyé”, nínú èyítí ọkọ̀ 389 kọjá ìlà ìparí. Eré-ìje yìí ti wọ inú Ìwé Ìgbàsílẹ̀ Guinness fún àwọn ọkọ̀ ojú-omi púpọ̀ jùlọ nínú eré-ìje ọkọ̀ ojú-omi àárín ìlú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá wáyé níbí pẹ̀lú Ọsẹ̀ Kílíboòtì àti eré-ìje Bayshore 200 km, àti báyìí Bayshore Marina Vaal Dam Treasure Hunt. Lake Deneys Yacht Club àti Pennant Nine Yacht Club ṣe alábàpín-ín sí ìṣètò ti àkójọpọ̀ ọkọ̀ ojú-omi èyítí ó kópa nínú ti àkọ́kọ́ 2014 àti èkejì 2015 ti káríayé “Bart's Bash”.

Àwọn ìgbèríko mẹ́ta ni ó wà ní etí ìdídò Vaal - Free State ní ó gùn jùlọ, Mpumalanga ní etí òkun tí ó lẹ́wà àti èyí tó dára, èyí tí ó ti bàjẹ́ púpọ̀ jùlọ ni ti Gauteng. Ìdídò náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1939, ó ní agbára ti 2.536 cubic kilometres (2,056,000 acre⋅ft) , [6] àti agbègbè ojú ti 320 square kilometres (120 sq mi), [7] odi ìdídò náà ga ní ìwọ̀n 63 metres (207 ft). Nítorí bí ìdídò náà ṣe tóbi tó ìsòro wà pẹ̀lú ìgbàsókè omi, wo Sterkfontein Dam fún àlàyé síwájú si.

Deneysville jẹ́ ìlú tí ó tóbi jùlọ lórí ìdídò Vaal ó sì pèsè ilé-ìtajà fún-un. Ó ní ẹgbẹ́ ọkọ̀ ojú-omi mẹ́ta àti àwọn màrínà méjì.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "VAAL DAM". Department of Water Affairs. Retrieved 19 December 2009. 
  2. Vaal (reservoir) Archived 22 June 2004 at the Wayback Machine.
  3. Empty citation (help) 
  4. "Museum History 1940–1950". British Airways Museum. Archived from the original on 2008-12-27. Retrieved 2009-07-10. 
  5. "There's much more to LDYC than Sailing". Lake Deneys Yacht Club. Retrieved 2009-07-10. 
  6. "VAAL DAM". Department of Water Affairs. Retrieved 19 December 2009. 
  7. Empty citation (help)