Jump to content

Wálé Adébáyọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Wálé Adébáyọ̀ jẹ́ òṣèrékùrin, adarí eré àti olùgbéré-jáde tí wọ́n bí ní ìlú Abẹ́òkútaÌpínlẹ̀ Ògùn, àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ qá láti Ìpínlẹ̀ Òndó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1]

Ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wálé lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé-ẹ̀kọ́ girama ti "Satellite Town" ní Ìpínlẹ̀ Èkó níbi tí ó dàgba sí. Ó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ .

Wálé di ìlú-mòọ́ká látàrí ipa rẹ̀ tí ó kó nínú eré Ṣàngó gẹ́gẹ́ bí olú ẹ̀dá-ìtàn. Ó ti gbé awọn eré ọlọ́kan-ò-jòkan eré bíi Makabba ati Double Game, The Legendary African King àti Figuring . Ó sì tún ti darí eré onípele àtìgbà-dégbà bí Binta and Friends ati Papa Ajasco and Company lábẹ́ ilé-iṣẹ́ Walé Adénúgà.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "PROFESSIONAL ACTORS DON'T REJECT ROLES-----WALE ADEBAYO". Modern Ghana. 2009-02-25. Retrieved 2020-11-25. 
  2. "- Actor Director profile on Nollywood Boulevard.". Nollywood Boulevard. Retrieved 2020-11-25. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]