Wikipedia:Àyọkà ọṣẹ̀ 29 ọdún 2020
Nelson Rolihlahla Mandela (ọjọ́ 18 oṣù keje ọdún 1918 – ọjọ́ 5 oṣù kejìlá ọdún 2013) jẹ́ alákitiyan ìgbógun ti ápátáìdì, olórí olóṣèlú àti ọlọ́rẹ ará Gúúsù Áfríkà tó ṣiṣẹ́ bí Ààrẹ ilẹ̀ Gúúsù Áfríkà láti ọdún 1994 di ọdún 1999. Ò hun ni ẹni aláwọ̀dúdú tó jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè níbẹ̀ àti ẹni àkọ́kọ́ tó jẹ́ dídìbòyàn pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ìbò gbogbo ènìyàn. Ìjọba Mandela dojú kọ títúká ètò ápátáìdì nípá gbígbógun tí ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà. Gẹ́gẹ́ bí ìrò-ọ̀ṣèlú, Mandela jẹ́ aṣèlú ọmọorílẹ̀-èdè ilẹ̀ Áfríkà àti sósíálístì, ó jẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú African National Congress (ANC) láti ọdún 1991 dé ọdún 1997.
Mandela tó jẹ́ ará ẹ̀yà Xhosa (Kósà), wọ́n bi sí ìdílé ìjòyè Thembu ní ìlú Mvezo. Ó kàwé òfin ní Yunifásítì Fort Hare àti Yunifásítì Witwatersrand kó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bí agbẹjọ́rò ní ìlú Johannesburg. Níbẹ̀ ló ti dara pọ̀ mọ́ àwọn alátakò ìmúnisìn àti ìṣèlú ọmọorílẹ̀-èdè ilẹ̀ Áfríkà, ó dara pọ̀ mọ́ ANC ní ọdún 1943, ó sí dá Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ ANC sílẹ̀ ní ọdún 1944. Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn òyìnbó fi tipátipa dá ápátáìdì sílẹ̀ ní ọdún 1948 Mandela àti gbogbo ANC búra láti gbógun tìí. Mandela di ààrẹ fún ẹ̀ka ANC ní Transvaal, níbi tó ti gbajúmọ̀ fún akitiyan rẹ̀. Wọ́n fẹ̀sùn ọ̀tẹ̀ kàn ní ọdún 1962, wọ́n sì da lẹ́bi ẹ̀sùn pé kó lọ sí àtìmọ́lé fún ìgbésíayé rẹ̀ lẹ́yìn Ìgbẹ́jọ́ Rivonia. (ìtẹ̀síwájú...)
ojúewé yìí ti jẹ dídá àbò bò láti ṣàtúnṣe sí. See the protection policy and protection log for more details. Please discuss any changes on the talk page; you may submit an edit request to ask an administrator to make an edit if it is uncontroversial or supported by consensus. You may also request that this page be unprotected. |