Jump to content

Oge Okoye: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Content deleted Content added
Created by translating the page "Oge Okoye"
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 03:46, 2 Oṣù Bélú 2020

Oge Okoye
Ọjọ́ìbí(1980-11-16)16 Oṣù Kọkànlá 1980
London, United Kingdom
Orílẹ̀-èdèBiritiṣi ati Naijiria
Iṣẹ́Osere

Oge Okoye (ti a bi ni 16 Kọkànlá Oṣù 1980) jẹ oṣere ọmọ Nàìjíríà. o wa lati Nnewi ni Ipinle Anambra ti Nigeria.[1] Ilu Lọndọnu ni a bi Oge Okoye si[2] ki o to di pe o gbere lati wa gbe ni Ilu Eko pẹlu awọn ẹbi rẹ. O pari ile-iwe alakọbẹrẹ rẹ ni Ilu Lọndọnu ṣaaju ki o to wa si Nàìjíríà. Nigbati o pada si Nàìjíríà, o tun lọ si Ile-ẹkọ alakọbẹrẹ University Primary School, Enugu ki o to tun wa lọ si Holy Rosary College, Enugu fun ẹkọ girama rẹ[3] .

O pari ile-ẹkọ giga ti Nnamdi Azikiwe University, Awka pẹlu oye ni Theatre Arts . O darapọ mọ ile-iṣẹ fiimu ti Naijiria ti a mọ ni Noollywood ni ọdun 2001. O di gbajumọ oṣere lehin ti o kopa ninu fiimu 'Spanner' ni ọdun 2002 pẹlu ajosepọ Chinedu Ikedieze ti gbogbo eniyan mọ si 'Aki' ni ile-iṣẹ fiimu ti Naijiria. O ṣe igbeyawo ni ọdun 2005 pẹlu ọrẹkunrin rẹ Stangley Duruo ti wọn ti jọ n ba ara wọn bọ fun igba pipẹ, sugbọn awọn mejeeji ti pada ṣe ipinya ni ọdun 2012 lehin ọmọ meji ti wọn ni funrawọn.[4] Ni ọdun 2006, o ri yiyan fun ami-ẹye African Movie Academy ni ẹka ti “oṣere ti o dara julọ ni ipa atilẹyin” fun iṣẹ rẹ ninu fiimu "Eagle's Bride"[5][6][7]

O tun jẹ olugberejade ati afẹwaṣiṣẹ. O ti han ninu ọpọlọpọ awọn atẹjade fun oge ṣiṣe ati awọn ikede ipolowo ọja lori Telifisoonu. O ti fi igbakan jẹ aṣoju ipolowo ọja fun awọn ile-iṣẹ bii Globacom ati MTN_Nigeria, awọn mejeeji jẹ ile-iṣẹ ti Nàìjíríà to n ri si ibaraẹnisọrọ lori ẹrọ.[8] .

Akojọ awọn ere rẹ

Ere tẹlifisiọnu

Odun Akọle Ipa Ref
2015 Hotel Majestic Patricia, ọmọ ọdọ laafin [9]

Awọn itọkasi