Oge Okoye
Oge Okoye | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | London, United Kingdom | 16 Oṣù Kọkànlá 1980
Orílẹ̀-èdè | Biritiṣi ati Naijiria |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Yunifásítì Nnamdi Azikiwe |
Iṣẹ́ | Osere |
Oge Okoye (tí a bí ní 16 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 1980) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó wá láti Nnewi ní Ìpínlẹ̀ Anámbra.[1] Ìlú Lọ́ndọ̀nù ni a bí Oge Okoye sí[2] kí ó tó di pé ó gbèrò láti wá gbé ní Ìlú Èkó pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀. Ó parí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù ṣááju kí ó tó wá sí Nàìjíríà. Nígbàtí ó padà sí Nàìjíríà, ó tún lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ University Primary School ní ìlú Enúgu, kí ó tó tún wá lọ sí Holy Rosary College fún ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀[3] .
Ó parí ilé-ẹ̀kọ́ gígai Yunifásítì Nnamdi Azikiwe, ti ìlú Awka pẹ̀lú oyè ní eré Tíátà . Ó darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ fíìmù ti Nàìjíríà tí a mọ̀ ní Nollywood ní ọdún 2001. Ó di gbajúmọ̀ òṣèré lẹ́hìn tí ó kópa nínu fíìmù 'Spanner' ní ọdún 2002 pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Chinedu Ikedieze tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí 'Ákí' nídi iṣẹ́ fíìmù ti Nàìjíríà. Ó ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 2005 pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ Stangley Duruo tí wọ́n ti jọ́ n bá ara wọn bọ̀ fún ìgbà pípẹ́, ṣùgbọ́n àwọn méjéèjì ti padà ṣe ìpinyà ní ọdún 2012 lẹ́hìn ọmọ méjì tí wọ́n ní fún arawọn.[4] Ní ọdún 2006, ó rí yíyàn fún àmì-ẹ̀ye African Movie Academy ní ẹ̀ka ti “amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ” fún ipa rẹ̀ nínu fíìmù "Eagle's Bride"[5][6][7]
Ó tún jẹ́ olùgbéréjáde àti afẹwàṣiṣẹ́. Ó ti hàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àtẹ̀jáde fún oge ṣíṣe àti àwọn ìkéde ìpolówó ọjà lóri tẹlifíṣọ̀nù. Ó ti fi ìgbàkan jẹ́ aṣojú ìpolówó ọjà fún àwọn ilé-iṣẹ́ bi Globacom àti MTN Nàìjíríà, àwọn méjéèjì jẹ́ ilé-iṣẹ́ ti Nàìjíríà tó n rí sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lóri ẹ̀rọ.[8] .
Àkójọ àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
|
|
Eré tẹlifíṣọ̀nù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọdún | Àkọ́lé | Ipa | Ìtọ́kasí |
---|---|---|---|
2015 | Hotel Majestic | Patricia, ọmọ ọdọ laafin | [9] |
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2020-11-07. Retrieved 2020-11-02.
- ↑ "Biography". Retrieved 20 June 2015.
- ↑ https://www.legit.ng/1183621-nigerian-actress-oge-okoyes-biography.html
- ↑ https://www.premiumtimesng.com/entertainment/naija-fashion/322886-actress-oge-okoye-visits-church-of-pastor-who-faked-resurrection.html
- ↑ "No Big Deal In Married Woman Going To Club - Oge Okoye". Nigerian Tribune (Ibadan, Nigeria). 30 January 2010. http://www.tribune.com.ng/sat/index.php/klieglight/164-no-big-deal-in-married-woman-going-to-club-oge-okoye.html. Retrieved 4 February 2011.
- ↑ Ogbonna, Amadi (1 August 2009). "My husband thought Iwas a prostitute, say Oge Okoye". Vanguard (Lagos, Nigeria: Vanguard Media). http://www.vanguardngr.com/2009/08/my-husband-thought-iwas-a-prostitute-say-oge-okoye/. Retrieved 4 February 2011.
- ↑ "Stars at War - Oge Okoye Battles Ini Edo Over Gossip". Allafrica.com (AllAfrica Global Media). 21 November 2010. http://allafrica.com/stories/201011221327.html. Retrieved 4 February 2011.
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2020-11-07. Retrieved 2020-11-02.
- ↑ "'Hotel Majestic' Oge Okoye, Ivie Okujaye, Bukky Ajayi star in new telenovela". Pulse Nigeria. Chidumga Izuzu. Archived from the original on 4 January 2015. Retrieved 31 December 2014.