Àṣà Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Asa at Ise

Mo tún ti dé pẹ̀lú ohùn ẹnu mi, mo tún fẹ́ sọ́nwan ní ọ̀rọ̀, lórí àṣà àti ìse ilẹ̀ Yorùbá. Nítorí náà ẹgbé àga, mo ni ejò kó kí ẹ gbọ́mi gbóhùn ẹnu mí. Mo ní kí ẹ gbólóhun tí mo fẹ́ bá gbogbo mùtúnmùwà àní ọmo adáríhunrun jẹ̀wọ̀ rẹ̀, Ẹ máa jẹ a bá òpó lo ilé olórò àní kín maa ba lo wonnaa. Òrò yìí jẹ mí ló lógún, ọ̀rọ̀ àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá. Nítorí àṣà Yorùbá jẹ́ àṣà tí ó gba yúmọ̀ láàrín àwùjọ, àní àṣà àti ìṣe wa ṣeé mú yangàn nílé àti ní oko, bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àṣà àti ìṣe Yorùbá a ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí a máa ń sẹ ìhùwàsí wa, ìrísí wa láàrín àwùjọ, Ohun méjì ní mo fẹ́ ṣọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ogún-lọ́gọ̀ àwọn àṣà àti ìṣe tí ó ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá. Àkínín ni, Àṣà àti ìsẹ Yorùbá lórí bí a se ń kíànìyàn. Èkejì ní Àsà àti ìṣe Yorùbá lórí ìsìnkú nílẹ̀ Yorùbá.

Ẹjẹ́ kí a jo ogbée yèwò, àní kí a jọ yàn-àn-náa rẹ̀. Ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé, Ìgbàgbọ́ nípa àṣà àti ìse Yorùbá lórí ìkínin ní ilẹ̀ Yorùbá. Àṣà ìkínin jẹ́ àṣà tí ó gbajúgbujà nílẹ̀ wa, ó jẹmọ́ ìgbà àti àkókò, Óníse pẹ̀lú Ohun tí ó ń sẹlẹ̀ ní dé èdè àsìkò náà. Bí Yorùbá ba jií láàrọ̀ ọmọ dé tí ó bájẹ́ okùnrin, á wà lórí ìdọ̀ bálẹ̀, èyí tí ó bá jẹ́ obìnrin àwá lórí ìkúnlẹ̀ wọn á sìn kí àwọn òbí wọn. Wọn á wípé ekú àárọ̀, àwọn òbí wọn á sìn dáwọn lóhùn wípé kárọ̀ ọmọ mí, ire ẹ́ẹ̀jí bií, bí ó bá jẹ́ òsán wọn á ṣe bákannáà, wọn á sọ wípé ẹ kú ọ̀sán àwọn òbí wọn á dáwọn ló hùn wípé ekú òsán, bí ó bá jẹ ìgbà iṣé ẹkú iṣẹ́ là ń kini. Bí ó sìn jẹ́ àṣálẹ́ ẹkú alẹ́ làń kínu nílẹ̀ Yorùbá gbogbo ìkíni ní à-sìkò wà fún, ṣùgbọ́n ọmọde nikọ́kọ́ máa ń kí àgbà. Èyí tí kò bà se bẹ́ẹ̀ ìgbàgbọ̀ Yorùbá ní wípé irú ọmọ bẹ ẹ̀ kòní ẹ̀kọ́ tàbí, wọn kọ̀ ọ nilẹ̀ kò gbà níi. Bí ó bá jẹ́ ìgbà ayẹẹ̣yẹ bíi ìsìnkú àgbà nítorí Yorùbá kìn ń se òkú ọ̀dọ́ àwọn ọ̀dọ́ ní ó má ń sètò ìsìkú wọn sí èyìn ilé. Òkú ọ̀fọ̀ ni ójẹ́ fún àwọn òbí irú ẹni bẹ́ẹ̀. Bí ó bá jẹ̀ òkú àgbà, wọn á ní ẹkú ọ̣̀fọ̀, ẹkú ìsìnku Olórun yíò mú ọjọ́ jìn-nàa sírawọn o. Bí ó bá jẹ́, Ìkó ọmọ síta wọn ání ẹkú ọwọ́ lómì o, ẹku ìtójú oni o náà. oríṣiríṣì àkókò ni ówà nínú odún. Àkókó òfìnkìn, Àkókò ọyẹ́, àkókò oòrùn, àkókò òjò, gbogbo rẹ̀ níi Yorùbá ní bí ó se ń kiní etó fún bí á se ń kúnin nílẹ̀ Yorùbá, Ẹjẹ́ á gbẹ̀ àsà ìkejì yẹ̀wò.

Àṣà àti ìse nípa ìsìnkú, mo ti so sáájú wípé óní àwọn òku tí Yorùbá máa ń se ayẹẹyẹ fún àwọn bí òkú àgbà. Nítorí wọ́n gbà wípé, ólọsinmi ni àti wípé wọ́n lọ lé. Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni wípé ọjá ni ayé ṣùgbọ́ òrun ni le. Ṣùgbọ́n bí ó bájẹ́ òkún òdó tàbí ọmọdé òkú ọ̀fọ̀ àti ìbànújẹ́, wọ́n agbà wípé àsìkòrè ò tíì tó wípé óṣékú níi. Yorùbá máa ń náà owó àti ara síí, bí ó bájẹ́ òkú ágbá. Bí ó bá tún jẹ́ pé ẹni tí óní ípò àti olá ni tí ó sìn bí ọmọ, òkún wọn máa ń lárinrin, ayé ágbọ́ òrun á sìn mọ̀ pẹ̀lú. Ní ayé àti jọ́ bí òkù bá kú àwọn àgbà àtì àwọn alúwo bí eni náà bá dara pò mọ́ ẹ̀gbẹ́ awo ní ìwàláyé rẹ́ àwọn awo ní ń sìkú irú eni bẹ́ẹ̀ wọn á pa edíẹ̀ ìrànàna wọn á sùn máà tun ìwù rẹ̀ lo bí wọ́n sẹ ń gbé òkú rẹ̀ lọ, wọn á sùn seé wọn á jẹ́ẹ, Èyí ní Yòóbù fí maa ń so wípè ẹdìẹ ìrà-nàa kò ń sohun àje gbé. Nítorí kò sí ení tí kò ní kú. Ọ̀fọ̀ ní ó máa ń jẹ tí obìnrin àní aya ilé bá sájú oko rẹ̀ kú Yorùbá gbà wípé oko ní ó máa ń sájú aya kú kìí ìyàwó máa bojú tó àwọn ọmọ. Nítorí náà bí okùnrin bákú àwọn ìyàwó irú eníbá, áse opó óníse pẹ̀lú ìlànàa àti àṣà ohun ìse irú ìpínlè okùnrin náà. ogójì ojo tà bí jú bé lọ ni wọ́n máa ń sẹ́, lẹ́hìn ìsìn-kú àwọn agbà wọ́n á sìn pín ogún olóòybé fún àwọn ọmọ rẹ̀. Bí ó bájẹ́ òkú olọ́mọ. Ṣùgbọ́n tí kò bá bí’ mo, Àwọn ebí rẹ̀, nipátàkì jùlọ, Àwọn ọmọ ìyá rẹ́ tí ó tun lọ ní wọ́n máa n pín ogún náà ní àárin ara wọn, Ótújẹ́ àṣà àti ìsẹ Yorùbá wípé kí wọn máa ń ṣu lópó aya olóògbé lópó fún àwọn àbúrò olóògbé wípé kí ó fi se aya.

ÀSÀ YORÙBÁ

Àṣà ni ohun gbobgo tó jẹ mọ́ ìgbé ayé àwọn asùwàdà ènìyàn kan ni àdúgbò kan, bẹ̀rẹ̀ lórí èrò, èdè, ẹ̀sìn, ètò ìsèlú, ètò ọrọ̀ ajé, ìsẹ̀dá ohun èlò, ìtàn, òfin, ìṣe, ìrísí, ìhùwàsí, ọnà, oúnjẹ, ọ̀nà ìṣe nǹkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò kọ̀ọ̀kan padà. Pàtàkì jùlọ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, eré ìbílẹ̀ àti iṣẹ́ ìbílẹ̀ ni a lè pè ní àṣà. Ohun ti o jẹ orírun àṣà ni ‘àrà’, ó lè dára tàbí kí ó burú. Ìpolówó Èkìtì – iyan rere, obe rere; Ipolowo Oǹdó Ẹ̀gin – (dípò Iyán) ẹ̀bà gbọn fẹẹ. Àṣà Oǹdó ni kí wọ́n máa pe iyán ni ẹ̀bà nítorí pé èèwọ̀ wọn ni, wọn kò gbọ́dọ̀ polówó iyán ni àárín ìlú. Àṣà jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ àpẹẹrẹ; àbíkú, àkúdàáyá. Àṣà jẹ mọ́ iṣẹ́ ọnà ti a lè fojú rí tàbí aláfẹnusọ. A lè pín àṣà sí ìsọ̀rí mẹ́ta èyí tí ó jẹ mọ́:

(a) Ọgbọ́n ìmò, ète tàbí ètò tí a ń gbà ṣe nǹken, àpẹẹrẹ ilà kíkọ, irun dídì abbl.

(b) Iṣẹ́ ọnà bíi igi gbígbẹ́

(d) Bí a ṣe ń darí ìhùwàsí àwọn ẹgbẹ́/ẹ̀yà kan Ara àbùdá àṣà ni pé: Kò lè súyọ láìsí ènìyàn; ẹ̀mí rẹ̀ gùn ju ti ènìyàn lọ; Ó jẹ mọ́ ohun tí a fojúrí; Àṣà kọ̀ọ̀kan ló ní ìdí kan pàtó; Àlàyé wà nípa àṣà. Àṣà lè jẹyọ nínú oúnjẹ: Òkèlè wọ́ pọ̀ nínú oúnjẹ wa. Àkókó kúndùn ẹ̀bà, Ìlàje-pupuru, Igbó ọrà-láfún. Àṣà lè jẹyọ nínú ìtọ́jú oyún/aláìsàn/òkú; ètò ebí/àjọsepọ̀; ètò ìṣàkóso àdúgbò, abúlé tàbí lara dídá nípa iṣẹ́ ọnà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbeyàwó abbl lóde òní ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti se àkóbá fún àṣà ní ọ̀nà yìí:

(a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́

(b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́

(d) Kí’yàwò ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́

(e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́.

Àwọn ọ̀nà tí àṣà máa ń gbà yí padà nì wọ̀nyí:

(a) Bí àṣà tó wà nílẹ̀ bá lágbára ju èyí tó jẹ́ tuntun lọ, èyí tó wà tẹ́lẹ̀ yóò borí tuntun, àpẹẹrẹ aṣọ wíwọ̀.

(b) Àyípadà lè wáyé bí àṣà tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ bá jẹ́ dọ́gbandógba pẹ̀lú àṣà tuntun, wọ́n lè jọ rìn papọ̀, bí àpẹẹrẹ àṣà ìgbéyàwó.

(d) Bí àṣà tuntun bá lágbára ju èyí tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, yóò sọ àṣà ti àtẹ̀hìnwọ́di ohun ìgbàgbé, àpẹẹrẹ bí a se ń kọ́lé.

Tí a bá wá wò ó fínnífínní, a ri wí pé àṣà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìtbà máa ń dá lé:

(a) Ìmọ̀ iṣé sáyẹ́ǹsì

(b) Ìṣe jẹun wa

(d) Ìsọwọ́ kọ́lé

(e) Iṣẹ́ ọwọ́ ní síṣe

ÀKÍYÈSI:-

Èdè àwọn ènìyàn jẹ́ kókó kan pàtàkì nínú àṣà wọn. Kò sí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò nínú àṣà àti èdè. Ìbejì ni wọ́n. Ọjọ́ kan náà ni wọ́n délé ayé nítorí pé kò sí ohun tí a fẹ́ sọ nípa àṣà tí kì í ṣe pé èdè ni a ó fi gbé e kalẹ̀. Láti ara èdè pàápàá ni a ti lè fa àṣà yọ. A lè fi èdè Yorùbá sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni, a lè fi kọrin, a lè fi kéwì, a lè fi jósìn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láti ara àwọn nǹkan tí a ń sọ jáde lẹ́nu wọ̀nyí ni àṣà wa ti ń jẹyọ. Ara èdè Yorùbá náà ni òwe àti àwọn àkànlò-èdè gbogbo. A lè fa púpọ̀ nínú àwọn àṣà wa yọ láti ara òw àti àkànlò èdè. Nítorí náà, èdè ni ó jẹ́ òpómúléró fún àṣà Yorùbá àti wí pé òun ni ó fà á tí ó fi jẹ́ wí pé bí àwọn ọmọ Odùduwà ṣe tàn kálẹ̀, orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n, èdè kan náà ni wọ́n ń sọ níbikíbi tí wọ́n lè wà. Ìṣesí, ìhùwàsí, àṣà àti ẹ̀sìn wọn kò yàtọ̀. Fún ìdí èyí, láísí ènìyàn kò lè sí àṣà rárá.

REFERENCE TEXTBOOKS:

1. Adeoye C.L. (1979) Àṣà àti iṣe Yorùbá Oxford University Press Limited

2. J.A. Atanda (1980) An introduction to Yoruba History Ibadan University Press Limited

3. Adeomola Fasiku (1995) Igbajo and its People Printed by Writers Press Limited

4. G.O. Olusanya (1983) Studies in Yorùbá History and Culture Ibadan University Press Limited.

5. Rev. Samuel Johnson (1921) The History of the Yorubas A divisional of CSS Limited.