Àdàkọ:Àyokà Ose/18
Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ (6 oṣù kẹta ọdún 1909 - 9 oṣù karún ọdún 1987), jẹ́ olósèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ẹ̀yà Yorùbá. Awólọ̀wọ̀ jẹ́ olórí fún àwon ọmọ ilẹ̀ Yorùbá àti ọ̀kan nínú àwọn olóṣèlú pàtàkì ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. A bí ni ọjọ́ kẹfà osù kẹta ọdún 1909 ni Ìkẹ́nnẹ́ tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun lóòní. Omo àgbẹ̀ tí ó fi iṣẹ́ àti ògùn ìsẹ́ ṣọ ara rẹ̀ di ọ̀mọ̀wé, Awólọ́wọ̀ lọ ilé ẹ̀kọ́ Anglican àti Methodìst ni Ikénne àti ni Baptist Boys' High School ni Abéòkúta. Lèyìn rè ó ló sí Wesley College ni Ibàdàn tí ó fi ìgbà kan jé olùìlú Agbègbè Apáìwọ̀òrùn Nàìjíríà láti ba di Olùko. Ní ọdún 1934 , ó di olùtajà àti oníròyìn. O se olùdarí àti alákóso Egbé Olùtajà Awon Omo Nàìjíríà (Nigerian Produce Traders Association) àti àkòwé gbogbogbo Egbé Awon Awako Igb'eru Omo Ilè Nàìjíríà (Nigerian Motor Transport Union).
àdàkọ yìí ti jẹ dídá àbò bò láti ṣàtúnṣe sí. See the protection policy and protection log for more details. Please discuss any changes on the talk page; you may submit an edit request to ask an administrator to make an edit if it is uncontroversial or supported by consensus. You may also request that this page be unprotected. |