Ìwà Ìfipá báni-lòpọ̀
Ìwà ìfipá báni-lòpọ̀ tabí Ìbáni lòpọ̀ lọ́nà àìtọ́ jẹ́ ìfipá múni láti bá ṣe àṣepọ̀ yálà láti ọwọ́ akọ (ọkùnrin)tàbí abo (Obìnrin) nígbà tí ẹni tí a fipá mú kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ìbálòpọ̀ lásìkò tí a fẹ́ ba ṣeré lọ́kọ-láy. Ìwà Ìfipá báni-lòpọ̀ yí lè wáyé nípa fífi agbára múni tàbí lílo ipò àṣẹ fúni láti báni-lòpọ̀ lọ́nà àìtọ́, nígbà tí ẹni tí a fẹ́ fi agbára mú kò bá ní ọ̀nà tí ó lè fi dáàbò bo ara rẹ̀ lásìkò náà, tàbí kí ẹni tí a fẹ́ hùwà kò tọ́ sí ó kéré jọjọ lọ́jọ́ orí.[1][2][3] [4]
Àkójọpọ̀ àkọsílẹ̀ ìwà ìfipá báni-lòpọ̀ lágbày
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ẹ̀sùn ìwà ìfipá báni-lòpọ̀ àti ìfìyà-jẹni lórí ìwà kò tọ́ yí yàtọ̀ sí ara wọn ní orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ní agbáyé. Lápapọ̀, iye àwọn ènìyàn tí a fi ẹ̀sùn ìwà ìfipá báni-lòpọ̀ tí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 2008 jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́eùn ún (100,000 people), láti 0.2 ní Azerbaijan sí 92.9 ní ìlú Botswana ati 6.3 ní ìlú Lithuania gẹ́gẹ́ bí ìdá méjì (median) ìṣẹ̀lẹ̀ yí lágbàyé [5] Nínú akójọ àkọsílẹ̀ nípa ìwà ìfipá báni-lòpọ̀ lágbàyé, ọkùnrin ló sábà ma ń hùwà kò tọ́ yí sí obìnrin jùlọ.[6]
Àwọn ìlànà ìfipá báni-lòpọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìwà ìfipá báni-lòpọ̀ láti ọwọ́ àrè tàbí àlejò kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ nínú àwọn ẹ̀sùn yí, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn alábàágbé tàbí aládùúgbò ẹni tí a mọ̀ dára dára. Ìwà ìfipá báni-lòpọ̀ akọ sákọ tàbí abo sábo àti ìfipá báni-lòpọ̀ tinú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú ìlànà ìfipá báni-lòpọ̀ tó wọ́pọ̀ jùlọ tí wọ́n.ṣe àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn rẹ̀ jùlọ lágbàyé.[7][8][9] Ìwà ìfipá báni-lòpọ̀ẹlẹẹ́wẹ̀ẹ́ ni ọ̀nà lílo ogun àti ìsọni dohun èlò ìbálòpọ̀ (sexual slavery). Àwọn ìlànà wọ̀nyí ló ma ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ogun, ìjà, tàbí ìdárú-dàpọ̀ bá bẹ́ sílẹ̀ nílú kan tabi orílẹ̀-èdè kan. Àwọn ìhùwàsí yí làwọn àsìkò tí a mẹ́nu bà yí ni wọ́n ń pè ní ìwà ọ̀danràn tako ọmọnìyàn (crime against humanity) àti Ọ̀ràn ogun (war crime).
Ìpalára tí ìwà ìfipá báni-lòpọ̀ ma ń mú wá
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Púpọ̀ èyàn tí wọ́n ti fipá bá lòpọ̀ lè ní ìpèníjà ọpọlọ tàbí kí wọ́n dojú kọ ìṣòro àrùn ọpọlọ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. [10] Ẹ̀wẹ̀, ìpalára tó lágbara lè ṣẹlẹ̀ sí ẹni a fipá bà lòpọ̀, lẹ́yìn kí ó lóyún. Àwọn arùn ìàfojúrí tí a lè kó látara ìbálòpọ̀ lè gbabẹ̀ wọlé sí ẹni náà lára, ẹni a fipá bá lòpọ̀ tún lè ma kojú ìdókùkù-lajà láti ọwọ́ ẹni tí ó hùwà àìtọ́ yí síi, tàbí kí àwọn ẹbí ọ̀daràn ó tú ma lérí sí ẹni nà pàá pàá jùlọ nínú àṣà ilẹ̀ ibòmíràn. [11][12][13]
Bí a ṣe lè dẹ́kun rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wípé ìwà ìfipá báni-lòpọ̀ ń kó ìpalára bá wa ní àwọn àwùjọ wa gbogbo, ìjí gìrì sí ìdẹ́kun ìwà ọ̀daran yí ṣe pàtàkì. Ìjí gìrì yí lè dá lórí àwọn ìlàna ìsàlẹ̀ yí:
- Dídábò bo ara ẹni.
- Sísapá àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera.
- Gbígbé ìgbésẹ̀ tó nípọn àwùjọ nípa fífi ìyà tó lágbara jẹ èyí-kéyí ọ̀daràn ní gbangba.
- líla awọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ọlọ́dún mẹ́wàá lọ́yẹ̀ lórí ìpalára rẹ̀,
- líla awọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ àgbà lọ́yẹ̀ lórí ìpalára rẹ̀,
- líla awọn òṣìṣẹ́ lọ́yẹ̀ lórí ìpalára rẹ̀. [14][15][16][17] [15][18][19]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Sexual violence chapter 6" (PDF). World Health Organization. 2002. Archived from the original (PDF) on 5 April 2015. Retrieved 5 December 2015.
- ↑ "Rape". dictionary.reference.com. April 15, 2011.
- ↑ "Rape". legal-dictionary.thefreedictionary.com. April 15, 2011.
- ↑ Petrak, Jenny; Hedge, Barbara, eds (2003). The Trauma of Sexual Assault Treatment, Prevention and Practice.. Chichester: John Wiley & Sons. p. 2. ISBN 978-0-470-85138-8. https://books.google.com/books?id=6KZfQ6cSVHoC&pg=PA2.
- ↑ "Rape at the National Level, number of police recorded offenses". United Nations.
- ↑ "Violence against women". World Health Organization. Retrieved 2017-09-08.
- ↑ Human Rights WatchNo Escape: Male Rape In U.S. Prisons. Part VII. Anomaly or Epidemic: The Incidence of Prisoner-on-Prisoner Rape.; estimates that 100,000–140,000 violent male-male rapes occur in U.S. prisons annually; compare with FBI statistics that estimate 90,000 violent male-female rapes occur annually.
- ↑ Robert W. Dumond, "Ignominious Victims: Effective Treatment of Male Sexual Assault in Prison," August 15, 1995, p. 2; states that "evidence suggests that [male-male sexual assault in prison] may be a staggering problem". Quoted in Mariner, Joanne; (Organization), Human Rights Watch (2001-04-17). No escape: male rape in U.S. prisons. Human Rights Watch. p. 370. ISBN 978-1-56432-258-6. https://books.google.com/books?id=QkFfYfEO5IgC&pg=PA370. Retrieved 7 June 2010.
- ↑ Struckman-Johnson, Cindy; David Struckman-Johnson (2006). "A Comparison of Sexual Coercion Experiences Reported by Men and Women in Prison". Journal of Interpersonal Violence 21 (12): 1591–1615. doi:10.1177/0886260506294240. ISSN 0886-2605. PMID 17065656.; reports that "Greater percentages of men (70%) than women (29%) reported that their incident resulted in oral, vaginal, or anal sex. More men (54%) than women (28%) reported an incident that was classified as rape."
- ↑ "Post Traumatic Stress Disorder in Rape Survivors". The American Academy of Experts in Traumatic Stress. 1995. Retrieved 2013-04-30.
- ↑ "Rape victim threatened to withdraw case in UP". Zeenews.india.com. 2011-03-19. Retrieved 2013-02-03.
- ↑ "Stigmatization of Rape & Honor Killings". WISE Muslim Women. 2002-01-31. Archived from the original on 2012-11-08. Retrieved 2013-02-03. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Harter, Pascale (2011-06-14). "BBC News - Libya rape victims 'face honour killings'". BBC News. https://www.bbc.co.uk/news/world-africa-13760895. Retrieved 2013-02-03.
- ↑ Smothers M.K.; Smothers, D. Brian (2011). "A Sexual Assault Primary Prevention Model with Diverse Urban Youth". Journal of Child Sexual Abuse 20 (6): 708–27. doi:10.1080/10538712.2011.622355. PMID 22126112.
- ↑ 15.0 15.1 Foubert J.D. (2000). "The Longitudinal Effects of a Rape-prevention Program on Fraternity Men's Attitudes, Behavioral Intent, and Behavior". Journal of American College Health 48 (4): 158–63. doi:10.1080/07448480009595691. PMID 10650733. https://apps.carleton.edu/campus/gsc/assets/1_4_Longitudinal_Effects.pdf.
- ↑ Vladutiu C.J. (2011). "College- or university-based sexual assault prevention programs: a review of program outcomes, characteristics, and recommendations". Trauma, Violence, and Abuse 12 (2): 67–86. doi:10.1177/1524838010390708. PMID 21196436.
- ↑ "Sexual assault prevention programs: current issues, future directions, and the potential efficacy of interventions with women". Clin Psychol Rev 19 (7): 739–71. November 1999. doi:10.1016/S0272-7358(98)00075-0. PMID 10520434.
- ↑ Garrity S.E. (2011). "Sexual assault prevention programs for college-aged men: A critical evaluation". Journal of Forensic Nursing 7 (1): 40–8. doi:10.1111/j.1939-3938.2010.01094.x. PMID 21348933.
- ↑ Sorenson SB, Joshi M, Sivitz E. Knowing a sexual assault victim or perpetrator: A stratified random sample of undergraduates at one university. Journal of Interpersonal Violence, 2014; 29: 394-416