Ṣeun Ọmọ́jọlà
Ṣeun Ọmọ́jọlà | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Oluwaseun Omolara Omojola Lagos, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | Singer, songwriter, actress, producer |
Ìgbà iṣẹ́ | 2003–present |
Notable work | Mo fe bae lo |
Ṣeun Ọmọ́jọlà (tí àbísọ rẹ̀ jẹ́ Olúwaṣeun Ọmọlará Ọmọ́jọlà) jẹ́ akọrin, akọ̀wé orin àti òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Nígbà kan rí, ó ti lo Vilara gẹ́gẹ́ bi ìnagijẹ rẹ̀ nídi iṣẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n ó padà wá pinnu láti maá lo orúkọ rẹ̀ gangan tí n ṣe Ṣeun Ọmọ́jọlà. Gẹ́gẹ́ bi akọrin, àkọ́kọ́ orin àdákọ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ 'Mó fẹ báẹ lọ' jẹ́ gbígbéjáde ní Oṣù Kẹẹ̀ta Ọdún 2012.[1]Ṣùgbọ́n ọdún 2003 ni ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ òṣèré, ó sì ti kópa nínu àwọn fíìmù Nollywood tó lé ní ogún láti ìgbà náà [2]
Ní ọdún 2016 òun pẹ̀lú Jọkẹ́ Jìgan, Jaiyé Kutì àti Tèmítáyọ̀ Adéníyì dì jọ ṣe Talonírọ́, èyítí wọ́n ṣe àkọ́kọ́ ìpolówó rẹ̀ ni ilé-ìwé London Film Academy ní oṣù kíní ọdún náà.[3] Lẹ́yìnwá ìgbà náà, ó ṣe Unjustified pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Frederick Leonard, Bọ́lánlé Nínálowó àti Esther Audu.[4]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Biography/Profile/History Of Nollywood Actress Seun Omolara Omojola". Daily Mail (Nigeria). 13 May 2016. Archived from the original on 5 November 2016. Retrieved 15 September 2016.
- ↑ "Curvy & Chic! Meet Actress & Singer, Seun Omolara Omojola A.K.A ‘Vilara’". Onobello. Archived from the original on 14 September 2016. Retrieved 15 September 2016.
- ↑ "Seun Omojola Unveils New Movie ‘Taloniro'(Watch)". Moji Delano. Retrieved 24 January 2016.
- ↑ "Watch the Trailer for "Unjustified" starring Frederick Leonard, Seun Omojola, Bolanle Ninalowo, Esther Audu & More". Bellanaija. 6 July 2016. Retrieved 15 September 2016.