Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Akínwálé
Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Akínwálé | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ìlú Ìbàdàn |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Yunifásítì ìlú Ìbàdàn |
Iṣẹ́ | òṣèré orí-ìtàgé |
Notable work | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀ |
Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Akínwálé jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé àti sinimá àgbéléwò, olùgbéré jáde ati Olùkọ́ àgbà fásitì.
Ìgbésí ayé ati ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Akínwálé ní Ìlú Ìbàdàn, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ oníwé mẹ́wàá ti Methodist High School àti Yunifásítì ìlú Ìbàdàn. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àgbà ní ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti ìlú Ìbàdàn.[1] Ó tún jẹ́ adarí ẹ̀ka ètò-ẹ̀kọ́ ti Faculty of Arts and Culture ní University of Ilorin.[2][3] Ọ̀jọgbọ́n Akínwálé nígbà ayé rẹ̀ tún jẹ́ alága fún ìgbìmọ̀ àwọn oníṣẹ́-ọnà (Council for Artand Culture) ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Bákan náà ni ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn eré ọdún ìbílẹ̀ oríṣiríṣi ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ìtàgé rẹ̀ ní ọdún 1970s níbi tí ó kópa ní àwọn eré sinimá orí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán àti àwọn eré ìtagé mìíràn.[1] Ó ti gba àmì ẹ̀yẹ ìdánọ́lá ti 4th Africa Movie Academy Awards ẹlẹ́kẹrin irú rẹ̀ níbi tí wọ́n ti yàán gẹ́gẹ́ bí òṣèré orí-ìtàgé ọkùnrin tí ó peregedé jùlọ..[4]
Àwọn sinimá tí ó ti ṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Sango (1997)
- Ladepo Omo Adanwo (2005)
- Iranse Aje (2007)
Ikú rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwálé ṣaláìsí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹsàán ọdún 2020.
Àwọn ìtọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 "Professor Ayo Akinwale". Dawn Commission. Archived from the original on August 13, 2015. Retrieved August 29, 2015.
- ↑ "Don Tasks Nollywood on Professionalism". thisdaylive.com. Archived from the original on 15 November 2014. Retrieved 15 November 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Lecturers as Nollywood Stars". modernghana.com. Retrieved 15 November 2014.
- ↑ "Between Film And Professionalism". thisdaylive.com. Archived from the original on 15 November 2014. Retrieved 15 November 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)
Àwọn Ìtàkùn ìjásóde
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Pages with citations using unsupported parameters
- Àwọn òṣeré ará Nàìjíríà
- Nigerian male film actors
- University of Ilorin faculty
- Àwọn ènìyàn alààyè
- Best Actor Africa Movie Academy Award winners
- 20th-century Nigerian male actors
- 21st-century Nigerian male actors
- Male actors from Ibadan
- Yoruba male actors
- Nigerian academics
- Yoruba academics
- The Polytechnic, Ibadan faculty
- Male actors in Yoruba cinema
- Year of birth missing (living people)