Ọlọ
Ọlọ ni ó jẹ́ ọ̀kan lára ohun èlò Ilé ìdáná tí wọ́n ma ń lò láti pèsè tàbí lọ oríṣiríṣi nkan bí ata, ẹ̀wà, ẹ̀gúsí, àlùbọ́sà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́é lọ.
Ìrísí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọlọ ní ojú tó tẹ́ pẹrẹsẹ, tí ó sì mọ níwọ̀n tí ó ṣeé gbé láti ibìkan sí ibòmíràn. Ẹ̀wé, ọlọ ma ń ní ọmọ ọlọ tí ó ṣé gbámú lẹ̀lú ọeọ́ kna tàbí ọwọ́ méjèèjì nígbà tí a bá fẹ́ lòó.
Ohun tí wọ́n fi ń ṣe Ọlọ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Láyé àtijọ́, àpáta tí ó sàn ni wọ́n ma ń lò láti fi ṣe ọlọ, tí wọn yóò sì wá òkúta tí ó tóbi mọ nìwọ̀n tí wọ́n lè fi ṣe ọmọ ọlọ. Àmọ́ láyé òde òní, diẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ni wọ́n tún bìkítà láti máa lo àpáta láti fi ṣe ọlọ tàbí ọmọ ọlọ mọ́, wọ́n ti ń lo ẹ̀rúnrún tàbí àfọ́kù àpáta tó ti di iyẹ̀pẹ̀ àti símẹ́ntì ìkọ́lé ṣe ọlọ ní ọ̀nà àrà àti ti ìgbà lódé tí ó s8 ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ti àpáta ayé àtijọ́. Ó kan jẹ́ wípé àwọn ẹ̀rún iyẹ̀pẹ̀ kọ̀ọ̀kan ma ń wà nínú ohun tí a bá lọ̀ lórí ọlọ ìgbà lódé ni. [1][2]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Maize and What They Call Rice, and Other Seeds" Royal Commentaries of the Incas and General History of Peru Chapter 7: The Empire Before Arrival of the Spaniards, p. 74
- ↑ Morvelli, Walter Coraza "The Best Flavor in Cuzco’s Cooking Still Comes from the Batán, the Grinding Stones." Archived 2023-03-22 at the Wayback Machine. 24 January 2013 Cusco Eats: Food and Culture of the Andes
- ↑ A Feature on the Sil Batta – The traditional Stone Grinder of the Indian Kitchen" Archived 2020-01-11 at the Wayback Machine. NMTV.tv March 3, 2011, Accessed March 4, 2017
- ↑ "Bhimthadi Jatra: A melange of craftsmanship and tradition" December 13, 2014 The Times of India website, Retrieved March 4, 2017
- ↑ [ta.wiktionary.org/wiki/அம்மி Meaning of the word in Tamil Wiktionary]
- ↑ [ml.wiktionary.org/wiki/അമ്മി[Wiktionary]
.