9ice

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

9ice, tí orúkọ rẹ jẹ Alexander Ábọ̀lọrẹ Adégbọlá Àkàndé (wọ́n bí ni ọjọ́ kẹtàdínlógún Oṣù Ṣéẹ́rẹ́, ọdun 1980), ó jẹ́ olórin, òǹkọ̀tàn-orin, oníjó ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà. Ó gbajúmọ̀ fún ìgbédègbẹyọ̀ rẹ̀, òwe lílò àti àgbékalẹ̀ orin rẹ̀ lọ́nà àrà.

9ice

Ìdílé olórogún ni 9ice ti wá, bàbá rẹ̀ ní ìyàwó márùn-ún àti ọmọ mẹ́sàn-àn ní Ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní Ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Ó dàgbà ní agbègbè Shomolu Bàrígà, Èkó. Ó wù 9ice láti jẹ́ olórin. Àwọn òbí rẹ̀ ṣe àkíyèsí ẹ̀bùn orin kíkọ rẹ̀, wọ́n sì gbà á láàyè láti di olórin.[1] Ó ni ìyàwó tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adẹ́tọ́lá Anífálájé, Ọlọ́run sì fi ọmọ jíìkí wọn.

Ní odun 2014, 9ice du ipò lábẹ́ Àsìá All Progressive Congress(APC) láti di aṣojú-ṣofin nílé Ìgbìmọ̀ Aṣofin ṣùgbọ́n kò wọlẹ́ ìbò. Nínú ìdìbò inú-ilé (Primaries) ló ti jákulẹ̀.Gómìnà Abíọ́lá Ajímọ̀bi sì fi jẹ oludàmọ́ràn pàtàkì sí gómìnà.

Ìdàgbàsókè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

9ice lọ sí ilé-ẹ̀kọalákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ ẹ Abúlé Okuta àti Ilé-ẹ̀kọ́ Gírámà CMS. Kò kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin tí ó lọ ṣe ní Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Èkó, ní ṣe ló gbájúmọ́ iṣẹ́ orin tí ó yàn láàyò. Ó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ ni ọdún 2000, ó fẹ́ràn Pasuma Wonder. Kẹ́sẹ́ tí ó ń gùn ún láti fi gbe orin rẹ̀ kalẹ̀ ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdúgbò rẹ̀ àti àwọn olórin aṣáájú tí rí ó rí bí àwókọ́ṣe bíi

Ebenezer Obey, King Sunny Adé, TÀlàmú Alamu, olóògbé AÀyìnláAỌmọwúraoàti , ati ològbé AHarunaHaruna Ishola.

Ìbẹrẹ Iṣẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1996, ló kọ́kọ́ ṣe rẹ́kọ̀ọ̀dù alápèjúwe tí ó pè ní Risi de Alagbaja ṣùgbọ́n ọdún 2000 ló tó gbé rẹ́kọ̀ọ̀dù àkọ́kọ́ rẹ tí ó pè ni Little Money jáde.

Ní ọdún 2008, 9ice gbé orin Gọngọ Ásọ. Tí orin náà sí gbalẹ̀ káàkiri, èyí sì mú kí wọ́n sọ pé kí ó wà kọ orin níbi ọjọ́ọ̀bí àádọ́rùn-ún ọdún Nelson Mandela ní ìlú London, United Kingdom ní Oṣù Òkudù 2008. Ó gba àmì ẹ̀yẹ olórin tàkasúfèé tí ó dára jù lọ ní MTV Africa Music Awards.

Gọngọ Aṣọ náà gbà àmì ẹ̀yẹ mẹ́rin níbi 2009 Hiphop World Awards tí ó wáyé ní International Conference Centre, Abuja.

Ní ọdún 2020, 9ice gbé àwo orin mìíràn jáde ti ó pè ní "Tip of the Iceberg". Òun ni olùdásílẹ̀ àti alákòóso iléeṣẹ́ agbórin-jáde Alápòméjì Ancestral Record


Àrà rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

9ice máa ń lo èdè Yorùbá nínú àwọn orin é. Nígbà mìíràn ó má ń lo àwọn Òwe èdè Yorùbá, tàbí kí ó ṣe àmúlùmúlà pẹ̀lú èdè Hausa, Igbo tabi èdè òyìnbó.

Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Oladipo, Tomi (2008-11-23). "Nigerians sweep MTV Africa awards". BBC NEWS. Retrieved 2022-08-10.