Abdul-Azeez Olajide Adediran
Jandor | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 25 Oṣù Kọkànlá 1977 |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Ẹ̀kọ́ |
|
Iṣẹ́ | Journalist Politician |
Olólùfẹ́ | Maryam Olajide Adediran |
Parent(s) | Alhaji Adeniran and Late Mrs Ruth Oluwafunmilayo |
Abdul-Azeez Olajide Adediran tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Jandor, jẹ́ olóṣèlú Nàìjíríà, oniroyin, oníṣòwò àti onímọ̀-ẹ̀rọ.[1] Òun ni alága ẹgbẹ́ Lagos4Lagos àti olùdíje ipò gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party pẹ̀lú olùdíje àti igbákejì rẹ̀, Funke Akindele .[2][3][4] Ó gba Doctorate Honorary nínú ètò ìdarí àti ìṣèjọba ní South American University, ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà.[5]
Ìgbésí ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Jandor sí ìdílé Alhaji Adeniran àti olóògbé Ruth Oluwafunmilayo Adeniran ni ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 1977 ní agbègbè Mushin ní ìpínlẹ̀ Èkó.[6] Jandor jẹ́ akékọ̀ọ́-gboyè láti ilé-ìwé gíga ti polytechnic ti ilú Ìbàdàn, Modul University, Vienna, Howard University School of Business, Washington DC, ní Orílẹ̀ èdè America àti Oxford University, United Kingdom .
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Jandor bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú iṣẹ́-ìròyìn, tí ó sì jẹ́ akọ̀ròyìn fún bíi ogún ọdún. Ó padà wọ inú òṣèlú, ó sì darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC. Òun ni olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbìmọ̀ ti Lagos4Lagos, ẹgbẹ́ kan lábẹ́ APC.[7] Níkẹyìn, ó padà lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ PDP, ó sì jẹ́ olùdíje ipò gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó tó kọjá.[8][9][10]
Ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Maryam Ọlajide Adediran ni ìyàwó rẹ̀, wọ́n sì bí ọmọ méji; Fareedah Oluwamayokun Amoke àti Fadhilulah Oluwamurewa Adedayo Akanniade Olajide-Adediran.[11]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Olajide Adediran (Jandor): Biography, Wife, Children, Political Career, and Source of Wealth". NewswireNGR (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-07-13. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ Jonathan, Oladayo (2022-07-13). "Lagos 2023: How Funke Akindele and I will defeat Sanwo-Olu, APC — PDP gov candidate - Premium Times Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-14.
- ↑ Informant247, The (2022-07-13). "Olajide Adediran Jandor Net Worth, Biography, Age, PDP, Wiki". The Informant247 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Lagos4Lagos Visioner Jandor Wins PDP Guber Primary Election | Channels Television". www.channelstv.com. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Abdul-Azeez Olajide Adediran Biography and Detailed Profile". Politicians Data (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-06-05. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Olajide Adediran Jandor Biography, Net Worth, Age, Family, Wife" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-07-13. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Lagos4Lagos Movement fires chairman over alleged N100 million bribe from Tinubu". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-04-20. Archived from the original on 2022-07-27. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Olajide Adediran (Jandor): Biography, Wife, Children, Political Career, and Source of Wealth". NewswireNGR (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-07-13. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Adediran defeats Vaughn, emerges Lagos PDP gov candidate". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-05-26. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ Report, Agency (2022-05-26). "Jandor clinches PDP guber ticket in Lagos - Premium Times Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-14.
- ↑ Informant247, The (2022-07-13). "Olajide Adediran Jandor Net Worth, Biography, Age, PDP, Wiki". The Informant247 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-14.