Adeniran Ogunsanya
Ọmọ-Ọba Adeniran Ogunsanya Q.C. S.A.N. | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Adéníran Ògúnsànyà ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù January ọdún 1918 Ikorodu, Lagos |
Aláìsí | 22 November 1996 (ẹni ọdun 78) |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Amòfin àti Olóṣèlú |
Adéníran Ògúnsànyà, QC, SAN (tí wọ́n bí lọ́jọ́ 31, oṣù kìíní ọdún 1918 – Ọjọ́ kejìlélógún oṣù kọkànlá ọdún 1996) jẹ́ amòfin àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó sì tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Ibadan Peoples Party (IPP). Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kọmíṣọ́nà fún ètò ìdájọ́ ati ètò ẹ̀kọ́ fún Ìpínlẹ̀ Èkó ní àsìkò ìṣèjọba alágbádá ẹlẹ́ẹ̀kejì. Òun náà tún ni alága pátá pátá fún ẹgbẹ́ òṣèlú Nigerian People's Party nígbà ayé rẹ̀.[1]
Ìgbà èwe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Adéníran ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kìíní ọdún 1918[2] ní agbègbè Ìkòròdú ní Ìpínlẹ̀ Èkó sí agbo ilé ọmọ Ọba Sùbérù Ògúnsànyà Ògúntádé tí ó jẹ́ Ọ̀dọ̀fin ti ìlú Ìkòròdú nígbà náà. Adéníran lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Hope Waddell Training Institute ní ìlú Calabar nígbà tí ó ń gbé pẹ̀lú àbúrò bàbá rẹ̀ tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba ní ìlú Calabar. [3] Ìjọba fi ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ dá Adéníran lọ́lá láti kàwé síwájú sí i ní ilé-ẹ̀kọ́ King's College tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó nítorí pé òun ló gbégbá orókè jù nínú ìdánwò àṣekágbá ti Standard VI (6) ní ọdún 1937. Ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀-òfin ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti University of Manchester àti Gray's Inn tí ó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀-òfin.[4]
Ìṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amòfin
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Adéníran bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amòfin lábẹ́ ilé-iṣẹ́ amòfin Olóyè T.O.S. Benson ní ìlú Èkó, lẹ́yìn tí ó padà dé láti ìlú Ọba.[5] Ó dara pọ̀ mọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sulu Adébáyọ̀ Ògúnsànyà láti dá ilé-iṣẹ́ amòfin tiwọn sílẹ̀ tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ògúnsànyà & Ògúnsànyà Chambers ní ọdún 1956. [6]
Ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Láàárín ọdún 1950, Adéníran ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkàn nínú àwọn abẹnugan ẹgbẹ́ òṣèlú National Council of Nigeria and the Cameroons. Kódà, òun ni Ààrẹ fún àwọn ọ̀dọ́ inú ẹgbẹ́ òṣèlú NCNC ní ọdún 1959, ó sì tún di aṣojú ẹkùn rẹ̀ Ìkẹjà àti Mushin nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin.[1] Adéníran dipò jànkàn-jànkàn mú nínú ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ àti iṣẹ́ ọba Ìpínlẹ̀ Èkó lápapọ̀. Nínú ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀, ó fìgbà kan rí jẹ́ Alága gbogboògbò fún àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ inú ẹgbẹ́ náà ati adarí fún àwọn àgbààgbà olóṣèlú fún àwọn ẹkùn amọ́nà ìjọba Gẹ̀ẹ́sì, ṣáájú kí ó tó ṣe akọ̀wé fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin. Lẹ́yìn èyí, ó ṣe Alága fún àwọn alábòójútó Ìjọba ìbílẹ̀ Mushin. Ṣáájú kí ìṣèjọba alágbádá akọ́kọ́ tó dojú dé, Adéníran ti ṣe Mínísítà fún ìjọba àpapọ̀ lórí ètò ilé-ìgbé lábẹ́ ìṣèjọba Gómìnà Mobolaji Johnson ní Èkó. Lẹ́yìn èyí ni wọ́n tún yàn án sípò Kọmíṣọ́nnà fún Ètò Ẹ̀kọ́ ní Ìpínlẹ̀ náà.[7]
Adéníran náà ló tún jẹ́ adarí fún ẹgbẹ́ òṣèlú kan tí ó ń jẹ́ Lagos Progressive tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú méjì mìíràn darapọ̀ mọ́ tí wọ́n sì da ẹgbẹ́ òṣèlú Nigerian People's Party (NPP) sílẹ̀ ní àsìkò ìṣèjọba alágbádá ẹlẹ́ẹ̀kejì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Láìpẹ́, Adéníran di Ààrẹ fún ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun yìí (NPP) lẹ́yìn tí Ọ̀gbẹ́ni Olú Akífòsílẹ̀ tí ó jẹ́ Alága ẹgbẹ́ náà pàdánú ipò ìṣèjọba Èkó tí òun àti Lateef Jakande dù, tí ó sì kúrò nípò adarí ẹgbẹ́ náà. Adéníran ni ó kọ́kọ́ jẹ́ Amòfin Àgbà fún Ìjọba Àpapọ̀ nígbà ayé rẹ̀ tí ó sì di Kọmíṣọ́nnà fún Ètò Ẹ̀kọ́ lẹ́yìn èyí.[1][4]
Àmì ìdánimọ̀ àti Ipa rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Wọ́n sọ ilé-ẹ̀kọ́ Lagos State College of Education (LACOED) ní Adeniran Ogunsanya College of Education ní ìràntí iṣẹ́ takuntakun tí ó ṣe fún ìdàgbàsókè Ìpínlẹ̀ Èkó.
- Senior Advocate of Nigeria
- Queen's Counsel
Àwọn Ìwé Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 "Adeniran Ogunsanya". Nigerian Wiki. Archived from the original on 7 July 2015. Retrieved 7 July 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Who's who in Nigeria. Lagos: Nigerian Printing and Publishing Company. 1956. p. 215. OCLC 6274926. https://books.google.com/books?id=egUaAAAAIAAJ.
- ↑ "Nigerian Political Parties: Power in an Emergent African Nation.". Richard Sklar.
- ↑ 4.0 4.1 "Adeniran Ogunsanya: Remembering an icon". Adenrele Adeniran Ogunsanya. National Mirror. 23 November 2012. Archived from the original on 25 December 2012. Retrieved 7 July 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ https://web.archive.org/web/20121225142644/http://nationalmirroronline.net/new/adeniran-ogunsanya-remembering-an-icon/
- ↑ The Third World Calamity. Brain May. pp. 184–185.
- ↑ "Mobolaji Johnson: An officer and gentleman goes home". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-12-04. Archived from the original on 2020-04-29. Retrieved 2020-05-30.
- Pages with citations using unsupported parameters
- Pages using web citations with no URL
- CS1 Èdè Gẹ̀ẹ́sì-language sources (en)
- Àwọn ọjọ́ìbí ní 1918
- Àwọn ọjọ́aláìsí ní 1996
- Yoruba politicians
- 20th-century Nigerian politicians
- Commissioners of ministries of Lagos State
- King's College, Lagos alumni
- Alumni of the Victoria University of Manchester
- Yoruba legal professionals
- Yoruba royalty
- People of colonial Nigeria
- Àwọn agbẹjọ́rò ará Nàìjíríà
- Lawyers from Lagos
- Àwọn ọmọ Yorùbá
- Nigerian legal scholars
- Nigerian People's Party politicians
- People from Ikorodu
- Ibadan Peoples Party politicians
- Citizens of Nigeria through descent