Aisha Lawal
Aisha Lawal | |
---|---|
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | Actress, scriptwriter, filmmaker |
Ìgbà iṣẹ́ | 2008–present |
Aisha Lawal Oladunni jẹ́ òṣèré Nàìjíríà, òǹkọ̀wé àti òṣèré fíìmù..[1] Arábìnrin náà ni wọ́n yàn fún àmì ẹ̀yẹ Òṣèré tí ó ní ìlérí jùlọ (Yoruba) ní ọdún 2014 City People Entertainment Awards, Òṣèré tí ó dára jùlọ nínú ìkópa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú (Best Actress in Leading Role - Yoruba) àmì ẹ̀yẹ ní ọdún 2015 Best of Nollywood Awards, Best Indigenous Language Movie/TV Series (Yoruba) ní Awards Africa Magic Viewers' Choice Awards 2016 àti Òṣèré Tí ó dára jù ti Ọdún (Yoruba) àti Òṣèré Àtìlẹ́yìn Dára jùlọ ti Ọdún (Yoruba) ní ọdún 2018 City People Movie Awards. </ref>[2][3][4]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Aisha Lawal jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó sì lọ sí Adeen International School àti Federal Government College, Ògbómọ̀ṣọ́. [5][6] Aisha Lawal ní ìtara láti ṣe ìṣèré láti ìgbà èwe rẹ̀, níbi tí yóò ṣe ní oríṣiríṣi àwọn eré orí ìtàgé. [7][8] Lẹ́hìn náà Lawal lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Lead City, níbití ó ti gba òye ní òfin àti òye kejì ní ìṣàkóso gbogbo ènìyàn (Public Administration).[9][10][11]
Iṣẹ́ Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Aisha Lawal lọ sí "Femi Adebayo's J15 School of Performing Arts" láti ọdún 2008 sí ọdún 2010 ó sì kọ́ bí a ṣe lè ṣe eré.[6][7] Fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀ ni 'Adun-ma-deeke' níbi tí ó ti ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó. Ó di olókìkí láti ipa rẹ̀ ní 'Irugbin'. [9][8] Láti ìgbà tí ó ti di olókìkí, ó tẹ̀síwájú láti ṣe eré ní àwọn fíìmù tí ó ju Ọgọ́rùn-ún lọ. Ó ti gbé fíìmù tó bí mẹ́wàá jáde gẹ́gẹ́ bí Imú Níkà àti Ọpọ́n Ìfẹ́. [5] Láìpẹ́, ó ṣàfihàn nínú Love Castle (2021) àti Fíìmù Netflix ti Kunle Afolayan, Aníkúlápó (2022) bí i Olòrì Súnkànmí. [12][13][14]
Ayé Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Aisha Lawal wá láti ìdílé tí ó ní ọmọ mẹ́ta àti pé òun ni ọmọ kejì. [6][7]. Ó ti ṣe ìgbéyàwó tí ó sì ti bí ọmọbìnrin kan. [9][8] Ó jẹ́ Mùsùlùmí. [5][15]
Àwọn Fíìmù Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- King of Thieves (2022)
- Aníkúlápó (2022)
- Love Castle (2021)
- Survival of Jelili (2019)
- Blogger's Wife (2017)
- Simbi Alamala
- Eregun
- Jalaruru
- Aiyepegba
- Apala
- Iyawo Kan
- Okirika
- Dilemma
- Shadow
- Nkan Inu Igi
- Irugbin
- Adunmadeke
Àwọn Ìtọ́ka Sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Aisha Lawal: I still attract men despite being married with child The Nation Newspaper" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 12 September 2020. Retrieved 2022-10-05.
- ↑ "AMVCA 2016: Full nomination list". Africa Magic – AMVCA 2016: Full nomination list (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ BellaNaija.com (6 June 2014). "Rita Dominic, Davido, Tiwa Savage, Majid Michel – 2014 City People Entertainment Awards Nominees". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.
- ↑ lawal, fuad (14 December 2015). "See full list of winners". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.
- ↑ 5.0 5.1 5.2 Reporter (3 September 2018). "Each Time I Get On Set, I Become A Different Person – Aisha Lawal". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.
- ↑ 6.0 6.1 6.2 "Àwọn ojú oge Yollywood t'ọ́jà wọ́n ṣì ń tà wàràwàrà". BBC News Yorùbá. 18 October 2019. Retrieved 2022-10-05.
- ↑ 7.0 7.1 7.2 "Some people laughed at me when they saw me in a public bus — Aisha Lawal". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 6 August 2017. Retrieved 2022-10-05.
- ↑ 8.0 8.1 8.2 Online, Tribune (14 March 2020). "I’d not have forgiven myself if I didn’t have my baby in the US —Actress Aishat Lawal". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.
- ↑ 9.0 9.1 9.2 Bello, Bisola (15 February 2016). "Femi Adebayo is a natural born leader –Actress, Aisha Lawal". QED.NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.
- ↑ Aanu, Damilare (7 March 2019). "Some details about Actress Aisha Lawal’s baby daddy you need to know (Photos)". WITHIN NIGERIA (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.
- ↑ Ononye, Ifeoma (12 December 2021). "Winning an Oscar will be my biggest achievement –Aisha Lawal". New Telegraph (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.
- ↑ Jonathan, Oladayo (3 October 2022). "Movie Review: 'Anikulapo' soars on compelling cinematography but leaves us wanting more". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.
- ↑ "Love Castle highlights Nigerian culture interwoven with disability -Actor". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 6 September 2021. Retrieved 2022-10-05.
- ↑ Okoroji, Kelvin (4 October 2022). "Aisha Lawal reacts to criticism of character in Kunle Afolayan's Anikulapo". QED.NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.
- ↑ People, City (6 September 2019). "Many People Don't Know I Am Happily Married – Popular Actress, AISHA LAWAL". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-05.