Ajégúnlẹ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ajégúnlẹ̀ tí eọ́n tún ń dàpè ní "AJ City" or simply "AJ", jẹ́ agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Èkó tí ó wà ní abẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Ajérọ̀mí Ifẹ́lódùn.[1]

Ajégúnlẹ̀ pààlà pẹ̀lú ibùdó etíkun Àpápá wharf àti Tincan, tí wọ́n jẹ́ ibùdó ìkẹ́rù wọlé lórí omi tí ó tòní jùlọ ní Ìpínlẹ̀ Èkó tí oríṣiríṣi nkan ti wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2] Iye awọn plùgbé Ajégúnlẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀taléláàádọ́ta ènìyàn níbi tí a ti rí gbogbo ẹ̀yà Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[3] Àwọn tí wọ́n jẹ́ olùgbé tí wọ́n pọ̀ jùlọ ní agbègbè náà ni àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí wọ́n jẹ́ Ijaw àti Ìlàjẹ.

Àwọn lààmì-laaka ènìyàn ibẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oríṣiríṣi àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ lààmì-laaka ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ati gbogbo agbáyé ni wọ́n tara Ajégúnlẹ̀ dìde. Lára wọn ni a ti rí agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀rí fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó tún ti jẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá un orílẹ̀-èdè Nàìjíríà rí Samson Siasia. Bákan náà ni a tún ti rí agbábọ́ọ̀lù atamátàsé tí ó ń gbà bọ́ọ̀lù lọ́wọ́ iwájú fún ikọ̀ Manchester United, ìyẹn Odion Ighalo.,[4] Ibẹ̀ náà ni a tún ti rí agbábọ́ọ̀lù lọ́wọ́ ẹ̀yìn fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, ìyẹn Taribo West. Bẹ́ẹ̀ náà ni a rí Chinwendu Ihezuo tí ó gbà bọ́ọ̀lù jeun nínú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù obìnrin ilẹ̀ Nàìjíríà. A tún rí Emmanuel Amuneke, tí òun náà jẹ́ agbábọ́ọ̀lù fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀. Lára wọn náà ni ìlúmọ̀ọ́ká olórin tàkasúfè Daddy Showkey.

Àwọn itọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Ajegunle: The good, the bad, the ugly". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-10-31. Retrieved 2020-06-19. 
  2. Obialo, Maduawuchi (2019-09-19). "All Major Sea Ports in Nigeria & Locations". Nigerian Infopedia (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-06-21. Retrieved 2020-06-19. 
  3. "Horrible link road: Ajegunle, on verge of isolation". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2013-05-20. Retrieved 2020-06-19. 
  4. "Nigeria: Ighalo – Another Ajegunle Boy Designed for Goals". All Africa. 23 May 2015. Retrieved 25 May 2015. 

Àdàkọ:Authority control