Jump to content

Aláàfin Ṣàngó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àyọkà yìí jẹ mọ́ nípa the spirit. Fún other uses, ẹ wo: Aláàfin Ṣàngó (ìṣojútùú).
Aláàfin Ṣàngó
Thunder, Lightning, Fire, Justice, Dance, Virility
Member of the Orisha
Script error: The module returned a nil value. It is supposed to return an export table.
Representation of Ṣàngó, National Museum of Brazil, Rio de Janeiro
Other namesSango, Ṣàngó, Changó, Xangô, Jakuta, Nzazi, Hevioso, Siete Rayos
Venerated inYoruba religion, Dahomey mythology, Ewe religion, Vodun, Santería, Candomblé, Haitian Vodou, Louisiana Voodoo, Folk Catholicism
DayThe fifth day of the week
ColorRed and White
RegionNigeria, Benin, Togo, Ghana,Latin America
Ethnic groupYoruba people, Fon people, Ewe people
Personal information
SpouseỌya, Ọbà,àti Ọ̀sun

Aláàfin Ṣàngó jẹ́ ọba Aláàfin Ọ̀yọ́ àti ọba àgbègbè-ìṣèjọ̀ba Ọ̀yọ́ ẹlẹ́kẹta kí ó tó di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ nínú ẹsìn ìṣẹ̀se n'ílẹ̀ Yorùbá. Ṣàngó jẹ́ alágbára ọkùnrin, agbára rẹ̀ ló farahàn nínú Aira, Àfọ̀njá, Lubé àti Obomi.[1][2]. Agbára kan tí gbogbo ènìyàn mọ̀ mọ Ṣàngó ni Oṣè Ṣàngó. Wọ́n ka Ṣàngó sí ọkàn lára ẹni tí Yorùbá gbà pé ó lágbára jù lọ.

Nínú ẹ̀sìn ìgbàlódé, wọ́n gbàgbọ́ pé òun ẹni mímọ́ Saint Barbara tàbí Saint Jerome.

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ṣàngó jẹ́ Aláàfin Ọ̀yọ́ ẹ̀kẹta lẹ́yìn Aláàfin Oranmiyan àti Àjàká.[2] Ó mú ọlá, ọlà àti ọrọ̀ wá sí Ọ̀yọ́ àti gbogbo àgbègbè-ìṣèjọba Ọ̀yọ́.[3] Gẹ́gẹ́ bí ìwé ọ̀jọ̀gbọ́n According to (Professor Mason) ṣe sọ nínú ìwé rẹ̀ kan tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Mythological Account of Heroes and Kings, Ṣàngó kì í ṣe ojo bí ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Àjàká, ó jẹ́ alágbára àti oníjàgídíjàgan ènìyàn. Ó jẹ́ Ọba to lágbára gan-an. Ọdún méje gbáko ló fi jọba ní Ọ̀yọ́, tí ó sì ń ṣàkóso gbogbo àgbègbè rẹ̀. Gbogbo àsìkò yìí ló fi ń jagun káàkiri. Àrá kan tó sán l' lójijì, tí ó sì jó gbogbo ààfin rẹ̀ ló mú ìjọba rẹ̀ wá sopin ni Ọ̀yọ́. Nígbà ayé rẹ̀, ó ní ìyàwó mẹ́ta, àwọn ìyàwó rẹ̀ ni Ayaba Ọ́sun , Ayaba Ọbà àti Ayaba Ọya.

Ẹ̀yà Yorùbá ni púpọ̀ nínú àwọn ẹrú tí wọ́n kó wá s'ílẹ̀ Amẹ́ríkà, wọn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà tí wọ́n fi ṣ'òwò ẹrú gba orí omi lọ s'ílẹ̀ òkèèrè, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n wá pẹ̀lú àṣà, ìṣe àti àwọn òrìṣà wọn. Ṣàngó wà lára àwọn òrìṣà tí wọ́n kó wá. Bíbọ òrìṣà Ṣàngó wà lára àwọn nǹkan tí ó ṣẹ̀dá ẹ́sìn ìṣẹ̀se Yorùbá ni orílẹ̀ èdè Trinidad àti Recifel, àti Brazil, nítorí èyi ni wọn ṣ ń jé orúkọ tó jẹ mọ́ Ṣàngó l'áwọ̀n orílẹ̀ èdè wọ̀nyí. [4]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named a
  2. 2.0 2.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named William
  3. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Anthony
  4. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named v