Jump to content

Alfa Belgore

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Salihu Modibbo Alfa Belgore

Wọ́n bí Alfa Belgore ní oṣù kẹtàdínlógún, Oṣù Ṣéẹ́rẹ́, 1937 sí ìdílé Fulani ní Ìlọrin, olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Kwara, gbùngbùn-àríwá Nàìjíríà. Ó lọ sí Iléẹ̀kọ́ Alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ Òkesúnà bákan náà Iléẹ̀kọ́ Middle kí ó tó tẹ̀síwájú sí Iléẹ̀kọ́ Gírámà Iléṣà níbi tí ó ti gba Ìwé-ẹri Iléẹ̀kọ́ tí Iwọ̀-Oòrùn Áfíríkà ní ọdún 1956. Ó gba oyè BA nínú imọ̀ òfin ní 1963 ó sì kẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún kan ní Inner Temple kí ó tó padà sí Nàìjíríà ní ọdún 1964,láti ṣiṣé sin Májísítírètì ní Àríwá Nàìjíríà. Ní ọdún 1986,wọ́n yàn án ni adájọ́ Ilé-ẹjọ́ tí ó gajù ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà (Supreme Court of Nigeria). Ó ti di ipò oríṣìíríṣìí ní ẹ̀ká ètò idajọ kí wọ́n tó fi jẹ́ adájọ́ àgbà ní oṣù Agẹmọ, ọdún 2006, ipò yìí ló fẹyìntìn sí ní ọdún 2007.