Amúwò-Ọ̀dọ̀fin
Amúwò-Ọ̀dọ̀fin ni ìjọba ìbílẹ̀ tí ó wà nị́ ẹkùn Àgbádárìgì ní ìpínlẹ̀ Èkó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1]
Ọ̀nà tí ìjọba ìbílẹ̀ yí pín sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìjọba ìbílẹ̀ yí pín sí méjì, níbi tí a ti rí onídàgbà-sókè Oríadé àti ìjọba ìbílẹ̀ onídàgbà-sókè Amúwò tí àwọn náà ní ìsọmọgbè méje (7) lábẹ́ ìkọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn ni : Abúlé-Òṣun, Agbójú, Ìbèshè, Ìjegun, Ìréde, Kiríkirì àti Kùjé tí wọ́n jẹ̣́ ìsọmọgbè ( ìjọba ìbílẹ̀ onídàgbà-sókè Oríadé), nígbà tí Àdó-sọbà, Èkó Àkéte, Ìfẹ́lódùn, Ìlàdó Tamaro, Ìrẹ́pọ̀dùn, Ọ̀dọ̀fin àti Oríre jẹ́ ti ìjọba onídàgbà-sókè Amúwò. [2]
Àkójọ ìlú abẹ́ àwọn Ìsọmọgbè wọn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oríṣi ìlú mẹ́tàdínlógọ́rin agbègbè ni ó wà ní lábẹ́ ìkọ̀ọ̀kan wọn nígbà tị́ ìlú méjìlá jẹ́ ìlú tí ó ti gòkè àgbà nínú wọn, tí Mẹ́jọ ń gòkè àgbà bọ̀, tí Mẹ́tàdínláàdọ́ta kò tíì dàgbà rárá. [3] Ìjọba ìbílẹ̀ Amúwò-Ọ̀dọ̀fin ni ó tó iye ìwọ̀n 300,000, tí ó sì mu láti jẹ́ ibi tí ó gbòòrò jùlọ. Nínú ìkànìyàn ọdún 2006, wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ìjọba ìbílẹ̀ Awúmò-Ọ̀dọ̀fin ni ó ní iye ènìyàn àti olùgbé tí ó tó 1,500,000. Ìjọba ìbílẹ̀ náà ni ó tún pààlà pẹ̀lú ìjọba ìbílẹ̀ Ajérọ̀mí àti Ìfẹ́lódùn ní apá Ìlà Oòrùn, ó pààlà pẹ̀lú Oríadé ní apá Ìwọ̀ Oòrùn, pẹ̀lú Àgbádárìgì ní apá Yáǹmọ́, tí ó sì tún pààlà pẹ̀lú Ìsọlọ̀/Ìgandò ní apá Àríwá. [4]
Ọdún ìbílẹ̀ tí wọ́n ma ń ṣe níbẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Púpọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ onílẹ̀ tàbí onílẹ̀ àti ọmọ bíbí Amúwò ni wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn Àwórì. Púpọ̀ nínú àwọn ọdún ìbílẹ̀ tí wọ́n ma ń ṣe níbẹ̀ ni : ọdún Ẹlẹ́gba, Orò, Sàńgbétọ́ àti Ìgunukó. Àwọn tí wọ́n dipò ìṣèjọba ìbílẹ̀ abẹ́lé pàtàkì mú níbẹ̀ ni àwọn adarí ẹ̀sìn íbílẹ̀ bí : Ọba àwọn Ìjòyè àti àwọn Báálẹ̀ .
Awon Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Amuwo Odofin Local Government". Amuwo Odofin Local Government. 2018-12-31. Archived from the original on 2020-01-18. Retrieved 2020-01-05.
- ↑ "List of Towns and Villages in Amuwo-Odofin L.G.A". Nigeria Zip Codes. 2014-03-10. Retrieved 2020-01-05.
- ↑ "Amuwo Odofin LGA to offer free surgeries, screenings during medical week". Tribune Online. 2019-08-10. Retrieved 2020-01-05.
- ↑ "Amuwo-Odofin, Lagos State - Nigeria Directory, A List of Nigerian Businesses, Organisations, Firms and Companies". Nigeria Yellow Pages. Retrieved 2020-01-05.