Anthonia Kehinde Fatunsin
Anthonia Kehinde Fatunsin | |
---|---|
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Known for | Being the first female archaeologist from Nigeria |
Anthonia Kehinde Fatunsin jẹ́ awalẹ̀pìtàn ọmọ Nàìjíríà, èyí tí àwọn onímọ̀ Gẹ̀ẹ́sì mọ̀ sí archaeologist. Wọ́n kà á sí obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣẹ̀ǹbáyé ní Nàìjíríà, àti obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ́ olórí ilé mùsíọ́mù orílẹ̀-èdè Ìbàdàn [1](National Museum of Ibadan).[2]Iṣẹ́ ìṣe ààyè rẹ̀ ti dojúkọ púpọ̀ jùlọ lórí amọ̀ mímọ Yorùbá, pàápàá láti agbègbè Ọ̀wọ̀.[3]
Iṣẹ́ Rẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Wúlẹ̀wúlẹ̀ Ti Awọn Òwúlẹ̀wútàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fátúnsìn bẹ̀rẹ̀ wúlẹ̀wúlẹ̀ nínu ilẹ̀ ìlú Igbólàjà àti Ìjẹ̀bú-Ọ̀wọ̀ láti ṣàwárí ohun alùmọ́nì tí wọ́n ń pè ní [ terracotta] lọ́dún 1981. Ọ̀gbẹ́ni Babásẹ̀hìndé Adémúléyá lati ifáfitì Obafemi Awolowo University ṣàkíyèsí pé àyẹ̀wò rẹ̀ ni ìgbà kejì tí iṣẹ́ ìwádìí wúlẹ̀wúlẹ̀ báyìí wáyé lẹ́yìn ti Ekpo Ẹyọ[4] tí ó wáyé lọ́dún 1976. Bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí, ìwádìí Fátúnsìn ni ó sàlàyé ọ̀ríkínniwín lórí àwọn ère. [5]
Iṣẹ́ Rẹ̀ Lórí Àwọn Mùsíọ́mù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fatunsin ti kọ nípa ipa tí Wúlẹ̀wúlẹ̀ ti àwọn òwúlẹ̀wútàn ní àwọn Museum Naijiria àti ipa rẹ̀ lórí àwọn ohun-ìní àṣà ní orílẹ̀-èdè náà.[6] A ti mọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọnà fún ìrònú àti ìtumọ̀ wúlẹ̀wúlẹ̀ ti àwọn òwúlẹ̀wútàn lẹ́hìn òmìnira ní Ilẹ̀ Áfíríkà.[7]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ National Museum of Unity, Ibadan - Wikipedia
- ↑ Oziogu, Apollos Ibeabuchi (17 June 2012). "Owo culture of ancient Nigeria". Vanguard. Retrieved 2021-06-09.
- ↑ "Fatunsin, Anthonia". WorldCat. Retrieved 2018-04-02.
- ↑ en.wikipedia.org/wiki/Ekpo_Eyo
- ↑ Babásèhìndé, Adémúlèyá (July 2015). "Stylistic Analysis of Igbo 'Laja Terracotta Sculptures of Owo". Mediterranean Journal of Social Sciences 6 (4 S2). http://www.mcser.org/journal/index.php/mjss/article/download/7071/6774. Retrieved 2021-07-01.
- ↑ Fatunsin, Anthonia K. (1994). "Archaeology and the protection of cultural heritage: the Nigerian situation" (in en). Archéologie et sauvegarde du patrimoine: Actes du VIe colloque, Cotonou, Bénin, 28 mars - 2 avril 1994 = Archaeology and safeguarding of heritage: Proceedings of the 6th colloquium, Cotonou, Benin, 28th March - 2nd April 1994: 63–69. https://www.bcin.ca/bcin/detail.app?id=170008.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Theory in Africa. doi:10.4324/9781315716381-7. https://www.taylorfrancis.com/books/e/9781315716381/chapters/10.4324/9781315716381-7. Retrieved 2019-11-14.