Jump to content

Ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ Aboakyer

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ Aboakyer jẹ́ ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ tí àwọn ará Winneba ní Ààrin Gbùgùn ilẹ̀ Ghana ti máa ń pa àgbọ̀nrín.[1]

Àwọn ọkùnrin mu àgbọlnrín láti fi ṣàjọyọ ọdún ìbílẹ̀ Aboakyer ní ìlú Ghana

Orúkọ ayẹyẹ yìí, tí í ṣe Aboakyer túmọ̀ sí "ṣíṣe ọdẹ láti pa ẹran" nínú ẹ̀ka-èdè Fante, èyí tí àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ààrin gbùngbùn ilẹ̀ Ghana ń sọ. Ṣíṣe àjọyọ̀ yìí wà láti fi ṣàjọyọ̀ ìwọ́kúrò àwọn ará Simpafo (èyí ni orúkọ ìbílè tí wọ́n fún Winneba). Àwọn ènìyàn kó kúrò ní apá Aríwá mọ́ Ìlà-Oòrùn ilè Áfíríkà ti ìlú Timbuktu ní ilẹ̀ Sudan lọ sí ààrin gbùngbùn ilẹ̀ Ghana.[2] Ọmọ ìyá méjì kan ló mú wọn rin ìrìn-àjò náà láti apá àríwá mọ́ ìlà-oòrùn ilè Áfíríkà.[3] Àwọn ènìyàn náà gbàgbọ́ pé òrìṣà kan tí wọ́n ń pè ní Otu, ló pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ewu tí wọ́n kojú lọ́nà. Ní ọnà láti fi ìmọ-rírì hàn, wọ́n bèrè lọ́wọ́ Aláwo kan láti mọ ohun ẹbọ tí òrìṣà náà ń fẹ́. Sí ìyàlẹ́nu wọn, òrìṣà náà béèrè fún ìrúbọ ènìyàn, láti inú ìdílé ọlọ́lá kan.[3] Ìrúbọ náà wáyé fún ọdún mélòó kan àmọ́ wọ́n dáwọ́ rẹ̀ dúró lẹ́yìn ọdún díẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn náà ò fẹ́ ìfènìyàn rúbọ́ mọ́.[2]

Wọ́n bẹ òrìṣà yìí kó yí irúfẹ́ ẹbọ tó ń gbà padà, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé fífí àwọn ọmọ ọlọ́lá rúbọ máa mú ìparun bá ìdílé ọlọ́lá.[4] Òrìṣà náà bá béèrẹ̀ pé kí wọ́n fi olóńgbò búburú tí wọ́n mú láàyè rúbọ ní ojúbọ òun. Lẹ́yìn ìfihàn yìí ni wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá bẹ́ orí rẹ̀, tí wọ́n á sì máa ṣe ní ọdọọdún.[5]

Kí ayẹyẹ náà tó bẹ̀rẹ̀, àwọn ènìyàn náà gbé ìdí òrìṣà yẹn kalẹ̀ sí ìlú Penkye. Lẹ́yìn ìwọ́kúrò wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pe òrìṣà náà ní Penkyi Otu, láti fi sọrí ilé òrìṣà náà. Láti ṣe ayẹyẹ yìí, àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní wá olóńgbò búburú bí òrìṣà náà ti pa á láṣẹ́ fún wọn. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló kú nítorí wọ́n ní láti mú ẹranko náà lóòyẹ ni, tí wọ́n máa sì gbe lọ sí Penkye. Àwọn ará ìlú náà bẹ̀bẹ̀ ní ẹlẹ́ẹ̀keji, pé kí Penkyi Otu fún wọn ní nǹkan mìíràn láti fi rúbọ dípò olóńgbò búburú yìí. Ẹ̀bẹ̀ náà sì mú kí ó wí fún wọn pé kí wọ́n fi àgbọ̀rín onílà lára rúbọ.[5] Àwọn ẹgbé ọlọ́dẹ méjì tí í ṣe Tuafo (èkíní) àti Dentsifo (èkejì), ní wọ́n máa ń ṣe èyí. Wọ́n máa ń ṣàjọyọ̀ yìí ní oṣù Èbìbí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ayẹyẹ tó gbilè jù lọ ní ìlú Ghana. Àwọn jagunjagun náà máa ń pa àgbọ̀nrín yìí láìsí ìbọn tàbí ohun èlò ọdẹ kankan, ọwọ́ lásán ni wọ́n fi máa ń pa ẹranko yìí.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ará Simpa fi àṣà yìí lé àwọn ìra wọn lọ́wọ́ nípasẹ orin, èyí tí wọ́n máa ń kọ ní àsìkò ogun wọn, tí wọ́n sì máa ń pìtàn náà lásìkò eré-òṣùpá. Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yìí ń lọ títí tí àwọn Òyìnbó amúnisìn dé sí ilè Gold Coast tí wọ́n sì mú èdẹ̀ Gẹ̀ésì dé. Àwọn onímọ̀ ló tú ìtàn náà láti èdè 'Fante' sí èdè Gẹ̀ẹ́sì.[6]

Àwòrán ìlú Winneba lásìkò ayẹyẹ ọdún Aboakyer

Ọjọ́ Àbámẹ́ta àkọ́kọ́ nínú oṣù Èbíbí ni wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ yìí. Ní ọjọ́ kìíní ayẹyẹ náà, àwọn ẹgbé jagunjagun méjèèjì ní Winneba á lọ dọdẹ. Ẹgbẹ́ àkọ́kọ́ tó bá pa ẹran náà ni wọ́n á lò fún ayẹyẹ yìí.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Aboakyer festival". pathghana. Archived from the original on 15 October 2011. Retrieved 2 December 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. 2.0 2.1 Brown, Kwesi Ewusi (December 2005), Social Conflicts in Contemporary Effutu Festivals (M.S. thesis), Bowling Green State University, archived from the original on 10 February 2012, retrieved 2 December 2011  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. 3.0 3.1 "Aboakyer festival". GhanaWeb. Archived from the original on 18 November 2011. Retrieved 2 December 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named TIM2
  5. 5.0 5.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named MIG2
  6. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named MIG3